Òkété borù, olókoòwò àti egbògi olóró N8.8bn bọ́ sọ́wọ́ NDLEA

Aworan ile ti wọn ti ri oogun oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ọwọ panpẹ ajọ oloogun oloro orileede Naijiria NDLEA tun ti tẹ ogbologbo oloogun oloro kan ni ilu Eko,

Ni adugbo Victoria Garden City, Lekki ni ilu Eko ni alukoro ajọ NDLEA, Femi Babafemi sọ pe awọn ti ri oogun oloro Tramadol gba.

Babafemi ni iye owo oogun oloro naa le ni biliọnu mẹjọ Naira, eyi ti wọn ko ni ile nla kan, ti baba isalẹ awọn oloogun olori yii kọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Ugochukwu Nsofor Chukwukadibia ni alaga ileeṣẹ to n ta ọkọ Autonation Motors,

Bi ọwọ ṣe tẹ Baba isalẹ agboogun oloro naa, lo waye ni akoko ti ko pẹ ti wọn ri awọn oogun oloro ni ile baba isalẹ mii ninu adugbo Victoria Garden City yi kanna.

Ni ti ẹni ti wọn mu kẹyin ni nkan bi oṣu meji sẹyin, Chris Emeka Nzewi, wọn ri ileesẹ to ti n pọn oogun oloro methamphetamine, ti ọwọ si tẹ apoogun rẹ iyẹn arakunrin Sunday Ukah.

Bi ọwọ ṣe tẹ Ugochukwu ree - NDLEA

Ajọ NDLEA lẹnu lọọlọ yi ni Naijiria ti n ko inira ba pupọ awọn to n ṣowo oogun oloro.

Gẹgẹ bi iṣe wọn, iwadii finifini ni wọn lo ṣe okunfa bawọn ṣe ri Ugochukwu ẹni ọdun majilelaadọta yii mu.

Wọn ni ayẹwo ile rẹ to kọ ni VGC lo mu ki awọn ri paali 443 oogun oloro Tramadol Hydrochloride 225mg, ti woro oogun naa ẹgbẹrun mẹtala si wa ninu rẹ.

NDLEA sọ pe awọn pali kan ti jona ṣaaju ni ọjọ ti ọwọ tẹ afurasi yii.

Ajọ to n gbogun ti oogun oloro sọ pe o ti se diẹ tawọn ti n tọ ipasẹ Ugochukwu gẹgẹ bi awọn to n lewaju iṣẹ oogun oloro tita yii.

Babafemi sọ pe iwadii ibẹrẹ pẹpẹ wọn fihan pe afurasi yii ni ile mẹfa ninu adugbo naa,

Amọ ọkan ninu ile naa lo n lo gẹgẹ bi ile ikẹrupamọsi, nibi ti wọn ko oogun oloro Tramadol si.

Ajọ NDLEA tun fi kun pe awọn ri ọkọ ayọkẹlẹ meji ni ile rẹ ti ọkan ninu wọn si jẹ ọkọ ayẹta taa mọ si bullet proof.

Alukoro NDLEA sọ pe awọn ti gbe awọn ọkọ yii lọ si aaye ikẹru pamọ si ajọ wọn.

Aworan ile ti wọn ti ri oogun oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Araalu kan saara si alaga ajọ NDLEA, Buba Marwa pe o n ṣe bẹbẹ

Kaakiri oju opo ayelujara, niṣe lawọn ọmọ Naijiria n kan saara si ọga ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro, agagunfẹyinti Buba Marwa.

Lẹnu igba to ti gba isẹ yii, iye awọn ti ajọ naa ti mu ati iye oogun oloro ti wọn ri gba lọwọ wọn kii se kekere.

Labẹ akoso rẹ ni wọn mu ọga ọlọpaa ilumọọka nii ASP Abba Kyari, lori ẹsun pe o n lẹdi apo pọ pẹlu awọn oloogun oloro.

Eleyi nikan kọ, lẹnu oṣu meloo kan sẹyin, NDLEA ti mu awọn to n ta oogun oloro ni Badagry nilu Eko lẹẹmeeji ati ni awọn ibomiran jakejado Naijiria.

Ipinnu ati ifarajin ajọ naa ti n fun awọn ọmọ Naijiria ni igbagbọ pe, ogun ti ajọ ati ijọba n gbe koju awọn oloogun oloro ti n so eso rere.

Aworan ọrọ loju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, Folorunsho Fatai Adisa