"Àṣìlò ìlù ìbílẹ̀ wa le pe ẹ̀mí àwọn baba ńlá wa àtàwọn ẹ̀mí burúkú míì dìde"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ijọba to risi ọrọ asa lorilẹede Burundi ti fẹhonuhan lori nkan ti wọn sapejuwe gẹgẹ bi asilo ilu, nibi ayẹyẹ ọdun orin Nyege Nyege.
Ayẹyẹ orin naa lo wa sopin lọjọ Aje lorilẹede Uganda.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sọwọ sori ayelujara Twitter, ileeṣẹ ijọba safihan awọn kan nibiti wọn ti tapa si asa to de lilu ilu naa.
“A ko ni fi aye gba ẹnikẹni lati tapa si ofin asa ati ise Burundi. Ẹnikẹni ti a ba ba irufẹ iwa ibajẹ bẹẹ lọwọ rẹ, yoo jiya ofin.
Igbagbọ wa pe ilu lilu yoo ta awọn baba nla wa dide ati ẹmi buruku miran.”
Ayẹyẹ Ilu lilu lorilẹede Burundi ni wọn maa n ṣe ti wọn ba fẹ ṣe ayẹyẹ tabi lati fi ki awọn alejo wọn kaabọ.
Alaye ko ti wa, boya Orilẹede Burundi yoo gbe awọn to tapa sofin lọ ileẹjọ nibi ọdun Nyege Nyege lorilẹede Uganda.
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ileeṣẹ ijọba yoo gbe ikilọ sita lori asilo ilu naa fun awọn ara ita to wa si orilẹede naa.
Bakan naa, kii n ṣe igba akọkọ ree ti ọdun Nyege Nyege yoo fa rogbodiyan .
Ijọba orilẹede Uganda ti n dunkoko lati fi ofin ọlọjọ mẹrin de ayẹyẹ naa tẹlẹ nitori awọn iwa ibajẹ orisirisi to maa n sẹlẹ nibi ayẹyẹ naa.
O to ẹgbẹrun mẹtadinlogun eeyan to wa nibi ayẹyẹ naa ni Itanda Fall nibi adagun odo River Nile.















