Queen Elizabeth II's death: Kí ni àwọn ìpènijà tí Ọba Charles Kẹta le è dojúkọ lórí ìtẹ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Piparọ agbara nilẹ Gẹẹsi ni o waye laisi rogbodiyan: lẹyin wakati mejidinladọta ti Ọbabinrin Elizabeth II jade laye ni wọn kede Ọba Charles kẹta gẹgẹ bi ori ade tuntun fun ilẹ Gẹẹsi.
Sugbọn ko rọrun bi ọpọ ṣe n wo nitori Charles bọ si ori alefa nigba ti nkan fẹ safẹrẹ diẹ fun ilẹ UK ati idile ori ade naa. Awọn onimọ nipa itan ti ileeṣẹ BBC ba sọrọ salaye pe Ọba tuntun naa yoo ri awọn idojukọ, eyi ti yoo safihan boya igba rẹ yoo dara ati awọn to ba tẹle.
Bẹrẹ lati ri igbesẹ lati mu ayipada rere ba ipese ohun amusagbara titi de ọna lati yi ero awọn araalu pada nipa isejọba oriade lẹyin aadọrin ọdun ti iya rẹ lo lori alefa, o daju saka pe awọn akoko isoro wa niwaju Ọba Charles Kẹta.
Wo awọn nnkan to lilo akiyesi Ọba tuntun.
Ṣe Iṣejọba awọn araalu ni?
Ogunlọgọ awọn eeyan nilẹ Gẹẹsi ni wọn ri idojukọ sisa fẹrẹ bẹntiro nitori gbogbo rogbodiyan to waye lorilẹede Ukraine. Iwadi safihan pe o to eeyan marundinladọta milọnu yoo ri inira lati bọ arawọn- eyi to jẹ ida meji awọn eeyan to wa niluu naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Irufẹ awọn nkan bayi ni o ṣeṣe ki owo nina awọn mọlebi ori ade wa gba iwadi ju bọ ṣe wa tẹlẹ lọ. Ko da ki ogun naa to waye ni iroyin kan ti ja kiri pe, Ọmọọba Ile Wales tẹlẹ naa fẹ ṣe dikun owo nina ati ayẹyẹ awọn mọlẹbi ori ade naa.
Iwe royin The Daily Telegraph ni ọjọ kẹtala oṣu kẹsan an ni ayẹyẹ ifinijoye ni ko fi ara pẹ ti Ọbabinrin olowo naalọdun 1953, eyi to jẹ akọkọ ti yoo han loti ero aimomaworan
Iwe royin naa ifinijoye Charles III, eyi ti yoo waye ninu osu kẹfa ọdun to n bọ,ni ko ni tobi ju, ko gba owo nla, ti yoo si tun fi aiye gba awọn iaran ni awujọ ileẹ Gẹẹsi.
Charles ti kede erongba rẹ sẹyin pe oun fẹ ki awọn to wa ninu iṣejọba oun ma pọju, eyi to jẹ pe awọn ti yoo ba sisẹ pọ koni ju mẹtin lọ ninu mọlẹbi ori ade naa. Ọba, Olori Camila, Ọmọọba William ati Iyawo rẹ Camila yoo si ṣe agbetẹru.
"Igbagbọ wa pe a mu nkan wa lẹ diẹ papajulọ nipa ti ifinijoye," Kelly Swab salaye fun BBC.
"Idile ori ade ni lati fi han pe awọn mọ ohun gbogbo to n lọ ni orilẹede lasiko isoro yii." o fikun.
Owo nina fun awọn idile ori ade ni waye lati ibi owo ori to o wọlw lọdọdun ti a n pe ni 'Sovereign Grant'
Fun ọdun 2021-2022, owo ori yii jẹ $99.8m, eyi to jẹ $1.49 ori kọkan nilẹ UK=, sugbọn ko ni afikun awọn owo miiran fun awọn mọlẹbi ori ade,
Iwasilẹ Aponle

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Itinilẹyin fun ori ade ni o ti ja walẹ lati ibi ọgbọn sẹyin naa, gẹgẹ bi ajọ British Social Attitudes Survey, to n ṣe iwadi lori iwuwasi awọn araalu si awọn ori ade ṣe ṣọ.
