Pásítọ̀ wọ gàù lórí ẹ̀sùn ìjínigbé àti ìṣekúpa ‘nọ́ọ̀sì‘

Oríṣun àwòrán, GEORGINA ASOR BOTCHWEY
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Ghana ti fi ṣikun ofin mu pasitọ kan ti wọn fẹsun kan pe o ji ọdọbinrin akẹkọọ nọọsi kan gbe.
Bakan naa, wọn tun fi ẹsun apaniyan kan-an tori bi wọn lo se gbẹmi obinrin naa lagbegbe Mankessim.
Awọn ọlọpaa ti wu oku obirin naa bayii nibi ti pasitọ naa ati ẹni ti wọn jọ ṣiṣẹ laabi ọhun, sin oloogbe naa si.
Ni bayii, wọn ti n wa afurasi keji to n ba pasitọ naa ṣiṣẹ, iyẹn oloye kan, Nana Clarke.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ohun ti a mọ nipa iṣekupani naa ree:
O ti to ọsẹ kan ti oloogbe-binrin ọhun, Georgina Asor Botchwey ti di awati ti wọn si ti n wa kiri.
Iroyin ni ṣe ni akẹkọọ naa lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo kan nile ẹkọ Ankaful nursing training school, nibi ti wọn ti n kọ awọn eeyan lẹkọọ nọọsi.
Lati igba naa, ko si ẹnikẹni to gbọ ohunkohun nipa rẹ, bẹẹ si ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ ko wọle.
Idi ree ti awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ rẹ bẹrẹ si n ke gbajare lori ayelujara.
Asiko ti iwadii bẹrẹ ni ọlọpaa ni awọn fura si pasitọ naa, lẹyin iwadii wọn, o si jẹwọ pe lootọ ni oun lọwọ ninu iku obinrin ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ọpọ araalu n fẹ idajọ ododo lọwọ ọlọpaa
Ẹwẹ, awọn eeyan lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ti ke si ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni Ghana lati wa ojutu si oniruru iṣẹlẹ iṣekupani to n waye nibẹ.
Aṣofin to n ṣoju agbegbe ọhun, Cephas Arthur sọ pe “Igba karun un ree ti irufẹ nnnkan bayii yoo waye ninu ọdun yii nikan ṣoṣo.
Mo si fẹ ki awọn ọlọpaa fi imu pasitọ naa ati oloye ti wọn jọ ṣiṣẹ papọ danrin.”
Wọn ti gbe oku oloogbe ọhun lọ sile iwosan Cape Coast Teaching Hospital bayii fun ayẹwo ati iwadii ni kikun.












