Àwọn Olùdíje, Òjísẹ́ Ọlọ́run gbàdúrà nínú òjò ṣáájú ìbò 2023

Oríṣun àwòrán, others
Bi igbaradi ṣe n sunmọ lori idibo lọdun 2023, awọn oludije si oniruuru ipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ akanṣe adura fun aseyori ẹgbẹ oṣelu naa.
Awọn ojisẹ Ọlọrun kaakiri gbogbo ẹsin peju si ọọfisi ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Abeokuta lọjọ Aje.
Nibẹ ni wọn si ti gbadura si Ọlọrun fun awọn ti yoo ma rin irinajo fun iponlogo ati aseyọri nibi eto idibo naa.
Lẹnu akanṣe adura ọhun ni ojo ti bẹrẹ, ti awọn Ojisẹ Ọlọrun ati awọn oludije si kọ lati kuro ninu ojo, ti wọn kẹnu bọ adura fun ẹgbẹ PDP naa.
"A n gbadura lati le erongba buruku kuro lori PDP la se n gbadura"
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn gbe adura naa kalẹ lati beere fun aabo Ọlọrun ati lati gbogun ti gbogbo erongba buburu ti ẹgbẹ alatako gbero si ẹgbẹ oṣelu naa.
Ninu ọrọ rẹ, oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ladi Adebutu ni gbogbo ọna ni ẹgbẹ oṣelu PDP n gba lati se aseyori ninu idibo ọdun 2023 pẹlu atilẹyin ara ati ẹmi.
Oludije sipo gomina naa wa gbadura aseyọri fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa to n kopa ninu eto idibo, lati ori aaarẹ si igbimọ aṣofin.
O ni ọpọ igba ni ọrọ eto idibo ko ni jẹ ki oun ri oorun sun, ti oun si ti pinnu pe oun ko ni dẹkun lati ma ṣe ohun to tọ fun idagbasoke ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, others
"PDP nilo adura ni awọn obinrin se seto adura ọhun"
Adebutu tẹsiwaju pe kii ṣe nitori owo ni oun fẹ fi jẹ gomina ipinlẹ Ogun sugbọn lati ri pe awọn eeyan ipinlẹ naa ko jiya rara, ki ipinlẹ naa si ni ilọsiwaju.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP , Dokita Sunday Solarin ni ẹgbẹ oṣelu naa nilo adura lati ti fi gbogun ti erongba awọn alatako, ti wọn fẹ da eto alaafia ẹgbẹ oṣelu naa ru.
Folarin ni akanṣe adura naa lo jẹ akọkọ iru ẹ, ti awọn igun obinrin ẹgbẹ oṣelu naa gbe kalẹ.
Woli kan wọ gàù fún ẹ̀sùn pé ó na àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀

Woli kan lorilẹede Uganda to ti wọ gau lori ẹsun ifiyajẹni ati ijinigbe ti wọn fi kan-an.
Woli naa, Kintu Dennis ti ile ijọsin Hoima Empowerment Church International ni a ri ninu fidio, nibi to ti n fi ẹgba naa awọn ọmọ ijọ rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa fi panpẹ ọba mu oun ati awọn ọmọ ijọ rẹ mẹrin lẹyin ti awọn eniyan fi aidunnu wọn han nipa fidio naa.
Bi Jesu ṣe ṣe fun awọn to n na ọja ninu tẹmpili ni mo se fun awọn ọmọ alaigbọran ijọ mi - Woli Kintu
Ohun to ṣe ni pe o paṣe fun awọn oṣiṣẹ ni ṣọọṣi rẹ lati jade si ita, ki wọn si maa na awọn ọmọ ijọ naa tabi ki wọn ma wa si ile ijọsin rẹ mọ.
Ni gbogbo asiko yii ni awọn eniyan n wo bi o ṣe n na awọn oṣiṣẹ ijọ rẹ naa.
Amọ ninu ọrọ rẹ, Woli Kintu ni bi Jesu ṣe ṣe fun awọn to n na ọja ninu Ṣọọṣi tabi tẹmpili ni oun se fun awọn ọmọ alaigbọran ijọ oun.
Bakan naa ni ijọba fẹsun un kan pe ijọ rẹ ko gba iwe aṣẹ kankan, ko to bẹrẹ rẹ.
Iwadii fihan pe ẹgba mẹta lo wa ninu ile ijọsin naa, ti wọn fi n na awọn eniyan.
Wọn ti fi Wolii naa atawọn mẹrin yoku si ahamọ ọlọpaa titi di jọ Keje, Oṣu Kẹsan, ọdun 2022.
Ọpọlọpọ ijọ lo wa ni Uganda, ti ko si ẹnikẹni to n yẹ wọn ni ọwọ wo.
















