"Buhari, àwọn olùkọ́, ọ̀gá àgbà fásitì kò gbọdọ̀ gbowó oṣù mọ́ torí ìyanṣẹ́lódì ASUU"

Oríṣun àwòrán, house_ngr/Instagram
Akẹkọọ fasiti kan, Soohemba Aker, ti sọ fun ile ẹjọ giga niluu Abuja pe ko pa lasẹ lati da owo osu Aarẹ ati awọn osisẹ agba miiran labẹ ijọba duro.
Akẹkọọ- binrin naa, to jẹ akẹkọọ imọ ofin ni Fasiti ipinlẹ Benue ni o ṣe koko pe ki ileẹjọ da owo oṣu awọn olori duro, lati ofisi Aarẹ lọ si ile gbimọ asọfin.
Aker ni gbogbo awọn minisita, ọga agba fasiti, akọwe ijọba, asofin ati ẹgbẹ ASUU ni ko lẹtọ si owo oṣu ti wọn n gba,
Akẹkọọ naa, ninu iwe ipẹjọ, FHC/ABJ/CS/1684/2022, ti agbẹjọro rẹ, Ckukwuma Machukwu Ume gbe kalẹ ni iyẹnsẹlodi ti ẹgbẹ ASUU gun le, n ṣe ọpọlọpọ akoba fun oun ati awọn akẹkọọ mii.
O ni erongba oun ati awọn akẹgbẹ oun lati pari eto ẹkọ lọdun 2022 ni ko le wa si imusẹ mọ nitori iyansẹlodi ti ASUU gunle.
Owo ileẹkọ ti mo ti san ti jona,
Aker ni o ti han gbangba pe owo ti oun san fun saa tuntun ni ile ẹkọ oun ni ko wulo mọ, ti ẹgbẹ ASUU ko ba le pada si ẹnu isẹ wọn.
Aker ni oun soju gbogbo akẹkọọ Naijiria ti iyansẹlodi si ti ṣe ọpọlọpọ ijamba fun awọn kaakiri orilẹede Naijiria.
Awọn olujẹjọ ti wọn fiwe pe ni ijọba apapọ, ẹgbẹ ASUU, Aarẹ ile igbimọ asofin, agbẹnugan ile gbimọ asofin kekere, awọn agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ.
Ni afikun, awọn olujẹjọ yoku ni Agbẹjọro agba fun ipinlẹ kọọkan, Olootu fasiti ti ilẹ Abuja, Gomina Abia, FAAC, RMAFC ati Umar Faruk.
Ipẹjọ naa ni wọn ko ti ri adajọ ti yoo lewaju rẹ.
ASUU fárígá lórí ìdájọ́ pé padà sẹ́nu iṣẹ́, ó kéde ìgbésẹ̀ tó kàn

Oríṣun àwòrán, ASUU
Ẹgbẹ awọn olukọ ni fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU, ti ni idajọ ti ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ gbe kalẹ, ko le tu irun kankan lara oun.
Lọjọru ni ileẹjọ naa ni pe ki wọn fi opin si iyansẹlodi ti wọn gun le lati ninu oṣu keji ọdun yii.
Amọ ASUU ni idajọ naa ni ko tẹ awọn lọrun, ti awọn si ti setan lati wọ ijọba apapọ lọ ileẹjọ kotẹmilọrun.
Alaga ẹgbẹ naa niluu Abuja, Dokita Kasim Umar lo kede bẹẹ nigba to fesi si idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ.
Umar ni awọn igbimọ alasẹ ẹgbẹ ASUU yoo ṣe ipade loni lati mọ ọna ti wọn gbe gba pẹlu ileẹjọ ko tẹmilọrun.
Agbẹjọro ẹgbẹ naa, Femi Falana naa ti fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ ASUU ti gbaradi lati wọ ijọba apapọ rele ile ẹjọ kotẹmolọrun.
Falana ni ẹjọ naa lawọn yoo pe lati tako idajọ ti Ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ gbe kalẹ lana.
Bakan naa, Olootu fasiti ti ilu Abuja, Ọjọgbọn Ahmed Modibbo Muhammed ti gba ijọba apapọ ni imọran lati fi suuru ba awọn ẹgbẹ olukọ fasiti ṣe.
Modeiboo ni asẹ ileẹjọ ko le tan rogbodiyan to wa laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ olukọ fasiti naa.
O wa rọ awọn igun mejeeji lati ṣe suuru, ki wọn si fi aye gba ibaraẹnisọrọ ni itubi-nubi lori ọna abayo si iyansẹlodi naa.
O tẹsiwaju pe ibaraẹnisọrọ ni itubi-nubi nikan lo le tan gbogbo rogbodiyan naa.
Ilé ẹjọ́ pàsẹ fún ASUU pé kó padà sẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ ti palasẹ fun ẹgbẹ olukọ fasiti lọrilẹede Naijiria, ASUU pe ko fi opin si iyansẹlodi to gun le.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti ijọba apapọ gbe wa si ile ẹjọ naa, Adajọ Polycrap Hamman fi ofin de ASUU lati mase tẹsiwaju pẹlu bo se n wosẹ niran.
Hamman ni titi ti igbẹjọ naa yoo fi wa sopin, ASUU gbọdọ maa sisẹ lọ.
Adajọ Hamman tun ni ki wọn da ẹjọ naa pada si ọdọ adajọ agba lati yan Adajọ tuntun fun igbẹjọ naa.
Adajọ naa ni iyanṣelodi ASUU ti ṣe ọpọlọpọ akoba fun awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria.
O ni oun gbe idajọ naa kalẹ nitori ihuwasi ASUU ni ko jẹ ki ọpọlọpọ awọn akẹkọọ, ti ko lagbara lati lọ sile ẹkọ adani, mase ni anfaani lati kawe.
Agbẹjọro ijọba, James Igwe ninu ọrọ rẹ rọ ileẹjọ lati pasẹ fun ASUU pe ko bẹrẹ isẹ lẹsẹkẹsẹ, ki igbẹjọ naa to wa sopin.
O ni ọrọ yii ti fa ọpọlọpọ ifasẹyin ba ilọsiwaju Naijiria nitori bí awọn akẹkọọ ṣe wa nile latinu oṣu kejì. LAipẹ yii ni ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU kede pe awọn ti ṣe adehun tuntun pẹlu awọn asofin apapọ Naijiria.
Awọn ikọ adari ile igbimọ asofin apapọ lo lewaju ipade oni wakati mẹrin, to bi adehun tuntun naa, eyi to waye ni ile gbimọ asofin niluu Abuja lọjọ isẹgun.
Adehun naa lo nilo ibuwọlu Aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to rin irinajo lati kopa nibi ijokoo Ajọ isọkan Agbaye niluu New York.
Emmanuel Osodeke lo lewaju fun ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ti minista fun eto ẹkọ, Goodluck Opiah si lewaju fun ijọba apapọ nibi ipade naa.















