Ọ̀pọ̀ dẹ́yẹ sí ni mo ti ri nítori mó ni ààrún ori pípa- Liliya Kukushkina

Liliya Kukushkina-Nugmanova
Àkọlé àwòrán, Liliya ní wan máa ń dẹ́yẹ sí òun nítori òun ń ni àrun tó máá fa irún èèyan lọsa
    • Author, Diana Munasipova, & Kirill Glazkov
    • Role, BBC Russian Service

ọ̀pọ̀ dẹ́yẹ sí mi nítori mó ni ààrún ori pípa- Liliya

O lé ní ènìyàn ogóje mílíọ̀nù lágbàyé to ní ààrùn orí pípá lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

O jẹ́ ààrun tó maa ń mú kí ẹni ti ara rẹ̀ dá tàbí tí kò láàrun kankan lára ní ààrún tí irún ori rẹ̀ yóò maa re, nígbà míràn irun ojú àtí ti ìpénpéju àwọn ti irú àwọn tó ba ni àrun bẹ́ẹ̀

Liliya Kukushkina-Nugmanova ní àwọn ọmọ ilé iwé maa n dẹ́yẹ sí òun nílé ìwé nítori ìrísí òun.

Ìdẹ́yẹ sí ní

Ní báyìí, ó ń ràn àwọn ènìyàn míràn to wà nínú ipò yìí lọ́wọ́ láti bori gbogbo ìsòro wọ́n ní orílẹ̀ èdè Russia.

" tí àwọn ènìyàn bá kọ́ka ri mí ǹkan to máá ń wá si ọkàn wan ni pé: ṣe ó ni ààrun jẹjrẹ ni tàbí o ni sòòbìà?"

"Gbogbo ìgbà ni mo máa n ni láti sàlàyé pé mo ní ààrun to ma ń mú ki orí ènìyàn pá ni, kìí ṣe pe mo gba ọjọ ikú kìí sì ran ènìyàn."

Liliya àti awon omo tó ní ìṣòrò kan naa
Àkọlé àwòrán, Liliya tí n ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ọmọ to n koju iru isoro bẹẹ

Liliya tí pé ọdún mẹ́jìdínlọ́gbọ̀n báyìí sùgban kò mọ̀ pé òun ni ipenija yìí titi ti o fí bàlágà.

"Awọn ọmọkunrinkan wà ni ile iwe mi nígbà ti mọ pé ọdún mẹ́tàdínlogun, wọ́n dá ẹgbẹ́ kan silẹ loju opo Facebook ní wọ́n so pe àkọle rẹ́ ni Nugmanova jẹ́ àjẹ́ apári"

"Wọn rò pé yóò bimi nínú sùgbọ́n kò dun mi to bẹ́ẹ̀. kò túmọ̀ si pé ènìyàn buruku ni mí.

Oówo Liliya tún ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí nígbà to gba ara rẹ̀ bi ó ṣe rí, ó kọ ọ̀rọ̀ si ojú òpó facebook rẹ̀lóri gbogbo ǹkan to n koju tó si gbe fọtọ rẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú lái lo wíígì.

Liliya ni botilẹ jẹ́ pe o nira láti gba bí òun ṣe ri síbẹ̀ òun ti ni ìdunu báyìí.

Liliya ń ya ara rẹ̀ ni fọ́tọ̀ pẹ̀lú wíìgì lórí
Àkọlé àwòrán, Lati ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn wá, Liliya kìí jẹ́ ki ẹni kẹni ri ori rẹ̀ lai lo wíìgì

Kaní pe mo ni òòre ofẹ́ láti yíi ọwọ́ aago sẹ́yìn ni mí o ba gba ara mi ni ìmọ̀ràn láti gbadun ara mi jú ìgbà náà lọ, ti mi o si ni bìkítà lóri wíígì"

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wan ti gbà láti maa gbé orí pípa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn máá ń sọ ọ̀rọ̀ alùfànsá sí yálà lóri ayelujara tàbi lóju kòroju.

Liliy ń wo àrà rẹ̀ ninu dígí
Àkọlé àwòrán, Liliya náà gbà pé o nira láti gba pé bi òun ṣe ri rèé

Kíkà nípa àrùn náà àti bíbá àwọn míràn ti wọ́n ni irú àìsàn bẹ́ẹ̀ pàdé jẹ́ ǹkan tó ràn lọ́wọ́ láti ni ìwúrí nínú ara rẹ̀. O fi kún pé líla àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ lóri ààrun náà láti mú àdínku bá bí ìdẹ́yẹ sini lórí rẹ̀.

Nígbà míràn àwọn ọmọde a pade mi lóju pópó láti bèrè idi ti mo fi pári, súgbọ̀n mí kìí mọ bí maa ṣe ṣe àlàyé lóri rẹ̀

Ríràn àwọn míràn lọ́wọ́

Liliya sàlàyé pé ìwà dídẹ́yẹ sini àti níní ìfẹ́ ara ẹni máà ń jẹ ǹkan to nira fun àwọn ọmọ to ni ààrun yìí àti òbi wọ́n, nítori ìdí èyí ni mó ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ fún égbẹ́ ti mó dá sílẹ̀

" Mó mọ pè ọ̀pọ̀ òbí àwọn ọmọ tí wan ní ààrun tìí ma n fòyà pé ọmọ àwọn kò ni rí ọkọ fẹ́ tàbi rí iọṣẹ́ gidi. Wọ́n máa n ròó pé wọ́n o maa dẹ́yẹ́ si àwọn ọmọ ọkunrin wọ́n ko si ni bọ̀wọ̀ fún wọ́n láàrin awùjọ"

Gẹ́gẹ́ bi NHS ní ilé Gẹẹsi ṣe sọ kò sí ìtóju kan to pé péré péré fún ìwòsàn àarun náà, bákan náà ni Liliya tako kìí awọn ènìyàn máa ló òògun to n mú irun gùn lái jẹ pé dókìtà dari wọ́n bẹẹ.

Liliya àti awon ọmọ to ni ààrun apárí
Àkọlé àwòrán, Liliya ni ioṣẹ́ oun lati maa ran àwọn ọmọ yìí lọ́wọ́ tí mu iwuri ba oun la'ti ma sisẹ iranwo amuludun.

Ní ìgbà míràn àwọn òbí máa n gbìyànjú láti wo ààrun náà sàn, àwọn obi mi pẹ̀lú gbìyànju wọ́n a ma gún wọ́n ni abẹ́rẹ́ ti o tun le fa ààrun miran si ara ọmọ

Liliya ni ioṣẹ́ oun lati maa ran àwọn ọmọ yìí lọ́wọ́ tí mu iwuri ba oun lati ma sisẹ iranwo amuludun.

"Tí o ba tún pàdé elòmírà to ni ààrun náà, o mọ pé onirúuru ọ̀na ni o lé gbà láti gbe igbe aye rẹ̀" Nkan tó ṣe pàtàkì ni pé kìi'ṣe dandan ni kí o maa dá gbe wàhálà náà. O lè tọ àwọn onímọ lọ, o lé ba dokita sọrọ tàbi ki o darapọ mọ àwọn ẹgbẹ́ fun ìrànwọ́ lọ́wọ́ àwọn ti wọ́n ti koju isoro kan náà láti ràn ọ lọ́wọ́"