Iwadi ti wọnb ṣe gbẹyin fihan pe ida marundinlọgọta awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi ni igbagbọ ninu pe ki ori ade wa ni awujọ. Ni ọpọlọpọ ọdun ṣeyin, itinilẹyin naa ni o wa laarin ida ọgọta ati ida adọrin.
Ninu oṣu karun un, Charles wa ni ipo kẹta awọn ori ade ti awọn arallu nifẹ si ju, saaju ni Ọbabinrin ati ọmọ rẹ agba, Ọmọọba Willam. Lẹyin iku Ọbabininrin, Ọba Charles ni afikun awọn eeyan to nifẹ rẹ, eyi ni apẹẹrẹ pe Ọba Charlse ni isé lati ṣe nipa riri atilẹyin awọn araalu.
"Ọkan lara awọn idojukọ fun Ọba Charles ni lati jẹ ki iṣejọba jẹ ohun iwuri fun awọn ọdọ." Richard Fitzwilliams lo sọ bẹ.
Ọrọ ti Fitzwilliams sọ ni iwadi ajọ British Social Attitude Survey ṣe atilẹyin fun to safihan pe lọdun 2021 , ida mẹrinla awọn eeyan lati ọmọ ọdun mejidinlogun si ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ri oye ori ade naa gẹgẹ ni ohun pataki ni ilẹ Gẹẹsi ti awọn yooku ti wọn jẹ ọmọ marundinlọgọta ko si ri bẹ.
Gẹgẹ bi iwadi YouGov ṣe ṣe afihan rẹ ninu oṣu karun un, ida mẹtadinlọgbọn awọn araalu fi ọwọ si pe ki a ma ni ohun to jẹ ori ade mọ nilẹ UK.
Kelly Swab naa nakasi pe "Nkan ti yatọ lati ọdun 1952." (Ọdun ti Ọbabinrin II de si ori oye) O ni ọpọlọpọ iwọde lo ti waye ni ọjọ melo sẹyin bayi.
"Ko si ibọwọ fun oei ade mọ lasiko yii."
"Eyi ni nkan ti Ọba Charles ni lati ni lọkan."
'Maṣe kerora, Maṣe salaye'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọba Charles III jẹ olori iṣejọba ilẹ UK. Sugbọn labẹ eto ofin ilẹ Gẹẹsi, agbara Ọba ni mọ nikan ibi ayẹyẹ, fun idi eyi awọn mọlẹbi ori ade ko ni anfani lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan.
Bi Ọbabinrin ṣe fa ṣeyin nibi ọrọ naa ni ọpọ ri gẹgẹ bi igbọgbọ ni iwe kan to ni 'Ma ṣe kerora, Ma ṣe salaye'
Oba Charles III ni atẹyin wa ma sọrọ lori awọn ọrọ kan to ba jẹ lọgun, Lọdun 2015, o kọ lẹta si minisita ijọba lati fẹhonuhan han lori ọrọ kan to jẹ owo awọn ọmọ ologun ati ohun ibilẹ.
N jẹ iyipada lo wate? Ọjọgbọn Vernon Bogdanor ni igbagbọ bẹẹ.
"O ti mọ lati igba ewe rẹ pe ayipade yoo deba oun nitori awọn araalu ko ni faramọ Ọba to ba kopa ninu iponlogo." Ọjọgbọ Bogdanor tẹsiwaju.
Lọjọ kejila oṣi kẹsan an, nigba ti o ba awọn ọmọ ile gbimọ aṣofin sọrọ. Ọba tuntun naa fi apẹẹrẹ rere si pẹlu ọrọ to ṣo, o ni awọn nkan wa ti oun ko le tẹsiwaju mọ ninu wọn. Charles III ni ile gbimọ aṣofin jẹ irinsẹ ẹlẹmi fun ijọba awarawa nilẹ Gẹẹsi.
