Ṣé lóòótọ́ ni pé tí Ọba bá wàjà dandan ni kì wọ́n lọ́ túfọ̀ fún oyin ní UK?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìpapòdà Ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ọbabìnrin Elizabeth Kejì àti bí Ọba Charles Kẹta ṣe ti gba ipò Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ń hú àwọn àṣà tó ti wà láti ọjọ́ pípẹ́ dìde nínú ìdílé náà.
Kódà ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀ nípa àṣà oyè ìdílé ọba Gẹ̀ẹ́sì ọ̀hún ni kò mọ̀ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí tí yóò sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn wí pé àwọn nǹkan báyìí wà lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe.
Lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìwọ̀nyí:
Títúfọ̀ ikú Ọbabìnrin fún àwọn oyin
(Ọ̀pọ̀ àwọn àtẹ̀jáde ló wà lórí ayélujára Twitter ìdílé Ọba Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàfihàn ilé oyin ní ààfin Buckingham.)
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Pẹ̀lú bí ìkéde ikú Ọbabìnrin Elizabeth II ṣe gba gbogbo ayé kan, lórí ayélujára, rédíò àti amóhùnmáwòrán, àwọn kan wà tó jẹ́ wí pé dandan ni láti túfọ̀ náà fún wọn láyè ọ̀tọ̀.
Àwọn oyin Ọbabìnrin náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ túfọ̀ fún ìpapòdà Ọba náà fùn-ún.
John Chapple tó ti ń tọ́jú àwón oyin Ọbabìnrin láti ọdún mẹ́ẹ̀dógún ló túfọ̀ ikú náà fún àwọn oyin tó wà ní ààfin Buckingham àti Clarence House (ilé tí Ọba Charles ń gbé tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọọba Wales).
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí Chapple ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn, ó ní òun ṣàlàyé fún àwọn oyin náà láti ṣe dada pẹ̀lú Ọba tuntun.
Àṣà yìí ló jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbàgbọ́ pé tí wọn kò bá sọ fún àwọn oyin náà, ó ṣeéṣe kí wọ́n má pèsè oyin mọ́ tí wọn kò bá sọ fún wọn wí pé wọ́n ti ní Ọba tuntun.
“Ohun tí a máa ń ṣe ni pé a máa kan ilẹ̀kùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ilé àwọn oyin náà láti sọ fún wọn wí pé ọba ti kú ṣùgbọ́n a ma sọ fun láti má lọ pé ọba tuntun ma hùwà dada sí wọn.”
Ṣé Ọba tuntun yóò ní ọjọ́ ìbí méjì?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lára àwọn ìpinnu tí Ọba Charles III gẹ́gẹ́ bí orí adé tuntun yóò ṣe ni ọ̀rọ̀ bóyà òun náà yóò máa ṣe àyẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì.
Ọbabìnrin Elizabeth II bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹrin ọdún ni wọ́n bi tó sì máa ń ṣe ayẹyẹ rẹ́, gbogbo sátidé tó bá ṣìkejì nínú oṣù Kẹfà ọdún ló máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mìíràn pẹ̀lú ohun tí wọ́n máa ń pè ní “Trooping di colour”.
Ìdí ni pé àkókò òtútù ni oṣù kẹrinm ọdún máa ń bọ́ sí ní UK tí oṣù kẹfà sì jẹ́ àkókò tí ooru máa ń bẹ̀rẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, ìgbésẹ̀ yìí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, láti orí Ọba George Kejì ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1748. Òun ló fi orí ọjọ́ ìbí rẹ̀ sọ ayẹyẹ kan tó ti máa ń wáyé níbẹ̀.
A ò tíì mọ ohun tí ìpinnu Ọba Charles Kẹta yóò jẹ́ lórí àṣà yìí àmọ́ oṣù Kọkànlá tó jẹ́ àsìkò ooru.
Ònímọ̀ nípa ìtàn ìdílé Ọba Gẹ̀ẹ́sì kan Richard Fitzwilliams sọ fún BBC pé òun lérò wí pé ọba Charles yóò fẹ́ fi ohun gbogbo kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà àti pé ayẹyẹ Trooping di Colour jẹ́ èyí tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà.
Fitzwilliams ní ohun kan tó tún jẹ́ àṣà Britain ni pé ènìyàn kò le sọ ní pàtó pé bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí èyí tí tó ni ó ṣe ìdíwọ́ fún ayẹyẹ oyè jíjẹ Ọbabìnrin lọ́dún 1953.
Lílo èniyàn dípò ẹṣin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láti ọdún 1901 ni àṣà lílo àwọn ènìyàn- àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò orí omi- dípò ẹṣin láti máa gbé òkú ọba bẹ̀rẹ̀.
Ṣaájú ìgbà náà, orí ẹṣin ni wọ́n máa ń gbé òkú àwọn Ọba fún gbogbo àwọn ayẹyẹ ìkẹyìn tí wọ́n yóò bá ṣe fún-un.
Àmọ́ nígbà òkú Ọbabìnrin Victoria ojú ọjọ́ kò dara tó bẹ́ẹ̀, tí òtútù sì pọ̀ ní ìlú náà débi wí pé àwọn ẹṣin fẹ́ sọ òkú Ọba náà sílẹ̀.
Onímọ̀ nípa ìtàn Kelly Swab sọ fún BBC wí pé Ọba Edward VI tó jẹ́ àrẹ̀mọ Victoria ló pàṣẹ nígbà náà wí pé kí àwọn ọmọ ogun orí omi tó wà níbi ètò náà gba òkú ọ̀hún.
Swab ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bá di ohun ìtìjú lójú gbogbo ayé tí àwọn ọmọ ogun náà kò bá gba òkú ọ̀hún lọ́wọ́ àwọn ẹṣin náà.
Ó ní láti ìgbà náà ló ti di àṣà kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò omi máa gbé òkú ọba ní èyí tó sì wáyé lásìkò Ọba tó jẹ kẹ́yìn ṣaájú Ọbabìnrin Elizabeth.
Nígbà ìsìnkú ọba George VI lọ́dún 1952, àwọn ènìyàn méjìláàdóje ló gbé òkú Ọba náà.
Kíkán ọ̀pá àṣà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lára àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe lára oyè ìdílé ọba ọ̀kan náà wà tí àwọn ènìyàn kò mọ̀ nípa rẹ̀.
Àṣà kan wà tí wọ́n fi máa ń fún Lord Chamberlain ṣe.
Lord Chamberlain ni olórí òṣìṣẹ́ ní ìdílé oyè tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ wí pé òun ló máa ń tẹ̀lé ọba lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọdọọdún.
Tí ọba bá kú Lord Chamberlain gbọdọ̀ lọ kán ọ̀pá àṣẹ funfun sí orí sàárè ọba tó papòdà náà láti ṣàfihàn wí pé òpin ti dé bá sáà ọba náà.
Ẹni tó jẹ́ Lord Chamberlain báyìí ni Andrew Parker, ọ̀gá àgbà M15 tẹ́lẹ̀ rí.
Ní oṣù Kẹrin ọdún 2021 ló gba ipò náà, tí àṣà náà sì ti wà fún ọjọ́ pípẹ́.
Richard Fitzilliams sọ wí pé àwọn àṣà yìí ló mú ìdílé Ọba Gẹ̀ẹ́sì yàtọ̀ sí ti ìdílé mìíràn ní àgbáyé.












