ASUU vs FGN: Ìjọba tó fọwọ́ ara wọn kó ìgbìmọ̀ alágbára méjì jọ náà ni yóò da gbogbo ìdúnàádúrà rú - Femi Falana

Ile ẹjọ́ to n gbọ ẹjọ́ laarin ìjọba àpapọ̀ Naijiria ati ẹgbẹ́ àwọn oṣiṣẹ Fáṣítì, ASUU nilu Abuja tun ti sun ìgbẹ́jọ́ naa siwaju titi di ọjọ Kọkàndínlógún Oṣù Kẹ̀sán Ọdun 2022.
Lonii ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ́ ni ọjọ ti wọn da yii gan ni ẹjọ́ naa yoo bẹ̀rẹ̀.
Ijọba àpapọ̀ lo gbe ẹgbẹ́ ASUU lọ sile ẹjọ́ latari iyanselodi ọlọjọ gbọọrọ ti wọn gun le lati oṣù Keji ọdun 2022.
Ijọba kọ iwe ipẹjọ si ile ẹjọ́ lati dawọ iyanselodi náà duro titi di igba ti ile ẹjọ́ yoo gbọ́ ẹjọ́ ti wọn yoo si ṣe ipinu fún igbesẹ to kan.
Gbas gbos laarin awọn agbẹjọro ijọba ati ti ASUU
Ni ti awọn agbejoro ASUU, wọn fẹ ki ile ẹjọ́ sun ìgbẹ́jọ́ ọhun siwaju amọ awọn agbejoro ti ìjọba kọjalẹ pe awọn ko gba gẹgẹ bi wọn ṣe so fun ile ẹjọ́ pe kò nílò kí wọn sún ìgbẹ́jọ́ naa siwaju nitori ọrọ iyanselodi ASSU jẹ ọrọ to nilo akiyesi kia kia to si kan gbogbo ilu gbọn gbọn.
Ṣe ni adajọ to da ẹjọ́ naa, Adajọ Polycarp Hamman
toju bọ gbogbo ọrọ naa ti wọn gbe wa to si gba pe iwe ìpéjọ naa ti to fun gbigbọ awọn yoo si gbọ́ ọ lọjọ Aje ọjọ Kọkàndínlógún Oṣù Kẹ̀sán Ọdun 2022.
Ki lo ṣẹlẹ nile ejọ?

Nnkan mii to tun sẹlẹ nile ẹjọ́ lọjọ Ẹti ni asiko ti tí agbejoro nipa ọrọ aráàlú, Amofin Agba Ebun Adegboruwa ran ile ẹjọ́ leti nipa ìwé ìpéjọ lati ọdọ àjọ SERAP pe ki wọn daa pọ mọ ẹjọ́ ọhun tori awọn naa da sii ti wọn si ni àwọn n ṣojú awọn akẹ́kọ̀ọ́.
Ẹwẹ, Agbejoro àgbà fun ijoba, James Igwe ko gba adapọ ti wọn dabaa pe ko tii to gbọ. Adajo Polycarp Hamman yoo boju wo adapọ naa lọjọ Aje Ọ̀sẹ̀ to n bọ.
Ohun ti Agbẹjọro ijọba sọ?

Agbejoro fun ijoba àpapọ̀ James Uko Igwe sọ fun awọn oniroyin lẹyin ìgbẹ́jọ́ pe o da oun loju pe gbogbo ọna ti ijọba le gba ni wọn ti lo tan patapata lati yanju ọrọ yii lo tun mu wọn wa sile ẹjọ́ tori o jẹ ọrọ to jẹ gbogbo araalu logun.
Ó fi kún un pé àwọn ọmọ ọlọmọ ti ko ṣẹ to wa nile lati Oṣù méje sẹ́yìn ni ọrọ yìí n ṣàkóbá fún eyi lo si mu ki Minisita fun ọrọ awọn Oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Chris Ngige fi ọrọ ile ẹjọ́ sii ó sì ní òun gbagbọ pé fun dáadáa ni igbesẹ náà.
