Ṣé lóòótọ́ ni pé NURTW Eko ń gba ₦500 lọ́wọ́ àwọn oníkẹ̀kẹ́ fún ìpolongo Tinubu?

Tinubu, kẹkẹ ati MC Oluomo

Ní àná ọjọ́ Ìṣẹ́gun ogúnjọ́ oṣù Kẹsàn-án ni fídíò kan gba orí ayélujára, èyí tó ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń sọ fún awakọ̀ kẹ̀kẹ́ márúwá kan láti san ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà.

Ohun tí wọ́n ní owó náà wà fún ni rira tíkẹ́ẹ̀tì kan tí wọ́n yóò lẹ̀ mọ́ ara kẹ̀kẹ́ náà láti lè máa polongo fun olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu.

Ní agbègbè Alagbado, ìpínlẹ̀ Eko ni fidio naa ní ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun tí wáyé.

Nínú fídíò náà ni òṣìṣẹ́ ẹgbẹ awakọti pọn ní dandan pe kí awakọ̀ náà gba tíkẹ́ẹ̀tì yii tó sì fẹ́ lẹ tíkẹ́ẹ̀tì náà mọ́ ara ọkọ̀ náà ní dandan.

Àmọ́ awakọ̀ márúwá náà fárígá wí pé òun kò ní gba tíkẹ́ẹ̀tì yìí, tó sì ní kí òṣìṣẹ́ Union yọ́ kúrò lára kẹ̀kẹ́ òun.

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ló ṣe bẹ́ẹ̀ fa awuyewuye láàárín àwọn méjèèjì, ti àwọn èrò si pe le awọn mejeeji lori loju titi.

Èyí sì mú kí àwọn ènìyàn da ẹnu bo òṣìṣẹ́ Union náà wí pé ìwà kò tọ́ ni wọ́n ń hù lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Fídíò náà ti wá gba orí ayélujára kan, eyi tó sì ti ń fa awuyewuye.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì ń fi ẹ̀sùn kan alága àwọn ọlọ́kọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko, Musliu Akinsanya, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MC Oluomo wí pé òun ló wà nídìí títa tíkẹ́ẹ̀tì náà.

Mi ò mọ nǹkankan nípa fídíò tí wọ́n ń gbé kiri lórí títa tíkẹ́ẹ̀tì fún ìpolongo Tinubu - MC Oluomo

Atẹjade ti MC Oluomo fisita

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo/Instagram

Lẹ́yìn tí fídíò náà gba orí ayélujára ni MC Oluomo fi àtẹ̀jáde kan léde lórí Instagram rẹ̀ láti fi wẹ ara rẹ̀ mọ́ wí pé òun kò mọ nǹkankan nípa tíkẹ́ẹ̀tì náà.

MC ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun wí pé àwọn kan ń fi orí tíkẹ́ẹ̀tì àti fídíò náà sọ òun àti gbígba owó fún ìpolongo ibo Ààrẹ fún Tinubu.

Ó là á mọ́lẹ̀ wí pé òun kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú tíkẹ́ẹ̀tì tàbí títà rẹ̀ àti pé inú òun yóò dùn tí àwọn ènìyàn bá le fi ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti waye gangan han òun láti ṣe ìwádìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Ó ní gbogbo àwọn nǹkan tó bá le kó ìpalára bá iṣẹ́ àti àwọn ènìyàn àwọn ni òun máa ń sá fún nítorí náà àwọn kò lè dédé gbé ìnáwó kan dìde fún àwọn ènìyàn láì bá wọn sọ tẹ́lẹ̀.

"Àwọn tó ń polongo fún Tinubu ti pọ̀ ju pé ka ma gba owó lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ lọ"

MC tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti ń gbèrò láti náwó tó pọ̀ rẹpẹtẹ sídìí ìpolongo Tinubu tí irú owó bẹ́ẹ̀ kò sì ní wá láti ọ́fíìsì òun.

Bákan náà ló ní tó bá ti di àsìkò ìpolongo ìbò báyìí onírúurú ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni àwọn ènìyàn máa ń gbé kiri láti fi ṣàkóbá fún ẹlòmíràn.

Ó wà rọ àwọn ènìyàn láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ yìí nítorí irọ́ pátápátá ló wà nìdí ẹ.

Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn olóṣèlú láti yé fi irọ́ kún ohun gbogbo tí wọ́n bá ń ṣe lásìkò yìí àti pé kí wọ́n yàgò nìdí dídárúkọ òun sí ọ̀rọ̀ òṣèlú wọn