Àwùjọ àgbàyé, ẹ fìyà tó tọ́ jẹ Russia, kẹ sì fi Putin jófin ìyà ìṣekúpani - Zelensky

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky ti pe fun ijiya to tọ fun orilẹede Russia lẹyin ti Aarẹ Putin ni oun ti ṣe afikun awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lati lọ koju orilẹede Ukraine.
Zelensky pe fun ijiya naa nigba to n darapọ mọ ijokoo Ajọ iṣọkan Agbaye níluu New York.
Ninu fọran to fi ransẹ si Ajọ Isọkan naa, adari Ukraine pe fun idasilẹ ileẹjọ to risi ogun jija lati gbe awọn ẹsun Russia yẹwo.
Aarẹ ni idasilẹ ileẹjọ naa ni yoo ṣe iranwọ lati fi ilu Moscow jofin fun bi wọn ṣe igba isakoso awọn agbegbe kan, ti wọn si tun ṣekupa ọpọlọpọ eeyan.
O ṣe agbekale awọn ilana bi afikun omo ogun ati bi wọn yoo ṣe fi iya jẹ Russia ni ita gbangba agbaye.
Afikun ọmọ ogun 300,000 fihan pe Putin ko nifẹ si igbesẹ alaafia - Zelensky
Ninu ọrọ rẹ, Zelensky fi ẹsun kan orilẹede Russia lori bi wọn se da gbogbo laasigbo silẹ pẹlu ogun ti ko lẹsẹ nilẹ.
O ni bi Russia ṣe ṣe ikede naa lana ti ṣe afihan pe Aarẹ Vladimir Putin ko nifẹ si isọrọ alaafia laarin orilẹede mejeeji.
Zelensky wa bu ẹnu atẹlu idunkoko Russia lati ṣe ikọlu si awọn agbegbe kan lorilẹede Ukraine.
O wa rọ awọn orilẹede agbaye lati ma ṣe dẹkun didabo bo awọn ọmọ orilẹede Ukraine, ki awọn orilẹede yooku si bọwọ fun awọn igberiko wọn.
Zelensky ni oun dupẹ lọwọ awọn orilẹede agbaye mọkanlelọgun ti wọn dibo pe oun ni anfani lati fi fọran ransẹ si ijokoo naa, ti wọn si fun oun laye lati ma wa si ilu New York.
Bakan naa lo sọ oko ọrọ si awọn orilẹede meje papa julọ Russia ti wọn tako bi o ṣe fẹ fi fọran ransẹ si ijokoo Ajọ Isọkan Agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Putin rán ọmọ ogún 300,000 mìí lọ kojú Ukraine, ariwo sọ

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti kede pe awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ti gbera lati lọ koju orilẹede Ukraine.
Putin ṣe ikede naa lori ẹrọ amohunmaworan ilẹ naa, to si ni awọn ni lati gbe igbesẹ lati dabobo awọn gberiko orilẹede na lọwọ ikọlu.
O tẹsiwaju pe awọn orilẹede to lagbara julọ lagbaye ni erongba lati ṣe buburu fun orilẹede Russia, nitori naa ni wọn ṣe purọ mọ oun lati ọjọ pipẹ.
Sugbọn o ni nibayii, Russia ni ohun ija lati fesi si gbogbo ọrọ wọn.
“A lo gbogbo ohun ija to wa ni isakoso wa lati daabo bo awọn eeyan wa, ti o si da mi loju pe ẹ ṣe iranlọwọ fun wa.”
Kí ní àwọn olórí àgbáyé yókù sọ lórí ìpinnu Russia?
Ukraine ti bori ogun yii na, idunkooko Russia ko si le dẹruba wọn - Ologun UK
Akọwe ọmọ ologun nilẹ UK, Ben Wallace ni igbesẹ Putin lati fi awọn ọmọ ogun ransẹ fi koju Ukraine, safihan pe Russia ti padanu ogun naa.
Wallace ni Russia ko tii ri aye lati wọle sinu Ukraine lo mu ko tun gbe akọtun igbesẹ yii..
“Putin ati minisita feto abo rẹ ti ran ọpọlọpọ awọn eeyan ilu wọn lọ si ogun aremabọ,
“Idunkoko kankan ko le dẹruba Ukraine nitori pe o ti han gbangba pe wọn ti bori ogun naa.”
"Akọtun iranwọ yoo dide fun Ukraine o dabi pe ẹru ti n ba Putin"
Aarẹ orilẹede Czech Republic, Petr Fiala ni bi orilẹede Russia ṣe kede pe oun ti ko akọtun ologun lọ koju Ukraine safihan pe Russia ti padanu ogun naa.
Fiala ni o ṣe koko ki iranlọwọ tubọ dide fun Ukraine ati pe orilẹede Czech Republic ko dẹkun lati maa ṣe iranwọ fun Ukraine.
Olootu Ijọba Germany, Robert Habeck ni igbesẹ Aarẹ Putin lo buru gidi gan, to si le ṣe akoba fun orilẹede naa.
Olootu ijọba orilẹede Holland, Mark Rutte ni ipe Aarẹ Putin safihan pe ẹru ti bẹrẹ si ni maa ba a ọpọlọpọ.















