Agbébọn kan pa èèyàn 17 nílé ẹkọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Russia

Awọn oṣiṣẹ alaabo nibi ti ikọlu naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ko din ni eeyan mẹtadinlogun ti ọkunrin agbebọn kan pa nile ẹkọ kan ni orilẹ-ede Russia lọjọ Aje.

Iroyin sọ pe eeyan mẹrinlelogun lo tun fi ara pa, ti akẹkọọ mọkanla si wa lara awọn to ku nile ẹkọ naa to wa nilu Izhevsk.

Awọn alaṣẹ sọ pe agbebọn naa pa ara rẹ sibi ikọlu naa, ti oun funra rẹ si jẹ akẹkọọ nibẹ nigba to wa lọmọde.

Awọn fidio to wa lori ayelujara sihan bi awọn eeyan ṣe n sa kijokijo ninu ile ti ikọlu ti waye, ati ni ayika ibẹ.

Fidio miran tun fihan bi ẹjẹ ṣe kun ilẹ yaara ikẹkọ kan, pẹlu bi awọn ọmọde ṣe sapamọ si abẹ tabili ikọwe wọn.

Ọmọde mọkanla ati agbalagba mẹrin ni agbebọn naa pa, lara awọ̀n ti oṣiṣẹ alaabo meji ati olukọ meji wa.

Ni bayii, wọn ti ko awọn akẹkọọ ati awọn olukọ wọn kuro nile ẹkọ naa.

Iroyin sọ pe agbebọn naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Artem Kazantsev ni wọn bi ni ọdun 1988, to si ṣe ikọlu naa pẹlu ibọn ilewọ ‘pistol’ meji.

Mọ̀ nípa òfin tuntun tí Putin fi síta tó lè sọ ọ́ di ọmọ Russia láàrin ọdún kan

Vladimir Putin

Oríṣun àwòrán, Shutterstock

Awọn ọmọ ilẹ okeere ti lanfaani bayii lati di ọmọ onilu lorilẹ-ede Russia laarin ọdun kan pere.

Ọjọ Satide ni Aarẹ Vladimir Putin kede pe ọmọ ilẹ okeere yoowu to ba gba lati fọwọ si adehun iṣẹ ọdun kan pẹlu ileeṣẹ ologun orilẹede Russia, lati kopa ninu ogun ni Ukraine, le kọwe lati di ọmọ onilu.

Ṣaaju ikede yii, ẹni ti yoo ba ni anfani lati di ọmọ orilẹ-ede naa gbọdọ ti gbe nibẹ fun ọdun marun-un.

Bakan naa ni Putin tun paṣẹ pe ẹwọn ọdun mẹwaa ni ki wọn o ju ọmọ ogun to ba kọ̀ lati ja ni Ukraine, tabi gbiyanju lati sa kuro nibi iṣẹ ologun.

Ikede naa waye lẹyin ọjọ diẹ ti Putin kede pe awọn yoo fa ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ọkunrin wọ ileeṣẹ ologun lati ja ni Ukraine.

Lati igba naa si ni iwọde ati ifẹhonu han ti n waye jakejado orilẹ-ede ọhun.

O si ti to ẹgbẹrun kan eeyan ti awọn agbofinro ti mu lara awọn oluwọde.

Ẹwẹ, iroyin sọ pe ni kiakia si ni wọn pin fọọmu fun diẹ lara awọn ti wọn mu lọjọ Satide, ti wọn si tun paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ alaabo ko wọn lọ si ibudo ti wọn o ti pin wọn si oju ogun.

Ijọba ni igbesẹ fifi ipa mu awọn araalu lọ si oju ogun, ko tako ofin.

Awọn ọmọ ogun fipa mu obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ofin tuntun yii mu ki ọpọ onwoye gbagbọ pe o ṣafihan pe awọn ọmọ ogun Russia ti dinku pupọ.

Ṣugbọn ṣa, bi awọn kan ṣe n fi ẹhonu han, ni awọn ọdọ kan ti n sa kuro ni Russia nitori ki wọn ma baa fa wọn wọ ogun jija, ti wọn si n salọ si awọn orilẹ-ede to mule ti wọn bii Finland ati Latvia.

Awọn alaṣẹ agbegbe ni Russia sọ pe ko din ni ẹgbẹrun meji aabọ ọkọ to n gbiyanju lati jade nilu.

Ṣugbọn ṣawọn ni ‘ayederu iroyin’ ni pe awọn eeyan n fi ilu silẹ nitori ki wọn o ma baa darapọ mọ ileeṣẹ ologun.

Oṣu Keji, ọdun 2022, ni Russia bẹrẹ ogun pẹlu Ukraine