Agbẹjọro ASUU, Femi Falana sọ̀rọ̀
Agbejoro Àgbà ní Naijiria, Femi Falana sọ fún àwọn oniroyin pe digbi ni ASUU ṣe tán láti ki ọwọ bọ adehun pẹlu ijọba ní gbogbo ìgbà, "ìṣòro ti a n koju gẹgẹ bi orileede ni pe ijọba kii bọ̀wọ̀ fun adehun, ohun lo si n fa iyanselodi."
Koko ohun to n fa ẹjọ́ yii ni lati fa ìnilára fun gbogbo idunadura ti ko si ni si ọna mọ lati yanju ìṣòro yìí - ẹ gbudọ dunadura, ìyẹn si ni a ń koju bayii.
Ó ni ijọba to fi ọwọ ara wọn ko igbimọ jọ náà ni yoo pada dá gbogbo idunadura igbimọ pataki mejeji nu lori iyanselodi yìí.
"Ìjọba nikan lo le fopin si iyanselodi yìí, toripe ijọba ti dalẹ̀ òtítọ́ awọn eeyan, kii ṣe ASUU nikan bi kò ṣe àwọn ẹgbẹ́ mii náà.
Koko ọrọ meji to wa nilẹ ni wípé:
Awọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fasiti ti ijọba béèrè fún amuṣẹ ọkan lára afẹnuko ti ijọba fọwọ́ sì pẹlu wọn lọdun 2009 lori ilana sisan owo oṣù ti ijọba fẹ maa lo fun wọn.
Ẹwẹ, ASUU ń tẹpẹlẹ mọ lilo ìlànà University Transparency Accountability Solution (UTAS) eyi to lodi si ti ijọba, ìyẹn Integrated Payroll and Personnel System (IPPIS).
Ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ òfin bíi 100 ni yóò ṣojú ASUU nílé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ tó pè tako ìjọba àpapọ̀.

Oríṣun àwòrán, Others
Nnkan bii ọgọrun ọjọgbọn ninu imọ ofin lo ṣeeṣe ko ṣoju ASUU ninu ẹjọ ti wọn pe tako ijọba apapọ lori iyanṣẹlodi ẹgbẹ ọhun to ti wọ oṣu meje bayii.Ọjọ Aje ni ASUU pe ẹjọ naa niwaju ile ẹjọ kan to n gbọ nipa ọrọ oṣiṣẹ, National Industrial Court, NIC, niluu Abuja.
- Ètò ìforúkọsílẹ INEC, olùdìbò 1.126m ni ìjákulẹ̀ dé bá
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò rìrìnàjò ìkẹyìn pẹ̀lú ọkọ̀ òfururfú
- Ni ilẹ̀ Adúláwọ̀, Wo ǹkan míì tí àwọn eèyàn ń sọ̀ nípa ìgbé ayé Obabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Camilla di Olorì tuntun
- Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?
- Irú Ọba wo ní Charles yóò jẹ́?
- Wó bí gbogbo ètò ìsìnkú náà yóò ṣe lọ ní Ọjọ́ Aje, Ọjọ́ Iṣẹ́gun, Ọjọ́ru àti Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀...
Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti gbogbo ipade laarin ASUU ati ijọba apapọ lati yanju aawọ naa, ki awọn akẹkọọ ni fasiti ijọba le pada sẹnu ẹkọ ja si pabo.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ọjọ melokan sẹyin ni Adamu Adamu sọ pe ẹgbẹ naa ti gbiyanju lati yanju aawọ rẹ pẹlu ijọba amọ pabo ni gbogbo igbiyanju rẹ ja si.
Olukọ kan ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Abuja, amọ ti ko fẹ ki awọn akọroyin darukọ oun sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Daily Post pe, ogunlọgọ awọn agbẹjọro to jẹ ọmọ ẹgbẹ ASUU ni yoo ya bo ile ẹjọ ti igbẹjọ naa ba bẹrẹ.O ni "A ko nilo lati gba agbẹjọro kankan nigba ti a ni nnkan bii ọgọrun agbẹjọro laarin wa ti wọn si ṣetan lati ṣoju wa nile ẹjọ."
