Àjọ NDLEA jó ẹgbẹ̀lẹgbẹ̀ oògùn olóró níná ní Eko

Oríṣun àwòrán, Google
Ajọ to n gbogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA ti sun ẹgbẹlẹgbẹ oogun oloro to to kilo 560,068.31414.
Iwadii fihan pe eleyii lo ṣi pọju ninu jijo oogun oloro ti ajọ naa ṣe ni orilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ Ajọ NDLEA, DFemi Babafemi ninu atejade ti wọn fi lede ni awọn alaṣẹ ajọ naa ati awọn ẹṣọ alaabo lo dari igbesẹ naa.
Won ni eyi yoo fi to awọn baba isalẹ awọn oloogun oloro naa pe niṣe ni wọn fi owo jona lori iṣẹ laabi ti wọn n ṣe.
‘’Awọn oniṣe ibi yi yoo maa padanu ọgọọrọ ti wọn fi n ṣe iṣẹ laabi yii, eyi yoo si kọ wọn ni ọgbọn pe kii se iṣe to yanju ni wọn n ṣe.’’
‘’Ti wọn ko ba yawọ ninu iṣẹ buruku yii, ọwọ palaba wọn ko nii pẹ segi.’’
Awọn oogun oloro ti wọn jo ni 7,414.519kg cocaine; 161,206kg heroin; 1,144.8kg methamphetamine; 60,144kg ephedrine; 311,416.19162kg cannabis sativa; 10,091.83kg khat; 273.223kg tramadol; 0.000170kg benylin pẹlu codeine ati 8,207.7505kg awọn oogun oloro miran.
NDLEA n sisẹ lati fopin si lilo oogun oloro ni Naijiria
Agbẹnusọ ajọ naa ni inu awọn dun pe iṣẹ awọ oṣiṣẹ wọn ko jasi asan, ti ohun gbogbo si lọ bi wọn ṣe fẹ.
O ni idaniloju w ape laipẹ aṣilo oogun ati mimu oogun oloro yoo dopin lorilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ ajọ NDLEA naa ni iṣẹ takuntakun ti ajọ naa ṣe lo mu ki wọn ki wọn ri awọn oogun oloro naa gba lọwọ awọn to n ṣe iṣẹ naa.
Bakan naa lo ni awọn ri awọn oogun wọnyii gba pada ni papako ofurufu Murtala Mohammed International Airport(MMIA), ileeṣẹ ajọ NDLEA ni ipinlẹ Eko, Seme ati awọn ti ileẹjọ giga ni Naijiria ti da ẹjọ fun pe ki wọn lọ daanu ati awọn ti wọn ju silẹ, ti wọn salọ.












