Ọkùnrin kàn dáná sún àrà rẹ láti fi ẹ̀hónú hàn

Aworan awọn ọlọpaa nibi ifẹhonuhan ni Japan

Oríṣun àwòrán, KYODO

Ọkunrin kan tii se ọmọ orilẹede Japan ti mọọmọ dana sun ara rẹ lati fi ẹhonu han lori eto isinku alarinrin to fẹ waye fun Olootu ijọba tẹlẹ, Shinzo Abe.

Shinzo Abe ni wọn ṣekupa ninu osu keje ọdun yii.

Ogunlọgọ olori orilẹede agbaye ni igbagbọ wa pe yoo wa ni ikalẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn osu Kẹsan yii fun isinku alarinrin naa.

Lọjọru ni awọn oṣojumikoro kan si ile isẹ ọlọpaa, lẹyin ti wọn kẹẹfin ọkunrin naa nibi to di dana sun ara rẹ.

Isẹlẹ naa lo waye nitosi ọọfisi olootu ijọba Japan to wa ni Tokyo.

Awọn ọlọpaa bu omi pa ina naa, ti wọn si gbe ọkunrin naa lọ si ile iwosan, amọ a ko tii le sọ ipo ti ilera ọkunrin naa wa bayii.

Ọkunrin naa ni igbagbọ wa pe o jẹ ẹni aadọrin ọdun.

Ijọba ko ti sọrọ lori isẹlẹ ifẹhonuhan naa sugbọn ọpọ awọn eeyan lo ti tako bi wọn ṣe fẹ ṣeto isinku alarinrin naa lati bi oṣu diẹ sẹyin.

Inu wọn ko si dun si bi ijọba ṣe fẹ seto isinku ọhun fun Olootu agba to doologbe naa.

Ko dín ní wakatì mẹrin tawọn dokìta lo lorí Abe lati doola ẹmi rẹ.

Shinzo Abe jade laye lẹyìn tí ọkunrin kan yìnbọn fun nibi ìpolongo kan lọjọ kẹjọ oṣu keje.

Bi wọn ṣe sekupa Abe, ẹni to jẹ adari to tii pẹ julọ ni Japan jẹ ohun iyalẹnu nitori orilẹede naa ki i ṣe orilẹede to maa n fa rogbodiyan.

Ìròyìn ní ko dín ní wakatì mẹrin tí awọn dokìta lo lorí Abe nikan lati doola ẹmi rẹ.

Eto isinku alarinrin ni ko wọpọ lorilẹede Japan, ti awọn olufẹhonuhan si ni awọn lodi si bi ijọba se fẹ na owo ilu toto biliọnu kan Yen, fi ṣe ayẹyẹ naa.

Ẹgbẹ alatako gboogi lorilẹede naa, the Constitutional Democratic Party, ni awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ko ni kopa ninu eto isinku naa lọsẹ to n bọ.

Kí ní ilééṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti fi idi isẹlẹ ifẹhonuhan to waye lọjọ isẹgun naa mulẹ.

Sugbọn iroyin ni ọkunrin naa ke sita lori bo ṣe lodi si eto isinku alarinrin naa nitosi ọọfisi kan ko to dana sun ara rẹ.

Awọn iwe to fi ọwọ rẹ kọ wa lara asọ rẹ, to si kọ sibẹ pe oun lodi si eto isinku alarinrin naa.

Eto isinku naa ni ọpọlọpọ awọn oloṣelu lorilẹede naa ti bu ẹnu atẹlu, ti ọpọ si ni o ni ibaṣepọ pẹlu ile ijọsin kan.

Ọkunrin ti wọn fi ẹsun kan pe oun lo ṣekupa Abe, ni oun gbe igbesẹ naa nitori ibaṣepọ olootu ijọba naa pẹlu ile jọsin ọhun.

Obìnrin tó lọ́kọ méjì ní Ilorin àti Bàbá rẹ̀ kan ìjàngbọ̀n nílé ẹjọ́

Àwòrán ohun èlò ìdájọ́

Oríṣun àwòrán, Kwara State Magistrate Court

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan ní ìpínlẹ̀ Kwara ti ju ìyàwó ilé kan sẹ́wọ̀n fẹ́sùn wí pé ó ní ọkọ méjì.

Ìyàwó ilé náà àti àwọn méjì mìíràn ni ilé ẹjọ́ ọ̀hún jù sẹ́wọ̀n ná títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi tẹ̀síwájú.

Ayuba Sule tó jẹ́ ọkọ àkọ́kọ́ tí Awawu Haruna kọ́kọ́ fẹ́ ló wọ́ Awawu àti bàbá rẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́.

O si fẹ́sùn kan wọn pé ó lọ fẹ́ ọkọ mìíràn láì tíì tú ìgbéyàwó tó wà láàárín àwọn ká.

Sule sọ fún ilé ẹjọ́ pé Awawu lọ fẹ́ ọkọ mìíràn láì ṣe wí pé wọ́n tú ìgbéyàwó òun àti Awawu ká kó tó ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó ní bàbá ìyàwó òun tó lọ́wọ́ sí bí òun àti ìyàwó òun ṣe fẹ́ ara àwọn ní ìlànà Mùsùlùmí náà ló tún ṣe bí ó ṣe lọ fẹ́ ọkùnrin mìíràn.

Ó ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹjọ, ọdún 2022 ni bàbá ìyàwó oun ṣètò ìgbéyàwó mìíràn fún ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan.

Orukọ ọkunrin naa ni Jemilu Bahause, ti Sule si ni ìgbéyàwó àárín òun àti ìyàwó òun kò ì tíì tuka lasiko naa.

"Nítorí kí wọ́n le ṣe ọ̀rọ̀ náà ní òkú òru, bàbá ìyàwó mi wá lọ gba ilé fún Awawu àti ọkọ rẹ̀ tuntun, Jemilu Bahause sí agbègbè mìíràn níbi tí wọ́n ti ń gbé bíi tọkọtaya."

Adájọ́ Abdulraheem Bello wá sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022.

Bákan náà ló ní kí Awawu àti Jemilu àti bàbá Awawu wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlú Ìlọrin títí tí ìgbẹ́jọ́ wọn yóò fi máa tẹ̀síwájú.