Ọdún 1981 ni mo ti ń ṣe ayálégbé kí ṣọ́ọ̀ṣì tó kọ́lé fún mi – Aludùrù ìjọ

Àkọlé fídíò, Ọdún 1981 ni mo ti ń ṣe ayálégbé kí ṣọ́ọ̀ṣì tó kọ́lé fún mi – Aludùrù ìjọ
Ọdún 1981 ni mo ti ń ṣe ayálégbé kí ṣọ́ọ̀ṣì tó kọ́lé fún mi – Aludùrù ìjọ

Ajani Godwin Babalola ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin, to jẹ aluduru ninu ijọ African Church ti ṣalaye fun BBC Yoruba bi igbe aye rẹ ṣe yi pada lẹyin ọpọ ọdun to ti n ṣiṣẹ fun ọlọrun.

Baba agba naa ti ijọ ọhun kọ ile fun ni ile tuntun naa jẹ iyalẹnu nla fun oun.

O ni awọn elere aye kan loun n tẹ gita fun tẹlẹ ki oun to pẹyinda bẹrẹ si n lo ẹbun oun fun Oluwa.

Ninu iriri rẹ, o ni igba ti oun bẹrẹ si n lo gbogbo akoko oun fun duru titẹ ninu ile Oluwa loun padanu owo ti oun n ṣe tẹlẹ, to fi mọ iyawo oun atawọn ọrẹ kan, amọ ni igbẹyingbẹyin, ayọ lo pada ja si fun oun.

Ẹmi Ọlọrun lo ni ki a da Babalola lọla

Nigba to n sọrọ, alufaa ijọba ti babalola ti n ṣiṣẹ sin Ọlọrun, Pasitọ Adebayo Olujimi sọ pe Ọlọrun lo fi si oun lọkan ki wọn da ọkunrin naa lọla.

Olujimi sọ pe asiko ti baba naa n ṣe ọjọ ibi lawọn gbero lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa fun ki inu rẹ le dun amọ Ọlọrun ni eto rere miran fun baba oniduru ọhun ju ero ti awọn ni lọkan.

Ọkan lara awọn to kọ gbero bi wọn ṣe kọ ile naa, Olusesan Akinpelu ni asiko ti wọn n gbero lati ṣe akara oyinbo nla kan fun baba ni ẹnikan ninu igbimọ ti wọn gbe kalẹ fun eto naa sọ pe o san ki wọn kọ ile fun baba ju ki wọn ṣe akara oyinbo fun lọ.

Gẹgẹ bii ohun ti Olujimi sọ, ile oniyara kan ni awọn kọkọ fẹ kọ tẹlẹ, amọ wọn yi ero awọn pada, ti wọn si kọ ile oniyara meji fun baba, eyii ti wọn pe orukọ rẹ ni “Bethel House.”

Bi igba ti eeyan kuro ninu ile eku lọ si aafin ọba lori

Lori bi inu rẹ ṣe dun to lori ile naa, Babalola sọ pe ayọ oun ko lohunka.

O ni ile ọhun da bi igba ti eeyan ba kuro ninu ile eku si aafin ọba lo ri loju oun.

Baba Babalola wa gba awọn eeyan to n ṣiṣẹ sin Ọlọrun lamọran pe ki wọn ni suuru nidi iṣẹ naa, ki wọn si maa fi ọkan kan ṣiṣẹ ọhun.