‘’Ebi ń pa wá, a kò rí oúnjẹ jẹ nítorí aàrùn Covid-19’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awon olugbe agbegbe ti wọn ti pasẹ ofin konile-o –gbele ni orilẹede China ri ni awọn ko ri ounjẹ jẹ ati ohun igbaye gbadun miran.
Ẹgbẹgbẹrun miliọnu awoṇ eniyan ni bi agbegbe ọgbọn ni wọn ti paṣẹ fun lati duro ni ile lasiko ofin konile o gbele naa.
‘’O ti le ni ọjọ marundinlogun ti ijọba ti paṣẹ – ko si irẹsi, ẹyin ati ounjẹ miran paapaa miliki fun awọn ọmọ kekeeke.’’
Ijọba ṣi n tiraka lati koju ajakalẹ aarun coronavirus naa to tun gberasọ lẹyin ti adinku waye nibẹ.
Ni ọjọ Aje, ni orilẹede China kede eniyan to fẹrẹ tọ ẹgbẹrun kan to ni aarun coronavirus tuntun nibẹ.
Ni ori ayelujara ni awọn eniyan ti n bẹbẹ fun iranwọ paapaa ni Xinjiang, to sunmo. Ibode Kazakhstan.
Bakan naa ni fidio kan ṣe afihan arakunrin Uyghur to bẹbẹ nitori awọn ọmọ rẹ mẹta ti ko I tii jẹun fun ọjọ mẹta.
‘Mi o ni owo lati ra ounjẹ fun idile mi. iyawo mi wa ninu oyun a si ni ọmọ meji.’’
Arakunrin to siọ iriri rẹ naa ni afẹfẹ gaasi naa ti tan bakan naa ni iyawo rẹ si nilo ayẹwo.
Saaju ni ajọ Iṣọkan Agbaye, UN fi ẹsun kan orilẹede China wi pe wọn n dẹyẹ si awọn ara agbegbe Ugyhur nitori wọn jẹ musulumi.
Iwadii fhan wi pe wọn ko fun awọn eniyan ni iroyin to peye ki wọn to paṣẹ ki onile-o gbele nitori ajakalẹ arun Coronavirus.
Bakan naa ni ijọba ko tun fun awọn eniyan laaye lati kuro ni agbegbe kan si omiran nitori itankalẹ arun naa.












