NDLEA dáná sun egbògi olóró tó lé ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà

Egbògi olóró tí wọ́n fẹ́ dáná sun

Àjọ tó ń gbógunti lílo egbògi olóró ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NDLEA ti dáná sun egbògi olóró tó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà.

Ní agbègbè Badagry ní ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n ti dáná sun àwọn egbògi olóró náà èyí tí wọ́n jáwọ ibi tí wọ́n ń kówọn sí ní Ikorodu lọ́sẹ̀ tó kọjá.

NDLEA ní ìgbà akọ́kọ́ nìyí tí àwọn yóò ṣe àwárí egbògi olóró tí ó pọ̀ tó báyìí láti ìgbà tí iṣẹ́ wọn ti bẹ̀rẹ̀.

Wọ́n ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko ló fún àwọn ní àṣẹ láti dáná sun egbògi olóró náà.

Nínú tọ́ọ̀nù 1.8 èyí tí wọ́n rí mú níbi iṣẹ́ náà, wọ́n ní búlọ̀kù 1,828 ni àwọn dáná sun tí àwọn sì fi ìyókù pamọ́ láti fi ṣẹjọ́ pẹ̀lú àwọn afurasí tí wọ́n mú nígbà tí wọ́n yawọ ilé náà.

Egbògi olóró tí wọ́n fẹ́ dáná sun
Àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA níbi tí wọ́n ti ń dáná sun egbògi olóró náà
Àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA níbi tí wọ́n ti ń dáná sun egbògi olóró náà

Àwọn afurasí ọ̀hún náà tẹ̀lé àjọ NDLEA lọ sí ibi tí wọ́n ti lọ sun egbògi olóró ní Ibereko Badagry tí wọ́n sì tọwọ́bọ ìwé pé kí NDLEA dáná sun àwọn egbògi náà.

Àjọ náà ní gbogbo dúkìá tí àwọn afurasí náà bá fi owó egbògi olóró kójọ ni àwọn yóò gbà pátápátá.

Buba Marwa tó jẹ́ olórí àjọ NDLEA ṣàlàyé pé láàárín ogún oṣù sí àsìkò yìí ọkọ̀ 249 ni àwọn ti gbà lọ́wọ́ àwọn tó ń gbé egbògi olóró tí àwọn sì tún ti dí akoto owó 600 ní àwọn ilé ìfowópamọ́.

Marwa tún fi kun pé kò dín afurasí 2904 tó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn gbígbé agbògi olóró.

Àjọ NDLEA jáwọ ibi tí wọ́n kó oògùn olóró tó lé ní ọgọ́rùn ún bílíọ̀nù Naira sí ní Eko

Aworan

Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe Ajọ tó ń gbógun tí lilo oògùn olóró lorilẹede Naijiria, NDLEA ti jawọ ibi ti wọ ti awọn oloogun oloro gbe oogun oloro to le ni ọgọrun biliọnu Naira (N194, 775,000,000) pamọ si.

Eyi jẹ igba akọkọ ni itan igbogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria ti ọwọ yoo tẹ awọn ologun oloro lọgọọrọ lẹẹkan naa.

Agbegbe kan ni Ikorodu ni wọn ti ri oogun oloro naa to le ni ẹgbẹrun kilo.

Ọwọ tẹ awọn mẹrin to jẹ baba isalẹ awọn oloogun oloro ni ilu Eko

O kere tan awọn to ni oogun oloro yii ni awọn ọtẹlẹmuyẹ naa fi panpẹ mu ni ẹyọ kọọkan kaakiri ilu Eko.

Ọmọ orilẹede miran wa lara awọn olori awọn oloogun ọrọ mẹrin ti wọn ri mu ni ilu Eko.

Awọn wọnyii ni ajọ to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA ni awọn ti n wa lati ọdun 2018 nitori wọn pẹlu ẹgbẹ awọn oloogun oloro lagbaye.

Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kejidinlogun ati Ọjọ Aje, Ọjọ Kọkandinlogun ni wọn ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to ṣafihan awọn oloogun oloro naa.

''Igba ti yipada, aṣiri awọn oloogun oloro ko bo mọ'' - NDLEA

 Iwadii fihan pe wọn fẹ ko oogun oloro naa lọ si ilẹ Yuroopu, Asia nibi ti wọn ti fẹ ta a fun awọn olubara wọn ni oke okun.

Ninu baagi mẹwaa ti wọn n di ẹru si ni wọn gbe oogun oloro ọhun si to fi mọ garawa mẹtala.

Ajọ NDLEA gboriyin fun awọn oṣiṣẹ wọn to ri pe wọn ri ẹyin awọn to n hu iwa ibajẹ lawujọ yii.

Bakn naa ni wọn gboriyin fun ikọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorilẹede Amẹrika (US-DEA).

Ninu ọrọ rẹ, Alaga Ajọ NDLEA ni Naijria, Mohammed Buba Marwa ni awọn oloogun oloro yoo ma ranti ọjọ yii titi ayeraye wọn.

Marwa fikun un pe eyi yoo jẹ ẹkọ fun wọn lati jawọ ninu ṣiṣe ibajẹ ati pe igba ti yipada, aṣiri wọn ko si bo mọ.