A kò fẹ́ ki Bàbá Charles Olumo jẹ ìrora kú, ìnira àìsàn wọn pọ̀ - Aya ọmọ Agbako

Àkọlé fídíò, Charles Agbako: N kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀, ara ń ni mí
A kò fẹ́ ki Bàbá Charles Olumo jẹ ìrora kú, ìnira àìsàn wọn pọ̀ - Aya ọmọ Agbako

Charles Agbako: Mo nílò òògùn òòrè-kóòòrè kí ń tó le è ní ìtura, Ọkùnrin ni mo fi ń gbé e

Agbako ati aya ọmọ rẹ

Laipẹ yii la mu iroyin wa fun yin pe ojojo n se ogun Baba agba lagbo tiata, Charles Olumo, ti ọpọ eeyan mọ si agbako.

Agbako, tii se odu, ti kii se aimọ fun ologbo lagbo tiata lede Yoruba lo ti dubulẹ aisan naa lati bii osu mẹta sẹyin.

Ninu fidio yii ni agbako funra rẹ ati aya ọmọ rẹ, Olamide ti ba BBC Yoruba sọrọ nipa ipo inira ti agba osere tiata naa n la kọja.

Gẹgẹ bi Agbako ti wi, ọkunrin ni oun fi n gbe inira naa, ti awn dokita si sọ pe oun nilo lati maa lo oogun oore koore, lati mu inira naa ku.

Baba Agbako ni owo to le diẹ ni igba naira ni dokita sọ pe oun nilo lati maa ra oogun naa lati igba de igba nitori oun ko le se isẹ abẹ mọ.

Agbako wa n bẹbẹ fun iranwọ awọn ololufẹ rẹ, ki inira naa le dinku.

A ko fẹ ki baba ku sinu irora, ara n ni wọn – Olamide, aya ọmọ Agbako

Nigba oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ ninu fidio yii, Olamide, tii se aya ọmọ baba naa kaanu pupọ nipa ipo inira ti baba ọkọ rẹ wa.

Olamide ni “Baba Agbako ti n sọ pe ti oun yoo ba ku, ki oun kuku ku nitori inira naa pọ amọ a ko gbadura pe ki baba naa ku sinu irora yii.”

O ni lootọ ni Agbako se isẹ abẹ amọ ko jẹ ki egbo naa jinna to tun fi bẹrẹ isẹ tiata pada eyi to mu ki aisan naa gbodi lọ lara rẹ.