Baba Ijesha lulẹ̀ nílé ẹjọ́ fún ìgbà kejì

Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ niluu Eko ti kọ lati gba beeli oṣere tiata Yoruba, James Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, ṣaaju ki wọn to bẹrẹ igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ.
Adajọ Oluwatoyin Taiwo da ipe fun beeli naa nu nitori Baba Ijesha ko ni awọn amuyẹ to tọ lati kunju oṣuwọn fun beeli naa.
Nigba to n dajọ lori beeli ọhun, adajọ sọ pe Baba Ijesha gbọdọ ṣe afihan awọn eredi pataki ti wọn fi gbọdọ fun ni beeli naa, eyii ti ko ṣe.
O tun ni ko si ẹri pe ọdaran naa ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tabi ẹri kankan pe ile ẹjọ yoo fi ẹjọ kotẹmilọrun rẹ falẹ.
Beeli wo ni Baba Ijesha n beere fun?
Gẹgẹ bii iwe ti agbẹjọro rẹ kọ siwaju adajọ, oṣere naa n fẹ ki ile ẹjọ fun oun ni beeli ki oun ma lọ sile lọna ati le pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ẹwọn ọdun marun run ti wọn da fun.
Ojọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii ni agbẹjọro rẹ, Gabriel Olabiran, sọ fun ile ẹjọ pe awọn ti pe igbejọ fun beeli ọdaran naa, ṣaaju ipẹjọ kotẹmilọrun.
To n tumọ si pe, Baba Ijesha n fẹ ki wọn fun oun ni beeli ki oun le kuro ninu ọgba ẹwọn lati maa gba ile lọ sile ẹjọ fun igbejọ kotẹmilọrun, kaka ko maa ti inu ọgba ẹwọn lọ sile ẹjọ ọhun fun igbẹjọ kotẹmilọrun naa.
Igbesẹ yii lo wa ni ibamu pẹlu abala kẹfa iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999, ati afikun rẹ ni abala kọkanlelaadọta to waye nile ẹjọ giga kan nilu Eko.
Olabiran ni awọn gbe ọrọ naa lọ siwaju ile ẹjọ adajọ Oluwatoyin Taiwo lẹyin to ṣoro fun awọn lati gba ọjọ ipẹjọ nile ẹjọ kotẹmilọrun.
Amọ agbeọjọro ijọba, Yusuf Sule tako igbesẹ naa pẹlu ipẹjọ tirẹ pe ko si eredi kankan ti ile ẹjọ fi gbọdọ fun Baba Ijesha ni beeli titi ti igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ yoo fi bẹrẹ.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2022 yii ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipanilopọ yii ṣedajọ ẹwọn ọdun maru un fun Baba Ijesha, lẹyin to jẹbi mẹrin ninu ẹsun mẹfa ti wọn kan an, eyii to ni ṣe pẹlu ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde ti ọjọ ori rẹ ko tii to mejidinlogun.
Igbesẹ to kan fun Baba Ijesha
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba lẹyin ti ile ẹjọ kọ lati gba beeli ọdaran naa, agbẹjọro rẹ, Gbariel Olabiran sọ pe oun ṣi ni ireti pe onibara oun yoo bọ ninu ọgba ẹwọn to wa.
O ni “Ẹjọ ti a pe ni pe ki ile ẹjọ tu silẹ ko maa wa lati ile fun igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ, amọ ile ko gba aba wa wọlẹ.”
“A ti pe ẹjọ nile ẹjọ kotẹmilọrun nile ẹjọ giga, a dẹ mọ wi pe a ni awọn ohun ti ẹjọ wa to fẹsẹ mulẹ ti a fi mọ pe wọn maa fun wa ni ohun ti a n fẹ.”














