Èèyàn mẹsan an pàdánù ẹ̀mi wọn nínú ìwọ́de tako Hijab ní Iran

Aworan Obinrin to fẹhonuhan lorilẹede Iran

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ifẹhonuhan to bẹ silẹ lẹyin iku obinrin kan ti gbẹmi eeyan mẹsan-an miiran lorilẹede Iran.

Obinrin to ku naa ni awọn agbofinro ti mọle nitori o tapa si ofin to rọ mọ lilo ibori lorilẹede naa.

Obinrin naa si lo padanu ẹmi rẹ lẹyin to lo ọjọ mẹta nile wosan.

Lara awọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan , ẹni ti awọn agbofinro yinbọn lu, nigba ti wọn ṣe ikọlu si awọn olufẹhonuhan.

Orisirisi fọnran lori ayelujara ṣe afihan bi awọn obinrin to n ṣe ifẹhonuhan ṣe ju anamọ soke, lẹyin ti wọn dana sun awọn ibori wọn.

Aarẹ Iran ni ki ipade awujọ agbaye kọ eti ikun si awọn obinrin to n fẹhonu han, Biden ni awọn wa lẹyin wọn

Fọnran naa ṣe afihan bi wọn ṣe pariwo pe “A ki n ṣe anamọ, a fẹ itusilẹ ati ibaradọgba akọ ati abo"

Ninu ọrọ rẹ niwaju Ajọ Isọkan Agbaye, Aarẹ Joe Biden ti orilẹede Amẹrika ni awọn wa lẹyin awọn obinrin to n fi ẹhonu han naa ni Iran nitori wọn ja fun ẹtọ wọn ni.

O sọrọ yii ni kete ti Aarẹ Iran, Ebrahim Raisi ni ki ajọ agbaye kọ eti ikun si ipe awọn obinrin naa to n ja fun ẹtọ wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ìwọ́de gbòde ní Iran báwọn obìnrin ṣe ń dáná sún 'Hijab' láti fi ẹ̀hónú hàn

Aworan awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ọpọ awọn obinrin lo lewaju ifẹhonuhan ni Iran, ti wọn si n dana sun ibori wọn, ‘Hijab’, lẹyin ti ọkan lara wọn to tapa si ofin ‘Hijab’ padanu ẹmi rẹ.

Ifẹhonuhan naa lo ti gbalẹ fun ọjọ marun un bayi, to si ti tan kalẹ kaakiri orilẹede naa.

Mahsa Amini, obinrin kan ti awọn ọlọpa fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to de lilo ibori si lo padanu ẹmi rẹ ni ile wosan lọjọ Ẹti.

Amini yii lo ku lẹyin to ti wa ni ẹsẹkan aye ẹsẹkan ọrun (Coma) nile iwosan fun ọjọ mẹta.

Iwadii fihan pe lọpaa na Amina pẹlu kumọ, gba ori rẹ mọ ọkọ wọn tori pe ko lo ibori bo se yẹ - UN

Ni Sari, ẹkun ariwa ilẹ Tehran, ogunlọgọ awọn obinrin lo tu sita, ti wọn si bẹrẹ si ni dana sun ‘Hijab’ wọn lati fẹhonu han.

Amini ni ọwọ awọn ọlọpaa to n risi igbọran araalu tẹ ni olu ilu orilẹede naa lọsẹ to kọja.

Wọn si fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to rọ mọ pe ki obinrin gbọdọ fi nkan bo ori, apa ati ẹsẹ wọn.

Iroyin naa ni awọn ọlọpaa na obinrin naa, to si daku, eyi to mu ko wa ni koma fun ọjọ mẹta.

Asoju ajọ United Nation to ri ija fun ẹto ọmọniyan, Nada al-Nashif, ni Iwadi awọn safihan pe awọn ọlọpaa naa fi kumọ naa Amina.

O ni ti wọn si tun gba ori rẹ mọ ọkan lara ọkọ wọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Aisan ọkan lo se Amina, a ko na rara - Ọlọpaa Iran

Awọn ọlọpaa ni awọn ko fi iya jẹ obinrin naa ati pe o kan sadede ni ijakulẹ ọkan rẹ.

Mọlẹbi Amina ni ilera rẹ wa ni alaafia, ti ko si nkan to mu rara.

Amini, ẹni ọdun mejilelogun wa lati Kurdistan ni ẹkun iwọ orun orilẹede Iran.

Agbegbe yii si ni eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn lọjọ Aje nigba ti ọlọpaa sina bolẹ fun awọn olufẹhonuhan.

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ adari Ayatollah Ali Khamenei, ti orilẹede Iran sabẹwo si idile ọmọbinrin, to si ṣe ileri pe ẹlẹsẹ kan ko ni lọ la jiya lori iṣẹlẹ naa.

MP Jalal Rasidi Koochi wa bu ẹnu atẹlu ihuwasi awọn agbofinro, to si ni wọn kan ko ba awọn araalu si ni lorilẹede Iran.

Aworan Mahsa Amini

Oríṣun àwòrán, Mọlẹbi Mahsa Amini

Kì ní àwọn òfin 'Hijab' lórílẹ̀èdè Iran?

Lẹyin ti ẹsin Islam ri ayipada lọdun 1979, awọn alasẹ lorilẹede Iran gbe ofin kalẹ lori asọ wiwọ awọn obinrin.

Wọn ni wọn gbọdọ bo ori wọn, wọn ko si gbọdọ wọ asọ to fun mọra ju ni awujọ.

Ẹka ọlọpaa to ri si igbọran "Gasht-e Ershad", ni wọn gbe isẹ naa le lọwọ lati ri pe awọn obinrin tẹle ofin naa.

Awọn ọlọpaa ni asẹ lati da obinrin duro lati wo boya o tẹle ofin ati irufẹ asọ ti wọn ba wọ sara.

Ijiya ẹsẹ fun ẹni toba tapa si ofin naa ni, owo itanran, lilọ sọgba ẹwọn ati ẹgba jijẹ.

Lọdun 2014., awọn obinrin bẹrẹ lati ma ṣe afihan awọn aworan ati fọnran ara wọn ni awujọ nibi ti wọn ti n tapa si ofin naa lati fi ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara.

Ifẹhonuhan naa ni wọn pe ni "My Stealthy Freedom".

Lara awọn ifẹhonuhan ti ọpọlọpọ awọn obinrin miran ti se lori lilo ibori ni wọn pe akori rẹ ni "White Wednesdays" ati "Girls of Revolution Street".