Wo ẹ̀yà tí ọkùnrin ti ń na obìnrin tí ara rẹ̀ yóò fi ṣẹ̀jẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi àmìn ìfẹ́

Ọkùnrin to n na obìnrin ni ẹ̀yà Hamar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pataki ni àṣà jẹ fun awọn eniyan ilẹ̀ Africa. Bi ọlaju si ṣe pọ to, ko gba àwọn àṣà kan danu ni Africa.

Bẹẹ gan-an lori fun àwọn obinrin ẹ̀yà Hamar, ni orile-ede Ethiopia.

Àwọn obinrin ẹ̀yà yii ma n kopa ninu orò ilu, nibi ti wọn ti maa ń lu wọn ní alubami.

Lílù naa jẹ ọna ti àwọn obinrin yii fi n ṣe atilẹyin fun awọn ọkunrin wọn.

Ukuli Bula ni wọn n pe orúkọ orò naa, eyi ti wọn ma n ṣe fun awọn ọmọkùnrin to ti bàlágà, lati ki wọn kaabọ si àwùjọ awọn gende.

Obinrin ati ọkùnrin ẹ̀yà Hamar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkùnrin to n na obìnrin ni ẹ̀yà Hamar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lẹ́oyìn oro naa ni ọmọkùnrin to le ṣe igbeyawo

Ọmọkùnrin ti yoo ba wọ awujọ gende gbọdọ dá abẹ́, ko si tun rin lori maalu.

Lara asa ẹya Hamar naa tun ni pe ọmọkùnrin ti yoo ba wọ awujọ awọn gende ni, gbọdọ dá abẹ́, yoo si tun rin lori maalu.

Igbeṣẹ naa ni yoo sọ boya iru ọmọkùnrin bẹẹ ti ṣe tán lati 'di gende ọkùnrin'.

Lasiko orò naa, ni àwọn obìnrin lati inu ẹbi àwọn ọmọkùnrin naa maa n yọnda ara wọn fun lílù lati fi ifẹ han si wọn.

Eyi tun wa safihan bí wọn ṣe le fi ara da iya to o.

Nise ni wọn maa n bẹ awọn ọkunrin lati lu wọn.

Ti wọn ba n lù wọn, wọn ko gbọdọ pariwo tabi ke ìrora, titi gbogbo ara wọn yoo fi sẹjẹ.

Lẹyin oro yii, eyi to má n waye ni àfonífojì odò Omo River Valley, ọmọkùnrin bẹẹ ti di ọkùnrin, o si lẹtọ lati fẹ iyawo.