"Babaláwo ní n kò ṣe lò làwọn tó fẹ́ fi mí ṣòògùn owó fi dá mi padà"
Ede Crisis: Baba Akogun ni Babaláwó rí àmìn ọ̀run lọ́wọ́ òun, ó ní ẹni ọ̀wọ̀ àti ẹran ọ̀hun ni òun tí kò ṣe fi ṣe owó torí ìjà Ṣàngó

Laipẹ la mu iroyin wa fun yin pe Họnọrebu Kofoworola Babajide ti ọpọ eeyan mọ si Akọgun nilu Ede, to tun jẹ olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere ju nile asofin ipinlẹ Osun kede pe oun ti ri baba oun tawọn n wa.
Idi ree ti BBC Yoruba fi gba ilu Ede lọ lati lọ gbọ tẹnu baba naa nipa ọna to gba bọ ni akata awọn to ji gbe salọ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alagba Mudasiru Lawal naa ni ori lo ko oun yọ lọwọ wọn.
O ni ọkada ni wọn fi gbe oun kuro nile oun nilu Ede, ti wọn si gbe oun lọ sile Babalawo kan.
O ni erongba wn ni lati fi oun se oogun owo amọ ti ẹlẹda oun ko jẹ.
"Amin ọrun to wa lọwọ mi ati Sango ti idile iyawo mi n bọ, lo ko mi yọ"
Alagba Lawal tẹsiwaju pe babalawo ti wọn gbe oun de ọdọ rẹ beere lọwọ ifa boya ẹran to se lo fun oogun owo ni oun.
Amọ o ni se ni ifa yari, ti babalawo naa si beere pe orisa wo ni wọn n bọ ninu idile awọn.
“Mo sọ fun wọn pe awa ko ni orisa amọ wọn maa n bọ Sango ninu idile iyawo mi.
Babalawo naa ni abajọ, to si tun ri amin ọrun kan ni ara oun, to si beere pe ki lo wa fun.
Mo si sọ fun pe lati ọrun ni oun ti mu amin naa wa, o wa sọ fun awọn to gbe mi wa pe ẹran ọwọ ni mi, ti n ko si se lo fun oogun owo.
O tun fikun pe ti awọn to gbe mi wa ko ba fẹ ki Sangho pa awọn, yoo dara ki wọn tete gbe oun pada sibi ti wọn ti gbe oun.
Bàbá aṣòfin tí wọn ń wá ní Ede ti dé lẹ́yìn oṣù méjì, ó sọ̀rọ̀ lórí ìrírí rẹ̀
saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe bàbá asofin Adewunmi Kofoworola Babajide, tii se Olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Alagba Muftau Lawal, ti pada wale.
Bẹẹ ba gbagbe, ọmọ rẹ, Asofin Koforola naa lo ń ṣojú ẹkun idibo Àríwá Ede, lo pariwo pe oun ko ri baba oun mọ lasiko laasigbo oselu to waye nilu Ede laipẹ yii.
Lasiko rogbodiyan naa si ni wọn jo ile ti Asofin Kofoworola kọ fun baba rẹ naa, ti wọn ko si ri oku tabi aaye baba naa nigba naa.
Amọ iroyin kan ti asofin Kofoworola fi soju opo Facebook rẹ lọjọ Ẹti to kọja ti salaye pe Baba oun ti de.
"Awọn Ọlọpaa lo pe mi lori foonu pe wọn ti ri baba mi nilu Lokoja nipinlẹ Kogi, ti wọn si ti n seto bi yoo se pada wa sile.
Bi inu mi tilẹ dun pe wọn ti ri baba mi amọ inu mi ko dun si awọn iriri ti ko dara to seese ko ni ni akata awọn eeyan to ji gbe naa.
Mo wa dupẹ pupọ lọwọ gbogbo awọn eeyan to duro ti mi lasiko isoro naa, mo si lero pe Baba mi ko ni ni irora nipa ilera rẹ nitori awọn ohun to ti la kọja naa."
Ọkada ni wọn fi wa ji mi gbe niwaju ile mi - Alagba Lawal
Alagba Lawal wa salaye lori iriri rẹ fawọn akọroyin lẹyin to ti akata awọn ajinigbe de, eyi ti ọmọ rẹ fi soju opo Facebook rẹ.
Ó ní ṣàdédé ni òun rí tí àwọn kan gbé ọ̀kadà wá bá òun ní ẹnu ọ̀nà ilé òun tí wọ́n sì ń dúnkokò mọ́ òun pé òun máa pa òun tí òun kò bá pàdé wọn.
"Iwájú ilé ni mo wà ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà tí mò ṣàdédé rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ya wọ ilé mi lórí ọ̀kadà."
