Àfojúsùn mi ni bí òṣìṣẹ́ yóò ṣe gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ láì tọ ipasẹ̀ ẹnikẹ́ni - Seyi Makinde

Aworan Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/seyiamakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ni iṣejọba oun ko ni fi aye gba ìdẹ́yẹsí si osisẹ ọba kankan nitori oun ko kọyan awọn osisẹ kere.

Makinde sọ eleyi nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ fun awọn osisẹ to waye niluu Ibadan.

O ni iṣejọba oun ko ni dẹkun lati ma ṣe ohun to tọ ati eyi ti yoo ṣe anfani fun ilọsiwaju ipinlẹ Oyo, fun awọn eeyan ipinlẹ naa.

Makinde wa pe akiyesi awọn eeyan si iroyin kan to n ja kiri pe ijọba ipinlẹ Oyo da awọn osisẹ kan yatọ, to si n fi iya jẹ awọn kan.

Gomina ni irọ to jina si ootọ ni.

“A ko kọyan ẹnikẹni kere ninu isejọba, a wa fun gbogbo awọn osisẹ nipinlẹ Oyo.”

"Afojusun mi ni bi osisẹ yoo se gba ẹtọ rẹ lai tọ ipasẹ ẹnikẹni"

O fikun pe ki ijọba ma mu ori awọn osisẹ wu fun isẹ gidi ti wọn n ṣe lo dara, oun ko si ni ya kuro lati se amusẹ eyi.

“Ami ẹyẹ ti a pin loni wa fun awọn to lẹtọ si.

“Ipinlẹ Oyo ti a ni lọkan, ni ibi tawọn osisẹ yoo ti gba ẹtọ wọn lai si pe wọn lọ ba ẹnikẹni, ki wọn to gba ami ẹyẹ.

“A ṣe tiwa lati mu idẹrun ba awọn eeyan ipinlẹ Oyo.”

Aworan Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/seyiamakinde

Iseyin kò ní pẹ́ di olú ìlú Naijiria níbí tí àlùmọ́nì pọ̀ sí jùlọ - Makinde sọ àsọtẹ́lẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ni ijọba oun ti bẹrẹ igbesẹ ti yoo sọ ilu iṣẹyin di olu ilu Naijiria, nibi ti ohun alumọni pọ si julọ.

Ilu Iṣẹyin to wa ni ariwa ipinlẹ naa ni awọn ohun alumọni wa loriṣiriṣi.

Gomina Makinde sọ eyi nibi ayẹyẹ ijade oku Ọba Aṣeyin ti Iṣẹyin, Oba Abdulganiyu Adekunle Salau to waja.

O ni ijọba oun yoo mu idagbasoke ohun alumọni lọkunkundun, ki awọn arinrinajo le maa wa si agbegbe naa.

Bakan naa ni gomina ọhun ni oun yoo ri pe awọn jẹ ere adagun omi Ikere Gorge Dam ati awọn ojuko to fanimọra nipinlẹ naa.

‘’Mo ṣeleri fun Aṣeyin to papoda lati tu ilu Iṣẹyin ṣe’’

Gomina Makinde tẹsiwaju pe ‘’Laipẹ yii ni ijọba pari awọn opopona Moniya-Iṣẹyin, to fi mọ Iṣẹyin -Fapote-Ogbomoso ati bẹẹ lọ.’’

‘’Gbogbo igbesẹ ọhun la n gbe, ki Ilu Iṣẹyin le ṣee wo gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ilu nla nipinlẹ Oyo, ki o si jẹ olu ilu ibi iwa ohun alumọni ni Naijiria.’’

‘’Bakan naa ni ijọba apapọ ti bẹrẹ eto lati ṣe atunṣe ileewosan gbogboogbo to wa ni ilu Iṣẹyin’’

Ninu ọrọ rẹ, gomina Makinde ni ifẹ ti Aṣẹyin to doloogbe ni si ilu Iṣẹyin wa lara ohun to mu ki oun fẹran ilu naa.

Gomina ipinlẹ Oyo ni oun ti ṣeleri fun ọba to waja naa wi pe gbogbo ohun ti wọn se alaini ni ilu naa ni wọn yoo ni lai yọ nkankan kuro.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post