"Mo fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ nínú yàrá kan tí èmi, aya àti ọmọ mẹ́fà ń gbé"

Oluwole Olusegun

Oríṣun àwòrán, @OgunPoliceNG

Ọwọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti ba baba kan, Olusẹgun Oluwole tii se ẹni ọdun mẹrindinlaadọta fun ẹsun pe o fi tipa ba ọmọdebinrin rẹ lopọ.

Ikede kan ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fisita loju opo Twitter rẹ lo sisọ loju eleyi pẹlu afikun pe agbebe Amolaso nilu Abeokuta ni isẹlẹ naa ti waye.

Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa Ogun ti wi, ọmọdebinrin naa lo mu ẹjọ baba rẹ tọ agọ ọlọpaa Ibara lọ lati fi ipalara ti Oluwole se han wọn.

Ọmọdebinrin naa, tii se ẹni ọdun mẹtadinlogun, ni baba rẹ fipa ba lopọ lasiko to n sun lọwọ ninu ile oniyara kan ti wọn n gbe ni deede aago mọkanla abọ.

"N ko mọ ohun to ta le mi, ti mo se fi tipa ba ọmọ mi lopọ"

Ọmọ naa ni “Nigba ti baba mi ri pe awọn eeyan yoku ti sun lọ fọnfọn, se ni wọn sadede ki mi lapa lojiji, ti wọn si fipa ba mi ni ajọsepọ.

Wọn wa n dunkooko mọ mi pe ti n ko ba gba, ki awọn ba mi lopọ, awọn yoo pa mi ni.”

Ileesẹ ọlọpaa ni, ni kete ti ẹsun naa to awọn leti, ni ọga ọlọpaa Ibara, Bernard Egbondiya nawọ gan afurasi ọhun.

Nigba ti wọn wa fi ọrọ wa Oluwole lẹnu wo, Oluwole, to bi ọmọ mẹfa, wa n bẹbẹ fun idarijin lọwọ awọn ọlọpaa.

Oluwole ni “N ko tiẹ mọ ohun to ta le mi, ti mo fi hu iwa yii, ti mo si fipa ba ọmọ mi lopọ.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

A ti gbe ọmọbinrin ti baba rẹ fi tipa ba lopọ lọ sile iwosan - Ileesẹ Ọlọpaa Ogun

Wayi o, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti wa pasẹ pe ki wọn mu afurasi naa lọ si ẹka ileesẹ ọlọpaa to wa fun iwa ọdaran fun iwadii to yẹ.

O ni lẹyin iwadii ẹka naa, ni ki wọn gbe Oluwole lọ sile ẹjọ, ko le gba idajọ to yẹ lọdọ ijọba.

Bakan naa lo ni ki wọn tete mu ọmọdebirin naa lọfun itọju nmile iwosan.

Oníṣègùn hú òkú ní ìbojì Mùsùlùmí l‘Osun, bẹ́ orí, kó ìfun rẹ̀

afurasi Babalawo

Oríṣun àwòrán, Osun Police

Awọn ẹgbẹ ọdẹ ibilẹ ni ilu Ede ni ipinlẹ Osun ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Ismail Adewuyi.

Ẹsun ti wọn fi kan Afurasi naa ni pe o ṣe ji ori ati ifun oku ọmọbinrin kan ni itẹ oku awọn musulumi to wa ni Oke Yidi, niluu Ede.

Adewuyi, ẹni ti wọn ba ọpọlọpọ ogun lara rẹ, lo ṣe ikọlu si itẹ oku naa ni owurọ ọjọ Satide, to si wu oku naa sita lati bẹ ori ati lati ko ifun rẹ.

Wọn ni kete ti o fẹ kuro ni itẹ oku naa lo bọ sọwọ ọkan lara awọn ọdẹ agbegbe naa, ni dede ago kan orun.

Onisegun naa ti wa ni agọ wa, iwadii n lọ lwọ - Ọlọpa Osun

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola ni ọwọ ti tẹ okunrin oniṣegun naa, ti iwadi si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Opadola ni “Lowurọ ọjọ Satide, ni bi iṣẹju diẹ kọja ago kan, ni ọwọ ọkan lara ẹgbẹ ọdẹ tẹ Adewuyi Ismail lati Oke Ola, Agbagudu ni Ede.

Wọn si mu wa si agọ ọlọpaa pẹlu ori ọmọbinrin kan to ji gbe ati awọn ifun pẹlu.

“Afurasi naa ti wa agọ wa, ti iwadi si ti ibẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.”

Ọwọ́ tẹ ọkùnrin méjì tó ń fipá bá obìnrin kan lòpọ̀ nínú ọkọ̀ ní Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ikọ itẹmuyẹ to n risi ọrọ pajawiri, Rapid Response Squad (RRS) ti fi panpẹ ọba mu awọn ọdọlangba meji fun ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko.

Ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun to jẹ alajota ni awọn ti wọn n fi ẹsun kan pe wọn n fi ipa balopọ ni inu ọkọ Nissan ni agbegbe Alausa ni Ikeja, Eko.

Awọn ti wọn fẹsun kan naa ni Solomon Barry ati Omega Bright, ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati ẹni ọdun mejidinlogoji.

Iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi aago mẹta ooru ni ilu Eko

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ninu atẹjade ni wọn fi idi ọrọ naa mulẹ.

O ni awọn oṣiṣẹ naa wa lẹnu iṣẹ ni wọn ri i pe wọn wa ọkọ naa gunlẹ ninu Nissan naa, ki wọn to ri ohun to n ṣẹlẹ ninu ọkọ naa.

‘’Nigba ti awọn oṣiṣẹ naa de ibẹ ni wọn ri i pe obinrin naa ko mi mọ, ti ko si gbo ohun ti awọn ọlọpaa n sọ.’’

‘’Lẹyin naa ni wọn gbe lọ si olu ileeṣẹ wọn fun iwosan to si ji pada.’’

Bakan naa ni iwadii fihan pe agbegbe Ile Itaja Ikeja Shopping Mall, Alausa ni wọn ti gbe obinrin naa to si gba pe ki wọn gbe oun kaakiri, ki wọn to lọ si ile itura.

Ileeṣẹ RRS naa ni wọn ti gbe iṣẹlẹ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii ọrọ obinrin.