Isọkan Commonwealth ati Ikonilẹrun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin iku iya rẹ, Ọba Charles III di olori fun ajọ isọkan Commonwealth, ogbimọ orilẹede mẹrindinlọgọta , ti pupọ laarin awọn jẹ awọn orilẹede to wa ni abẹ ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ. Oun naa ni olori fun orilẹede mẹrinla ati ilẹ UK - Australia, Canada, Jamaica, and New Zealand.
Ni bi ọdun melo sẹyin awọn orilẹede kan bẹrẹ lati bu ẹnu lu ibaṣepọ wọn ori ade ile Gẹẹsi. Nitori naa ni Orilẹede Barbados fi pinnu lati kede ominira wọn lọdun 2021, ti o si yoo Ọbabinrin Elizabeth gẹgẹ bi olori ijọba wọn lati fi opin si iṣejọba ọpọlọpọ ọdun ile Gẹẹsi.
Irinajo Ọmọọba William lọ si orilẹede Caribbean ni ọdun 2022 fa ọpọlọpọ ifẹhonuhan, ti olotu agba Jamaica Andrew Holness sọ ni gbangba fun awọn ori ade naaa pe orilẹede naa yoo tẹsiwaju .
Sean Coughlan, akọroyin ileeṣẹ BBC fun ori ade nigbagbọ pe ibaṣepọ to daranmọran Isọkan Commonwealth jẹ ọkan gbogi lara awọn isoro ti Ọba Charles yoo dojukọ.
"Gẹgẹ bi olori tuntun, bawo ni abẹwo si awọn orilẹede ajọ isọkan ṣe le pin opin si awọn awuyewuye."
Ọba nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun mẹtadinladọrin, Ọba Charles III jẹ ẹni to dagba julọ ti wọn yoo kede gẹgẹ Ọba ilẹ Gẹẹsi. Ọkan lara awọn ibere ti wọn ọpọ bere ni boya o ni agbara lati ṣe awọn isẹ lorekore
Ọpọ lo ti ọmọ rẹ, eyi to jẹ arẹmọ, Ọmọọba Willama ni kẹ sẹ bọ awọn ohun to ba jọmọii irinajo lọ si oke okun. Ọbabinrin Elizabeth naa fi opin ririn irinajo nigba to wa ni ẹni ọgọrin ọdin
"Charles jẹ Ọba to ti dagba, ko le mṣe gbogbo ẹ." Kelly Swab sọ bẹẹ fun BBC.
"Mo reti pe ki Ọmọọba WIllam kẹsẹbọ pupọ ninu awọn isẹ naa. "
Bata to tobi lati wọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu bi awọn eeyan se n sọrọ lẹyin ipapoda Ọbabinrin Elizabeth II jẹ Ọba to gbajumọ gan.
Eyi ni o jẹ ipenija fun Ọba tuntun, sugbọn ki n ṣe eyi to le gẹgẹ Evalin Brueton ṣe salaye.
O sapejuwe irufẹ iṣẹlẹ yii waye si Ọba Edward VII nigba ti o gba Ade lọdun 1901 lẹyin iku Ọbabinrin Victoria, Ọbabinrin miiran ti ọpọ fẹran.
"Irufẹ iṣẹlẹ yii ṣelẹ sẹyin nigba iṣejọba Ọbabinrin Victoria."
Edward VII ati Charles III gba ijọba nigba ti itipada de ba ilẹ Gẹẹsi. Awọn mejeeji ko si gbajumọ to awọn iya wọn."
Ọdun mẹrin jẹ ọba fun ọdun mẹsan sugbọn iranti wa pe oun lo sẹ isẹ ribiribi lori idasilẹ gbajugbaja Entente Cordiale, eyi to jẹ adehun laarin orilẹede France ati ilẹ UK lọdun 1904.
"Edward VII ṣe isẹ gan ati ko si nkan to sọ wipe Charles so jẹ Ọba pataki naa."
Brueton ni "Charles ni Ọbabinrin Elizabeth gẹgẹ bi awukọse, ti o si ni ọpọlọpọ asiko lati gbaradi.












