Eyinwumi Muka 'Muka Ray' darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara

Aworan Muka Ray

Oríṣun àwòrán, Mukayray

Gbajumọ oṣere sinima Yoruba, Eyiwunmi Muka Aramide ti ọpọ mọ si Muka Ray ti darapọ mọ oṣelu bayii pẹlu bi gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahaman ṣe yan an gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ agba lori ọrọ aṣa ati irinajo afẹ.

Gbajumọ onitiata to lokiki ni Muka Ray, ọmọ agbegbe idibo wọọdu Ipetu/ Rore/ Aran-Orin ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun si ni.

Ijọba ipinlẹ Kwara kede orukọ Eyiwumi Muka Aramide ati ipo tuntun ti wọn yan an si l’Ọjọbọ.

Ṣaaju iyansipo rẹ, gomina Abdulrazaq kan naa ti yan eekan elere sinima miran, Fẹmi Adebayọ si ipo amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ aṣa, iṣe ati irinajo afẹ lọdun 2016.

Ikede iyansipo Muka Ray tun tọka si ara igbesẹ akọtun eyi to n fihan bi awọn eekan elere sinima lorilẹede Naijiria pẹlu ṣe ti n lẹnu ninu ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria.

Awọn gbajumọ oṣere ti Muka Ray n tọpasẹ wọn lagbo oṣelu

Muka Ray

Oríṣun àwòrán, mukaray

O n tọ ipasẹ awọn oṣere bii Bukky Wright to dije fun ipo ile aṣofin apapọ lọdun 2014. Bukky Wright dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu SDP nigba naa.

Desmond Elliot to wa nile aṣofin ipinlẹ Eko bayii. Desmond Ellio lo n ṣoju ẹkun idibo Surulere nile aṣofin ipinlẹ Eko bayii labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

Olubankọle Wellinghton ti ọpọ mọ si Banky W to n dije fun ipo aṣojuṣofin lẹgbẹ oṣelu PDP fun eto idibo apapọ ọdun 2023 pẹlu Funkẹ Akindele ti ọpọ mọ si Jennifer to n dije gẹgẹ bi igbakeji gomina nipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.