Wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń díje sípò Ààrẹ, ilé aṣòfin àtàwọn obìnrin olùdíje

Awon oludije sipo aare

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, INEC ti fi orúkọ àwọn olùdíje sípò òṣèlú tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ léde.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí INEC fi sórí ayélujára Twitter rẹ̀, ni wọ́n ṣe àgbéjáde orúkọ àwọn olùdíje sípò Ààrẹ, igbá-kejì Ààrẹ, àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan.

INEC ní èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin eto ìdìbò ọdún 2022.

Ayafi ti Oludije kan base alaisi ni ayipada to le waye lori awọn orukọ oludije ta fi sita - INEC

Wọ́n ní àwọn tí àwọn fi orúkọ wọn síta náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú wọn tẹ̀lé ìlànà tó tọ́ lásìkò tí wọ́n ṣe ìdìbò abẹ́nú.

Àtẹ̀jáde náà tí Agbẹnusọ INEC, Festus Okoye fi léde ní orúkọ àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti díje nìyí.

O fikun pe kò sí àyípadà kankan tó lè wáyé lórí rẹ̀ mọ́ àyàfi tí ọ̀kan nínú àwọn olùdíje náà bá ṣe aláìsí.

Okoye ní gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú méjìdínlógún tí INEC fọwọ́ sí ni wọ́n fi olùdíje sípò Ààrẹ kalẹ̀.

Bákan náà ló ní àwọn olùdíje 1,101 lọ ń díje fún ipò sẹ́nétọ̀ tí àwọn tó ń díje sípò ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin sì jẹ́ 3,122.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Oruko awon oludije ti INEC fi sita

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER

Oruko awon oludije ti INEC fi lede

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER

Oruko awon oludije

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER

Àwọn mélòó ló jẹ́ ọmọ Yorùbá nínú àwọn tó ń díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà?

Nínú àwọn méjìdínlógún tí INEC gbé orúkọ wọn jáde pé wọ́n ń wá ipò Ààrẹ márùn-ún nínú wọn lọ jẹ́ ọmọ Yorùbá.

Àwọn náà ni:

Omoyele Sowore

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, yelesowore/Instagram

Sowore Omoyele Stephen ló ń díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú African Action Congress, AAC.

Ọmọ bíbí ìlú Ese-Odo ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Sowore. Ọdún 1971 sì ni wọ́n bi.

Sowore jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, òun sì ni olùdásílẹ̀ Iléeṣẹ́ ìròyìn Sahara Reporter.

Ìgbà ìkejì rèé tó ń díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà. Ní ọdún 2019 ló kọ́kọ́ díje tó sì fìdí rẹmi sọ́wọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/FACEBOOK

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu náà jẹ́ ọ̀kan lára olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.

Gbajúgbajà olóṣèlú ni Tinubu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bó ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ àti adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Ní ọdún 1952 ni wọn bí Tinubu ní ìpínlẹ̀ Eko.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko fún sáà méjì, láàárín ọdún 1999 sí 2007, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó ń wá ipò Ààrẹ Nàìjíríà.

Adenuga Sunday Oluwafemi

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ogun ni Adenuga Sunday Oluwafemi tó ń díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Boot Party, BP.

Ọmọ ọdún méjìdínláàdọ́ta ni Adenuga tó sì jẹ́ ògbóǹtarigì oníṣòwò.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó ń díje fún ipò Ààrẹ Nàìjíríà.

Abiola Latifu Kolawole

Kola Abiola

Oríṣun àwòrán, Kola Abiola/FACEBOOK

Ọmọ bíbí olóògbé M. K. O. Abiola ni Kola Abiola tó ń díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Redemption Party, PRP.

Ọdún 1962 ni wọ́n bí Kola Abiola tó sì ti pé ọgọ́ta ọdún báyìí.

Ìgbà àkọ́kọ́ tó ń díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà nìyí.

Adebayo Adewole Ebenezer

Adebayo Adewole

Oríṣun àwòrán, Adebayo Adewole/FACEBOOK

Ọmọ bíbí ìlú Ondo ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Adebayo Adewole Ebenezer tó sì jẹ́ ọmọ àádọ́ta ọdún.

Agbẹjọ́rò ni Adewole Adebayo tó sì tún jẹ́ olùdásílẹ̀ Iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán KAFTAN TV.

Lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP ló ti ń díje.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí yóò gbé gbá láti du ipò Ààrẹ Nàìjíríà.

Àwọn mélòó ni obìnrin tó ń wá ipò òṣèlú ní Nàìjíríà?

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí INEC fi síta ṣe sọ àwọn obìnrin 381 lọ ń wá ipò òṣèlú sí àwọn ipò ijoba àpapọ̀.

Nínú àwọn 381 yìí, ẹnìkan péré ló ń wá ipò igbakeji Ààrẹ, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ni àwọn yòókù ń gbèrò láti lọ.

Lati ilẹ̀ Yorùbá, awọn ogún ló ń díje sípò sẹ́nétọ̀ tí àwọn àádọ́rin sì ń wá ipò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin.