Eku kò ké bí eku ní Nàìjíríà, a tí sọ fún Buhari láìmọye ìgbà - Sultan

Oríṣun àwòrán, others
Araalu nikan lo ku to le tan isoro ta dojukọ - Sultan
Sultan ti Sokoto, Sa’ad Abubakar kẹta ti sọrọ lori ipo ti orilẹede Naijiria wa bayi, eyi to ni gbogbo nkan ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
Ọba alaye naa sọ eleyi lọjọ Isẹgun nigba to sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Abuja.
Sultan ni ọpọ igba ni awọn ti pe akiyesi Aarẹ Muhammadu Buhari si bi ọrọ orilẹede Naijiria ko ṣe ni ojutu.
Sultan salaye pe awọn araalu nikan lo le tan isoro orilẹede yii, ti wọn ba le gbe igbesẹ to yẹ lati gbogun tawọn ipenija ta dojukọ.
O wa gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati mase ri eto idibo gẹgẹ bi ogun sugbọn ki wọn ri gẹgẹ bi ọna lati mu iyipada pa Naijiria.
"A ko ni dẹkun lati ma ba ara wa sọrọ, a ko ni jẹ ko suwa rara"
“Ẹni to ba ni nkan lọ bo ṣe yẹ ko lọ ni lorilẹede yii, o parọ fun yin ni o.
“A ti sọ ni aimọye igba fun Aarẹ Muhammdu Buhari.
“Nkan ko lọ bo ṣe yẹ ati pe bi eeyan ba ti mọ isoro rẹ, eeyan ti ri idaji ọna abayọ si isoro naa.
“A ko ni dẹkun lati ma ba ara wa sọrọ, a ko ni jẹ ko suwa rara."
‘Gbogbo ọmọ Nàìjíríà tó kúrò lẹ́wọ̀n ní Dubai tó ń tún ń ba ìjọba àpapọ̀ lórúkọ jẹ́, ẹ ṣọ́ra o!’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun, NIDCOM ti ki awọn ọmọ Naijiria to ha si ilẹ United Arab Emirate iyẹn dubai lati jawọ ninu biba orukọ ile ati orilẹede bi wọn jẹ lẹyin odi.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Abdur-Rahman Balogun sọ pe ọpọlọpọ awọn to ha si oke okun, arinrinajo lọna aitọ ni wọn ti wọn ti fi ẹwọn gbara lọpọ igba tori wọn kọ lati tẹle ilana to tọ.
“Ni ibamu pẹlu ẹyinju aanu ijọba, ijọba buwọlu ki wọn ko ọọdunrun ọmọ Naijiria to ha si ilu Dubai pada wa sile.
Amọ o ba ni ninu jẹ pe ọpọlọpọ awọn ti eyi kan gaan ko fọwọsowọpọ pẹlu ijọba gẹgẹ bi wọn n kọ lati tẹle ilana.
“Iwadii tun fihan pe o le ni ọgọrun ọmọ Naijiria to ti ṣẹwọn oriṣiriṣi (latori eyi to rọ mọ ogun oloro, adigunjale kaadi ibanisọrọ, jibiti ati bẹẹ bẹẹ lọ.)
T i wọn si ti wa ba ara wọn ni ibudo oniruuru ti wọn si n wa ki ileeṣẹ Naijiria to wa ni Dubai ko wọn pada wale ni kiakia.
Ohun tiwọn gaan lo n ke tantan ju,” atẹjade naa wi bẹẹ.
Bakan naa ni atẹjade yii fi ọrọ alaga ajọ, Abike Dabiri-Erewa sita pe o ni “dipo ki wọn faramọ titẹle ilana ti ileeṣe Naijiria to wa ni Dubai fun wọn, awọn ọmọ Naijiria kan fi irọ le awọn oniroyin kiri nipa ijọba apapọ Naijiria ati ti Dubai papọ”.
Ibanijẹ lori iroyin yii gẹgẹ bo ṣe sọ yoo tunbọ sọ ẹsun ti ko dara di eyi to buru jai ni ti yoo si ṣe ọpọlọpọ akoba.
O fi kun un pe irọ patapata gbaa ni ẹsun pe wọn pa awọn ọmọ̀ Naijiria ti si Dubai.
O ni o to si jẹ aṣinilọkan gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okere ati ajọ aṣoju Naijiria ṣe ti n ṣe iṣẹ takuntakun pẹlu ijọba UAE lati ṣeranwọ fun awọn ọọdunrun ọmọ Naijiria to ha si ọhun fun oniruuru idi.
ǹọwa araL latori gbigbe niluu kọja gbendeke wọn, iwe idanimọ to ti sọnu, ai ni akọsilẹ paapaa ni ti awọn ọmọde to fi mọ awọn ẹsun oniruuru pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa Dubai.















