"Mo gba ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ sí Amẹ́ríkà láì lówó lọ́wọ́ tàbí mọ èèyàn pàtàkì"

Àkọlé fídíò, Ìrírí àgbà: Oladele Awobuluyi ní Nàíjíríà yóò jìyà báwọn dókítà ṣe ń yọ lọ sókè òkun
"Mo gba ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ sí Amẹ́ríkà láì lówó lọ́wọ́ tàbí mọ èèyàn pàtàkì"

Ìrírí àgbà: Oladele Awobuluyi ní Nàíjíríà yóò jìyà báwọn dókítà ṣe ń yọ lọ sókè òkun

Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi

Ìrírí àgbà: Oladele Awobuluyi ní Nàíjíríà yóò jìyà báwọn dókítà ṣe ń yọ lọ sókè òkun

Yoruba ni iriri lo n jẹ agba, ohun ti agbalagba ba si ri lori ijoko rẹ, bi ọmọde ba gun ori igi, o le maa ri.

Idi ree ti BBC Yoruba fi n tọ awọn agba awujọ lọ lati bu mu ninu omi ọgbọn wọn lati ipasẹ iriri ti wọn ti ri nile aye, ni abala eto Iriri agba ta n mu wa fun yin ni ọsọọsẹ.

Iriri yii naa si ni wọn yoo fi gba awọn ọdọ nimọran to le tọ wọn sọna lati se ile aye wọn, ki wọn maa ba si ẹsẹ gbe.

Yoruba naa lo sa ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọde wọ.

Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi, tii se akọsẹmọsẹ olukọ agba ni ẹka ẹkọ ede, onkọwe ati agba awujọ lo ba BBC Yoruba sọrọ ni abala Iriri agba lọsẹ yii.

Lasiko ifọrọwerọ naa si ni agba awujọ ọhun ti mẹnuba awọn anfaani ti orilẹede Naijiria se fun nigba ewe rẹ ati ọna to gba sanjọ pada fun orilẹede yii.

Amọ ka to sọrọ nipa ifọrọwerọ to waye, ẹ jẹ ka mọ diẹ nipa baba agba Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi,

Ta ni Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi?

Ọmọ bibi ilu Okeagbe nijọba ibilẹ iwọ oorun ariwa Akoko ni Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi.

Ọjọ Kẹtadinlogun osu Keje ọdun 1937 si lo dele aye lẹyin ti iya rẹ ti bi ọpọ abiku.

O ni awọn akẹẹgbẹ oun tawọn dijọ n sere lo se iwuri fun oun lati lọ forukọ silẹ nile ẹkọ bi o tilẹ jẹ pe o to ọdun kan lẹyin igba na, ko to le bẹrẹ ẹkọ kikọ.

Idi ni pe wọn ni ọwọ rẹ ko to eti nigba naa, ti wọn si ni ko pada lọ sile lati lọ dagba diẹ si, ko to wa bẹrẹ ile ẹkọ.

“Mo ri ẹkọ ọfẹ gba lọdun 1959 lai mọ ẹnikẹni fun iranwọ”

Nigba to n salaye awọn ọna ti orilede Naijiria fi gbe larugẹ lati goke agba, Awobuluyi ni ọdun 1959 ni oun ri ẹkọ ọfẹ ijọba apapọ gba lati lọ kawe ni Amẹrika.

“Mo se ọdun meji ati aabọ ni Colorado, ki n to wa lọ si Columbia nilu New York lati kawe gboye si ninu ede Latin.

Ijọba apapọ lo ran mi lọ, mo si bẹbẹ pe ki wọn fun mi ni ọdun meji si, ki n le ni iriri isẹ olukọ nile ẹkọ giga.

Ijọba gba fun mi, mo si pada sile lọdun 1969.’

Awobuluyi ni oun ko mọ ẹnikẹni ri, ti ijọba apapọ to fun oun ni ẹkọ ọfẹ lati lọ kawe.

Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi

"Ijọba se mi loore ni mo se pada wa sile wa se ẹlomiran loore"

O ni agbẹ ni awọn obi oun, oore nla si ni ijọba se oun.

“N ko tiẹ sopo pe mo fẹ duro silu oyinbo, mo mọ pe ijọba se mi loore, mo si gbọdọ pada wa sile, lati wa se ẹlomiran loore pẹlu imọ ti mo ni.

Ko tiẹ ro mi lara rara lati sọ pe mo fẹ pada wa sile nitori pe ile ni abọ sinmi oko, a si tun ni ero lati wa tun orilẹede wa se.

Kii se emi nikan lo pada wa sile, gbogbo awa ti ijba ran lọ soke okun, la pada wa.

Amọ bi ilu wa se ri bayii, lo n mu kawọn to ba lọ soke okun fi aake kọri, lati mase pada wa sile mọ.”

Awọn to fẹ fun wa nisẹ ma n duro de wa lati pari ile ẹkọ ni”

Nigba to n salaye pe oun ko se laalaa, ki oun to ri isẹ se, Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi fikun pe awọn ileesẹ to fẹ fun awọn nisẹ, maa n duro, ki awọn pari ile kọ ni.

“Ko ba jẹ ileesẹ ijọba ni eeyan fẹ ba sisẹ ni tabi ti aladani, ka to pari idanwo, ni wọn yoo ti maa wa fi ọrọ wa wa lẹnu wo.

O nilo lati mọ ẹnikẹni ri, ko to fun ọ nisẹ, to ba ti pegede ninu ifọrọwerọ pẹlu wọn.”

Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi ati aya rẹ

“A maa jiya bi awọn dokita wa se n sa lọ soke okun”

Ọjọgbọn Awobuluyi tun woye pe inu oun ko dun si bi awọn dokita wa se n sa lọ soke okun.

O ni yoo nira fun Naijiria lati gberi nitori awọn to yẹ ko maa fi orilẹede yii yangan, lo n sa lọ yẹn.

Bakan naa lo ni a maa jiya si bi ọpọ awọn dokita naa se n sa kuro nilẹ Naijiria nitori pe yoo se akoba fun ẹka ilera wa.

O wa rọ ijọba apapọ lati tete mọ pe ojuse oun ni lati setọju awọn ọmọ orilẹede yii nitori eyi nikan lo le dẹkun ba se n sa lọ soke okun.

Ọjọgbọn Oladele Awobuluyi

“Itanjẹ gbaa ni bawọn obi kan ko se fẹ ki awọn ọmọ wọn sọ ede Yoruba”

Nigba to n foju abuku wo awọn obi ti ko fẹ ki awọn ọmọ wọn maa sọ ede abinibi, paapaa Yoruba, Awobuluyi ni itanjẹ gbaa ni iwa yii.

O ni wọn kan n tan ara wọn jẹ ni nitori awọn isẹ to labuku ni wọn yoo pada se loke okun ti wọn ba sa lọ.

O wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun imọ nipa ede Yoruba to yan laayo, ti Ọlọrun si tete fi ọna han oun.

O ni lẹni ọdun marundinlaadọrun, oun si n kọ iwe jade, ti oun si n ronu nipa ohun tuntun ti oun le mu jade nipa ede Yoruba lojoojumọ.