Ọ̀jọ̀gbọ́n Zainab, to na Ọlọ́pàá-bìnrin tó ń ṣọ́ ọ, dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n

Ileẹjọ majistereeti kan nilu Abuja ti paṣẹ pe ki wọn sọ Ọjọgbọn Zainab Dike si ahamọ ni ọgba ẹwọn to wa ni Suleja.
Ọjọ Ẹti ni adajọ gbe idajọ yi kalẹ.
Eyi ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan an pe o ṣeto bi wọn ṣe lu ọlọpaa obinrin kan ti wọn ni ko maa sọ ọ iyẹn Insipẹktọ Teju Moses.
Adajọ kọ lati gba beeli Zainab Dike to si sun igbẹjọ siwaju lati gbọ ẹjọ lori ọrọ naa, di ọjọ Karun un oṣu Kẹwaa ọdun yii.
Ṣaaju ni ọga ileeṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn mu ọjọgbọn yi ati ọmọ ọdọ rẹ ti wọn jijọ fẹsun kan pe wọn da bantẹ iya fun ọlọpaa obinrin ti wọn ni ko maa sọ ọ.
Eyi waye lẹyin ti fọnran fidio ọlọpaa obinrin yi nibi to ti n kerora ti gbode kan.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi ti wọn si ni ki adajọ ododo waye lori iṣẹlẹ naa.
Bí ọ̀rọ̀ ṣé bẹ́yìn yọ

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ọwọ ti tẹ ọjọgbọn Dike Zainab tii se agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan.
Bakan naa lo ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn ọmọ ọdọ ọjọgbọn naa mejeeji, Rebecca Enechido, ti wọn si n wa ọkunrin kan to ti sa lọ.
Awọn eeyan yii ni ileesẹ ọlọpaa fi ẹsun ifiyajẹni kan, lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si obinrin ọlọpaa kan niluu Abuja, Teju Moses, ẹni to n sọ obinrin ọjọgbọn naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Ọmọọba Olumuyiwa Adejobi kede lori ẹrọ ayelujara Twitter pe iwadi ti bẹrẹ, ti wọn si ti ṣetan lati gbe ọjọgbọn naa lọ si ile ẹjọ.
Adejobi ni inu ileeṣẹ ọlọpaa ko dun si iṣẹlẹ naa, ti awọn si setan lati gbe lọ si ile ẹjọ fun ijiya to tọ lori awọn iwa ibajẹ naa.
Ọlọpaa Obinrin , Teju Moses ni Ọjọgbọn Dike Zainab ati awọn miran ṣe ikọlu si lọjọru ni agbeagbe Garki niluu Abuja.
Fọnran to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ safihan bi ẹjẹ ṣe bo oju obinrin naa, to si ni Ọjọgbọn Dike Zainab lo lewaju awọn to wa ṣe ikọlu naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Awọn ọmọ Naijiria fara ya lori ikọlu si ọlọpaa obinrin
Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa ni olu ilu Abuja, Sunday Babaji naa kede pe ọwọ ti tẹ Ọjọgbọn Dike Zainab ati awọn meji yooku lowurọ ọjọbọ niluu Abuja.
Ọpọ eeyan ti bu ẹnu atẹlu iwuwasi Ọjọgbọn naa lori ọpọ ayelujara Twitter.
@Tunepas, “Ni oun gba ladura pe ki Ọjọgbọn naa jẹ iya labẹ ofin”
Ẹlomiiran, @Babiessa, “Ta ni Ọjọgbọn Zainab Dike? Ati pe ki idi ti wọn se fi ọlọpaa ti i, pe ko ma sọ ọ.
@yhoccy ni “O ti yẹ ki Ọjọgbọn Dike Zainab wa ninu sẹkẹsẹkẹ bayii.
@DejiAdesogan, “Mo gbo pe Ọjọgbọn Zainab Dike pẹlu awọn ọmọ ọdọ ti wọn ṣe ikọlu si obinrin ọlọpaa naa, ninu fọnran to wa lori ayelujara, ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Idile mi ko ni nkan se pẹlu obinrin to lu ọlọpaa, ẹ lọ se iwadii yin - Ọga agba ọlọpaa
Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti wa bu ẹnu atẹ lu bi obinrin-ọlọpaa, Teju Moses ṣe ri iya he.
Baba, ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olumuyiwa Adejobi fi ransẹ si awọn akọroyin, pa lasẹ pe ki awọn afurasi mẹtẹte naa si wa ni ahamọ ọlọpaa titi iwadi yoo fi pari.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣe ohun to yẹ lati ri pe ọwọ tẹ ọkunrin to salọ naa.
Bakan naa ni Ọga ọlọpaa ni ko si ibaṣepọ pẹlu afurasi naa ati awọn mọlẹbi oun gẹgẹ bi iroyin kan ṣe n jakiri lori ayelujara.
Ọga agba ọlọpaa ni o ya ni lẹni pe irufẹ iwa bayii wa lọwọ ẹni to pe ara ẹ ni ajafẹtọ ọmọniyan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
"Ọlọ́pàá fìyà jẹ́ mí pẹ̀lú ọkọ àti ọmọ mẹ́rin, dá egbò sí wa lára pẹ̀lú ọmọ oṣù mọ́kànlá"