"Lẹ́sẹ̀ kan náà ni àwọn ọmọ tí wọ́n wà níwájú ilé tí wọ́n ń ṣeré kọ́kọ́ sá dànù."
"Àwọn ajínigbé náà wá ń sọ fún ara wọn pé kí àwọn yìbọn fún mi tàbí kí wọ́n jó mi ní ààyè."
Ó ní lẹ́yìn tí àwọn yẹn lọ tán ni àwọn mìíràn tún dé pẹ̀lú ọ̀kadà tí wọ́n sì ní kí n gun orí ọ̀kadà.
Ọ̀nà Ilesa ni wọ́n gbé mi gbà kí n tó bá ara mi nílé babaláwo
"Mo bèrè wí pé níbo ni wọ́n ń gbé mi lọ, tí ọ̀kan nínú wọn sì fún mi lésì wí pé àwọn ń gbé mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọmọ mi, Akogun."
"Nítorí ọjọ́ orí mi, ojú mi kò ríran dada mọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe díẹ̀ mo ri wí pé ọ̀nà Ilesa ni wọ́n ń gbé mi lọ."
"Nígbà tó tún ṣe díẹ̀ ni mo tún bèrè wí pé níbo ni wọ́n ń gbé mi lọ ṣùgbọ́n wọ́n fèsì wí pé tí mo bá tún bèrè ọ̀rọ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn, àwọn ma pa mí síbẹ̀."
"Ilẹ̀ ti ń ṣú ní gbogbo ìgbà tí à ń sọ yìí tí wọ́n sì ń sáré gidigidi lórí eré mi ò sì le rí nǹkankan mọ́."
Alagba Lawal tẹ̀síwájú pé nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn dé ilé kan tí babaláwo wà nínú rẹ̀ tó sì ń dífá.
Alagba Lawal ní díẹ̀ ló kù kí wọ́n fi òun ṣe oògùn owó ni ahamọ ti oun wa.
Babaláwo ní kí àwọn tó jí mi gbé wá gbé mi padà nítorí mi ò ṣé lò
Ó ní lẹ́yìn tó pọfọ̀ ló bèèrè lọ́wọ́ òun pé ṣé òun ní òrìṣà kankan tí wọ́n ń bọ ní ìdílé àwọn tí òun sì fún lésì pé rárá ṣùgbọ́n àwọn ìyàwó òun máa ń bọ Ṣàǹgó.
Ó fi kun pé ìgbà náà ni babaláwo náà pe àwọn tí wọ́n gbé òun wá pé kí wọ́n wá gbé òun padà nítorí òun kò ṣé lò.
Ó ṣàlàyé pé àwọn tó gbé òun lọ sí ọ̀dọ̀ babaláwo náà kò padà wá fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí wọ́n tó wá gbé òun ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Ó ní nígbà tí wọ́n wá gbé òun ní àárín òru ni wọ́n gbé òun sínú ọkọ̀ kan tó gbé òun lọ sí ìlú Lokoja.
Alagba Lawal fi kun pé nígbà tí òun dé Lokoja ni òun lọ sí àgọ́ Ọlọ́pàá láti lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó wọn létí tí wọ́n sì kan sí àwọn ènìyàn òun ní ìpínlẹ̀ Osun.
"Nígbà tí mo dé Osun, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi to sì ṣèlérí láti wá ìdí ọ̀rọ̀ náà láti mọ àwọn tó ṣiṣẹ́ náà kí òun tó padà sí ìlú Ede."
Baba agba naa ní ọlọ́pàá ló fún òun ní bàtà tí òun wọ̀ padà sí Osun nítorí aṣọ kan tí òun wọ̀ ló wà ní ọrùn òun.
Alagba Lawal wá rọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti fojú àwọn aṣebi tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà hàn.
Ki lo ti waye sẹyin?
Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kẹjọ ọdún yìí ni ni wọn fi ẹsun kan olórí ọmọ ẹgbẹ oselu to kéré jùlọ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Kofoworola Babajide
Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ni wọọdu kan nilu Ede ni o ń fi ọlọ́pàá dúnkokò mọ́ àwọn níbi ìpàdé ẹgbẹ́ wọn kàn to waye nilu naa.
Nígbà ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀, ènìyàn méjì ni ọta ìbọn pa, Abideen ati Kafayat Olalekan, ti awọn mejeeji si wa latinu ẹbi kan soso.
Ẹ̀wẹ̀, Babajide jiyàn gbogbo ẹ̀sùn náà wí pé àwọn kan lọ sí ilé bàbá òun, tí wọ́n jó ibẹ̀ níná, kí wọ́n tó jí gbé.

















