ASUU àtàwọn aṣòfin ṣàdéhùn tí yóò fòpin sí ìyanṣẹ́lódì, Buhari ló kú kó buwọ́lù ú

Ipade ASUU ati awọn asofin

Oríṣun àwòrán, NASS

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU ti ṣe adehun tuntun pẹlu ijọba apapọ Naijiria.

Awọn ikọ adari ile igbimọ asofin apapọ lo lewaju ipade oni wakati mẹrin to bi adehun tuntun naa to waye ni ile gbimọ asofin to wa niluu Abuja lọjọ isẹgun.

Adehun naa lo nilo ibuwọlu Aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to rin irinajo lati kopa nibi ijokoo Ajọ isọkan Agbaye niluu New York.

Emmanuel Osodeke lo lewaju fun ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ti minista fun eto ẹkọ, Goodluck Opiah si lewaju fun ijọba apapọ nibi ipade naa.

Lẹyin ipade naa, Adari ile igbimọ aṣofin kekere, Femi Gbajabiamila, to tun jẹ alaga fun ipade naa kede pe ipade naa bi awọn adehun tuntun sugbọn ko sọ ipo ti adehun tuntun naa dirọ mọ.

Ilọsiwaju wa nibi ipade wa pẹlu awọn asofin, a si bun awọn ọmọ ẹgbẹ wa gbọ - ASUU

O ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yoo ṣe agbekalẹ awọn adehun naa fun Aarẹ Buhari, to ba pada de si orilẹede Naijiria.

“Ọna meje ni ASUU fi ṣe agbekalẹ wọn, to si ti fi ẹnu ko lori awọn nkankan lẹyin ti a jọ wo awọn ọna naa.

“Lẹyin eleyi, Awọn Adari ile igbimọ aṣofin yoo duro ki Aarẹ Buhari pada si orilẹede Naijiria lati ibi ipade ajọ isọkan agbaye.

A ṣe awọn agbekalẹ fun Aarẹ, ti a si ni ireti pe Aarẹ yoo fara mọ awọn adehun naa, pẹlu eleyi, mo ni igbagbọ pe ọrọ naa yoo tete ri iyanju.”

Nigba ti o sọrọ nibi ipade naa, Aarẹ ajọ Asuu, Emmanuel Osodeke ni ọrọ ko ni pẹ ti wọn ma fi iyanju rẹ.

“A ti ri ilọsiwaju latara ipade, ti a si duro de nkan ti wọn yoo fi ransẹ si wa lati fi ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ.

A ni ireti pe ko ni pẹ ti ọrọ iyansẹlodi yoo fi di ohun igbgagbe.”

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbégi dánà pápákọ̀ òfurufú, òjú pópó dí pa

aworan awọn ẹgbẹ Akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria, NAN ti balẹ si papakọ ofurufu to wa ni ipinlẹ Eko, ti wọn si da lilọ bibọ duro saaju bi ijọba ṣe kuna lati fi opin si iyanṣelodi ti ẹgbẹ olukọ ASUU gunle.

Ifẹhonuhan naa ko ṣẹyin iyanṣelọdi to ti wọ oṣu meje bayii lori bi ijọba ko ṣe mu adehun to ṣe pẹlu awọn olukọ ṣe.

Ati aisan owo oṣu fun wọn ni gbogbo igba ti wọn fi yan iṣẹ lodi

Ogunlọgọ awọn akẹẹkọ lo ti balẹ si agbegbe naa lati bẹrẹ ifẹhonuhan naa

Ọsẹ to kọja ni Ẹgbẹ NAN ṣe ipade nipinlẹ Ondo, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ko ṣe naani awọn olukọ ati eto ẹkọ paapaa ni Naijiria.

aworan awọn ẹgbẹ Akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, others

aworan awọn ẹgbẹ Akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, others

Nibi ipade naa ni wọn ti kede pe awọn yoo bẹrẹ ifẹhonuhan kaaliri papakọ ofurufu lorilẹede Naijiria.

‘’Bẹrẹ lati Ọjọ Aje, Ọjọ Kọkandinlogun, ọdun 2022 ni a o bẹrẹ ifẹhọnuhan miran.

‘’A o ri pe ko si ọkọ ofurufu kankan lati ilẹ okeere to balẹ si Naijiria abi eleyii ti yoo jade.’’

‘’Aarẹ Buhari gbọdọ san gbogbo owo awọn olukọ to jẹ wọn nitori o ti su wa ki a ba wọn sọrọ ti wọn kọ’’

‘’A ko ni gba ki awọn akẹkọọ joko si ile nigba ti awọn oloṣelu n ran ọmọ wọn lọ si oke okun.

‘’#OccupyTheAirports yoo bẹrẹ ni Ọjọ Aje, ki gbogbo agbaye le mọ ohun ti a n la kọja ni orilẹede Naijiria.’