A ti ṣetán láti dáwọ́ ìyanṣẹ̣lódì dúró – ASUU

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti ni Naijiria, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke ti ni ẹgbẹ awọn olukọ, ASUU ti ṣetan lati pada si ileẹkọ.
Osu Keje ree ti awọn olukọ Fasiti ti gunle iyanṣẹlodi kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi si ti fa ifẹhọnuhan ti awọn akẹkọọ Fasiti lọgọọrọ wọn ti opopona marosẹ Ibadan si Eko lori ẹsun pe awọn ko ni kuro nibẹ afi ti ijọba ba fagile iyanṣ̣elodi awọn olukọ nipa fifun wọn ni adehun ti wọn jọ gunle.
Amọ ninu ọrọ rẹ, Osodeke ni ọna kan ti awọn le fi wọgi le iyanṣẹlodi ọhun ni ki ijọba buwọlu adehun ti awọn ati ijọba jijọ ti ẹsẹ bọ.
O sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ohun to kan bayii ninu iyanṣẹlodi olosu meje ti wọn gunle.
Oni ni igbẹjọ n tẹsiwaju lori iyanṣlodi ASUU ti ijọba gbe lọ si ileẹjọ
Laipẹ yii ni ijọba apapọ gbe ẹgbẹ oṣiṣẹ naa lọ si ileẹjọ lati kan an ni ipa fun wọn ki wọn pada si ileẹkọ.
Lasiko igbẹjọ naa ni adajọ naa sun igbẹjọ naa di ọjọ Ḳerindinlogun, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 ki igbẹjọ le tẹsiwaju.
Ninu ọrọ rẹ, Osodeke ni awọn ṣetan lati pada si ileẹkọ amọ ijọba gbọdo ṣe ipa ti wọn naa, ki ijiroro ati adehun waye lori ọrọ wọn.
Kini ASUU n beere fun lọwọ ijọba Naijiria?
Ẹgbẹ ASUU ni dandan ni ijọba gbọdọ lo apo isuna awọn olukọ Fasiti, University Transparency Accountability Solution (UTAS) lati fi san owo oṣu wọn.
Bakan naa ni wọn ni ki ijọba pese ayika to dẹrun awọn akẹkọọ , ki wọn si tun awọn Fasiti to ti dẹnukọlẹ se pada.
Nibayii, gbọn mi si –o mi ko to o n waye nipa sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ fun osu meje ti wọn fi daṣẹ silẹ yii, amọ ijọba apapọ ni ko si ohun to jọọ.
Ni ọdun 2009 ni ijọba ṣeleri pẹlu adehun pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU lati maa mu idagbasoke ba eto ẹkọ wọn ni ọdọọdun marun un-marun un.
Àfi tí ìjọba bá dáwọ́ ìyanṣẹ́lódì ASUU dúró ni a tó lè dáwọ́ ìfẹ̀họ́núhàn dúró – Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ ifẹhọnuhan ni opopona Ibadan si Eko, eleyii to fa akoba fun awọn to n lọ si ibi iṣẹ oojọ wọn.
Bi oju ọjọ ṣe ri ti awọn eniyan si n tiraka lati lọ si ibi iṣẹ wọn ni awọn akẹkọọ naa di opopona.
Ohun ti wọn n bere fun ni ki ijọba fopin si iyanṣẹlodi awọn olukọ wọn to ti wa nile fun oṣu meje bayii lai si ojutuu si iṣoro naa.
Awọn akẹkọọ to wa ni oju popo naa ti wọn jẹ ara ẹgbẹ awọn akẹkọọ, National Association of Student ti yari pe awon ko ni jawo ifehonuhan han titi opin yoo fi deba iyanṣẹlodi awọn olukọ wọn ni fasiti kaakiri orilẹede Naijiria.
Bakan naa ni wọn n bere fun ki wọn fi owo osi juwe ile fun minisita fun eto ẹkọ, Mallam Adamu Adamu ati minisita fun eto igbaniṣiṣẹ, Dokita Chris Ngige.
Ohun ti wọn n sọ ni pe ‘’ opin gbọdọ de ba iyanṣelodi awọn olukọ wa
Ọna ti wọn di naa ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo, ti o si ti fa inira fun awọn arinrinajo.
Lara awọn akẹkọọ to ba awọn oniroyin sọrọ ni o dabi ẹni pe ijọba Buhari ko naani eto ẹkọ to si n tẹ oju ẹtọ awọn eniyan mọlẹ lai naani ọjọ ọla wọn.
Ijọba fesi si ifẹhọnuhan awọn akẹkọọ
Amọ ijọba Buhari ti fesi si ifẹhọnuhan awọn akẹkọọ ni opopona maroṣẹ Ibadan si Eko, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.
Minisita fun iṣẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola ni o tẹ ẹtọ awọn eniyan mọlẹ ki awọn akẹkọọ naa di opopona marọsẹ.
O ni bi o tilẹ jẹpe ẹtọ awọn akẹkọọ naa ni lati ṣe ifẹhọnuhan amọ wọn ko lẹtọ lati fi ifẹhọnuhan wọn pa awọn eniyan to n rin ni opopona maroṣẹ.
Ohun to fa airojutu si iyanṣẹlodi awọn ẹgbẹ olukọ fasiti ASUU
Ọkan gboogi ninu ohun to fa ifasẹyin lori idunadura awọn olukọ ati ijọba apapọ ni ọrọ ibi ti wọn fẹ maa san owo si.
Ẹgbẹ ASUU ni dandan ni ijọba gbọdọ lo apo isuna awọn olukọ fasiti, University Transparency Accountability Solution (UTAS) lati fi san owo oṣu wọn.
Wọn ni ajọ to yẹ ko ṣe abojuto apo isuna naa ti kọ silẹ lẹyin ti wọn ti ṣe atunto oju opo naa.
Ọpọ igba ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU ati ijọba apapọ ti ṣepade pẹlu ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ igbanisisẹ ati iṣẹ lati wa ọna abayọ si iyanṣẹlodi yii.
Ni ọdun 2009 ni ijọba ṣeleri pẹlu adehun pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU lati maa mu idagbasoke ba eto ẹkọ wọn ni ọdọọdun marun un-marun un.
Ẹgbẹ ASUU ati Ijọba apapọ wọ iya ija papọ
Ileẹjọ to n risi ọrọ iṣe ti dasi ọrọ ijọba apapọ ati ASUU lori ọrọ iyanṣẹlodi naa.
Ijọba apapọ lo gba ileẹjọ lọ lati kan an ni ipa fun awọn olukọ naa lati pada si ileẹkọ ni tipa tipa.
Minisita fun eto iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Chris Ngige ni ki ileẹjọ paṣẹ ni kiakia ki awọn olukọ naa pada si ẹnu iṣẹ.
Bakan naa ni ki ileẹjọ paṣẹ boya awọn olukọ naa laṣẹ lati gba owo oṣu lasiko ti wọn ba yansẹlodi.
Bakan naa ni ki ileẹjọ sọ boya ijọba apapọ ko gbiyanju lori ati mu adehun ti wọn ba ẹgbẹ ASUU ṣe lati ọdun 2020.