Oríṣun àwòrán, Others
Abilẹkọ kan, Happiness Liberty ti sọ iriri rẹ lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko fun akọroyin ileesẹ iroyin Sahara Reporters.
Abilekọ naa ni ọjọ mẹrin ni awọn ọlọpaa to wa ni agbegbe Igando, ni ijọba ibilẹ Alimosho ni ipinlẹ Eko fi ti awọn mọle.
Koda, o ni atimọle naa ko yọ ọmọ oun mẹrin silẹ, to fi ọmọ oṣu mọkanla.
Iwadii ni lẹyin ti awọn ọlọpaa naa fi iya jẹ awọn tan, ni wọn tun gbe awọn lọ sile ẹjọ.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye re e...
Abilekọ Happiness Liberty ni Ọjọ Aiku, Ọjọ Kọkanla, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni Ọlọpaa fi iya jẹ awọn fun ọjọ mẹrin lai jẹun tabi mu omi.
Obinrin naa ni lọjọ Isinmi naa ni awọn n bọ lati ile ijọsin, ti ọkada kan si kọlu awọn.
O ni lẹyin naa ni ọkọ oun jade lati beere lọwọ ọlọkada naa pe ki lo de to fi kọlu awọn.
Amọ Happiness ni kaka ki ọlọkada bẹbẹ, n ṣe lo dunkoko mọ awọn wi pe ṣe awọn mọ iru eniyan ti oun jẹ.
Lẹyin naa ni wọn to mọ pe ọlọpaa ni, to n ṣiṣẹ pẹlu agọ ọlọpaa to wa ni adugbo Igando.
Ija bẹ silẹ laarin wọn, to si ni ọlọpaa na digbaju bo ọkọ rẹ, nigba naa ni awọn mọlẹbi rẹ to sunmọ tosi dasi.
O fikun pe ọlọpaa naa tun fun aburo oun ni igbaju pẹlu ọmọ oṣu mọkanla to gbe sẹyin.
"Awọn ọlọpaa pupọ wa sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si fi panpẹ gbe wa"
Happiness tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe ‘’Lẹyin ti wọn na wa tan, ni wọn ko wa lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ni Igando.’’
‘’Lẹyin ti a de agọ ọlọpaa naa ni wọn tun bẹrẹ si ni na wa, ti mọlẹbi kan si subu lulẹ, o daku, ki wọn to ji i pada lẹyin wakati mẹfa.’’
‘’Nigba naa ni wọn ko ọkọ mi, atawọn ọmọ mi ọdun meje, mẹjọ ati oṣu mọkanla si gbaga lai jẹun fun ọjọ mẹrin.’’
‘’Lẹyin ọjọ kan ni wọn fun mi laaye lati jade, ko si ẹni ta le pe, ti wọn si fi iya jẹ wa bii ole’’
‘’Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹsan ni wọn ṣẹṣẹ fi wa silẹ ni panpẹ.’’
Bakan naa ni Abilekọ Happiness ni ọlọpaa to da iṣẹlẹ naa silẹ tun dunkoko mọ awọn pe awọn ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni ankan to ṣẹlẹ, ki oju awọn ma baa ri ibi.
A ti ko awọn ẹbi ati ọlọpaa ti isẹlẹ yii kan, iwadii si ti bẹrẹ – Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin ti wa fesi si iṣẹlẹ naa loju opo Twitter rẹ.
Hundeyin ni awọn mọlẹbi ti wọn fi iya jẹ naa ati awọn ọlọpaa ti wọn darukọ, ti wa ni agọ ọlọpaa bayii.
Bakan naa lo fikun un pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadi, X-Squad ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4















