Iléẹjọ́ tí rán Ọlọ́pàá tó ṣekúpa Kolade Johnson lọ sí ẹ̀wọ̀n igbere

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES/STYLES KOLADE JOHNSON
Ileẹjọ ti ran osisẹ ileeṣẹ ọlọpaa nigba kan ri, Olalekan Ogunyemi lọ si ẹwọn gbere.
Idajọ naa lo waye lẹyin ọdun mẹta ti wọn fi ẹsun kan-an pe o pa ololufẹ ere bọọlu kan, Kolade Johnson.
Adajọ Adenike Coker, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọbọ pe ki ọlọpaa naa wa ni atimọle ayeraye.
Johnson lo padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale, SARS ṣe ikọlu si agbegbe Mangoro ni ipinlẹ Eko.
Wọn yinbọn fun Johnson ni isalẹ ikun, to si gba ibẹ ku.
Awọn aladugbo ti ọrọ naa ṣoju wọn ni idije bọọlu alafẹsẹgba laarin Liverpool ati Tottenham ni oloogbe ọhun wa wo nile olounjẹ adugbo, ki ọlọjọ to de.
Wọn ni awọn SARS naa ti pinnu lati gba ẹjẹ eeyan ninu ọrọ ẹnu wọn bi wọn ṣe de adugbo naa tẹlẹ.
Koda wọn ni oju ara nkan ọmọkunrin Kolade ni ibọn ikẹta ti ọlọpàa SARS naa yin ti baa ko to ku ki wọn to gbee de ilé iwosan
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Adenike Coker ni olujẹjọ jẹbi ẹsun ti wọn fi kan, fun idi eyi, ko ma lọ igbesi aye rẹ yoku ni ọgba ẹwọn.
O tẹsiwaju pe Olalekan mọmọ ṣekupa ọmọdekunrin nani
Àwọn eégún yawọ ṣọ́ọ̀ṣì, na olùjọ́sìn, ba dúkìá ìjọ jẹ́

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ń ṣe ni ọ̀rọ̀ dàbí eré orí ìtàgé ní ilé ìjọsìn kan lánàá ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 nígbà tí àwọn elégún yawọ ilé ìjọsìn náà.
Awọn olùjọsìn ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nígbà tí àwọn eégún náà yabò wọ́n, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní na ọmọdé àti àgbà.
Lásìkò tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn eégún náà yawọ ilé ìjọsìn náà tó wà ní ìlú Shikal, ìjọba ìbílẹ̀ Langtang, ìpínlẹ̀ Plateau tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní na gbogbo àwọn olùjọsìn.
Bákan náà ni ìròyìn ní yàtọ̀ sí wí pé wọ́n na àwọn olùjọ́sìn, àwọn dukia ìjọ náà ni àwọn eégún náà tún bàjẹ́.
Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà - CAN
Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Krìsìtẹ́nì (CAN) ti ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Plateau ní àwọn àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí sí ohun tó ṣokùnfà ìdí tí àwọn elégún náà ṣe gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí.
Alága ẹgbẹ́ CAN ìpínlẹ̀ Plateau, Ẹni ọ̀wọ̀ Polycarp Lubo, nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ohun ìyàlẹ́nu ńlá ni ìròyìn náà jẹ́.
O ni iwa títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú ni pẹ̀lú.
Ẹni ọ̀wọ̀ Lubo ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìjọsìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kò ì tíì fi isẹlẹ naa tó àwọn létí àmọ́ àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti wá fìn-ín ìdí kókò ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
"Bí mo ṣe rí fídíò náà lórí ayélujára, ọkàn mi gba ọgbẹ́, tó sì ká mi lára gidi gan."
"Mi ò tíì lè sọ pé òótọ́ tàbí irọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ ohun tó dájú ni pé a ò ní kawọ́ lẹ́ràn, a máa wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan."
Lubo fi kun pé láti agbègbè náà ni akọ̀wé ẹgbẹ́ CAN ìpínlẹ̀ náà ti wá, tí òun sì ti pè é láti ṣèwádìí ilé ìjọsìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, kó sì jábọ̀ fún òun.
Ó fi kun pé ní kété tí àwọn bá ti ṣèwádìí tí àwọn sì mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ni àwọn yóò fi ìròyìn léde.

Oríṣun àwòrán, TWITTER















