Falana sòkò ọ̀rọ̀ sì agbẹnusọ Ọlọ́pàá tó ní aráàlù kò le gbẹ̀san, bí ọlọ́pàá bá gbá a létí

Oríṣun àwòrán, others
Gbajugbaja Agbẹjọro to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti bu ẹnu atẹlu lu ọrọ kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi sọ lori ayelujara lori bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ṣe ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa.
Adejobi ni ọlọpaa to ba wa ninu asọ idanimọ rẹ ni ẹtọ lati gba oju ẹnikẹni, ti ko si yẹ ki ẹnikẹni le ṣe ikọlu ọlọpaa.
O tẹsiwaju pe arifin, abuku ati tita ẹrẹ si orilẹede Naijiria ni ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria maa gbiyanju lati ṣe ikọlu si ọlọpaa.
“Ti ọlọpaa to ba wa ninu asọ idanimọ rẹ ba gba oju araalu, ẹni naa ko ni anfani lati gba ẹsan.
Si ṣe ikọlu si ọlọpaa ni o da bi pe eeyan ṣe ikọlu su orilẹede Naijiria.
“Abuku yii ki n ṣe ti ọlọpaa nikan sugbọn gbogbo orilẹede Naijiria.
“O lo di ofin, ti o si sapejuwe ẹni to ba ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ọdaran.”

Oríṣun àwòrán, @Princemoye1
Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n wà lábẹ́ òfin fún ọlọ́pàá tó bá fìyà jẹ aráàlú - Falana
Nigba ti yoo fesi si ọrọ naa, Femi Falana ni si ṣe ikọlu si ọmọ orilẹede Naijiria labẹ ofin ni ijiya ọdun mẹẹdọgbọn ni ọgba ẹwọn, ti ko si yọ ileeṣẹ ọlọpaa silẹ.
Falana ni labẹ ofin ọdaran lọdun 2015 ati ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ọdun 2020, ko fi aye gba ọlọpaa tabi awọn agbofinro yoowu lati ṣe ikọlu si ẹnikẹni.
“Koda ẹni ti ile ẹjọ ko ti da lẹbi ni anfani si ofin yii, awọn ko gbọdọ fi iya jẹ ẹnikẹni ni ọna aitọ.
“Ninu iwe ofin orilẹede Naijiria, ẹni to ba ti jẹ ọmọ orilẹede yii ni wọn ni anfani si ẹtọ ọmọniyan, wọn ko si gbọdọ fi iya jẹ wọn ni ọna aitọ
“Ijiya fun ẹnikẹni ti wọn ba ba iwa ibajẹ naa lọwọ rẹ ni yoo fi ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn gbara tabi ko san owo itanran.”
Falana wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati dẹkun sise ikọlu si awọn ọlọpaa nitori ohun naa ni ijiya tiẹ labẹ ofin.
O ni ọdun mẹta ni ẹnikẹni to ba se ikọlu si ọlọpaa labẹ ofin.