"ASUU ko da bi awọn ẹgbẹ to toku, kaka ki ijọba apapọ wa ojutu si iyanṣẹlodi ASUU, nnkan mii ni wọn n ba kiri."
Ẹwẹ, ijọba apapọ naa ti gbe ASUU lọ sile ẹjọ lori iyanṣelodi yii kan naa.
Ni kete ti wọn pe ẹjọ ti ijọba apapọ pe niwaju adajọ ni agbẹjọro, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Ebunolu Adegoruwa, SAN, sọ pe ASUU naa ti pe irufẹ ẹjọ kan naa tako ijọba apapọ.
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Polycarp Hamman wa sun ẹjọ naa si ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 yii fun itẹsiwaju rẹ.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2022 yii ni iyanṣẹlodi naa bẹrẹ.
- ASUU: Àrúmọjẹ lásán ni N208 bílíọ́nù tí Buhari buwọ́lù
- ASUU Strike- Da padà, fásítí ìpínlẹ̀ kìí ṣe àtẹ̀mẹ́rẹ̀ – KWASU, UNIOSUN fèsì fún ASUU - BBC News Yorùbá
- LAUTECH sọ̀rọ̀ lórí akẹ́kọ̀ọ́jáde rẹ̀ tó dá ìwé ẹ̀rí padà, tó tún fẹ́ gba owó iléẹ̀kọ́ tó san - BBC News Yorùbá
- Kíló kàn? Bí ètò ìsìnkú yóò ṣe lọ lójoojúmọ́ rèé títí Obabìnrin yóò fi wọ káà ilẹ̀
- Òkú Ọbabìnrin Elizabeth balẹ̀ sí Edinburgh, wo ìgbésẹ̀ tó kàn....
- Bí ètò Ọba jíjẹ àtàwọn tó le jọba ṣe yípadà rèé
- Ni ilẹ̀ Adúláwọ̀, Wo ǹkan míì tí àwọn eèyàn ń sọ̀ nípa ìgbé ayé Obabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- À-wọn agbébọn ṣèkọlù sí Sẹ́nétọ̀, gbẹ̀mí ènìyàn 5
SERAP àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì márùn ún pe ìjọba Nàìjíríà lẹ́jọ́ lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU
SERAP àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì márùn ún pe ìjọba àpapọ̀ lẹ́jọ́ lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU.
Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP, atawọn akẹkọọ fasiti marun un mii ti gbe Aarẹ Muhammadu Buhari lọ sile ẹjọ.
Lori ẹsun pe o kọ lati yanju aawọ to wa larin ẹgbẹ ASUU ati ijọba apapọ, eyii to fa iyanṣẹlodi oloṣu meje to n lọ lọwọ.Ìdí rèé tí a fí gbé ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU lọ sílé ẹjọ́ lórí ìyanṣẹ́lódì- Ìjọba Nàìjíríà
Wọn ni awọn n fẹ ki ile ẹjọ naa kede pe ohun ti Buhari n ṣe ko ba ofin mu bo ṣe la oju rẹ silẹ ti iyanṣẹlodi ASUU fi pe oṣu meje ti ko si ri nnkankan ṣe nipa rẹ.
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò rìrìnàjò ìkẹyìn pẹ̀lú ọkọ̀ òfururfú
- Ọba Charles Kẹta yóò ṣe àìsùn lẹ́gbẹ́ẹ̀ òkú ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth
- Òkú Ọbabìnrin Elizabeth balẹ̀ sí Edinburgh, wo ìgbésẹ̀ tó kàn....
- Queen Elizabeth: Àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin ṣe àwàdà tó pa àwọn èèyàn lẹ́rìín rèé
- Àwòrán àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ṣe àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́rán
Awọn olupẹjọ naa tun sọ pe Buhari n tẹ ẹtọ awọn akẹkọọ naa loju mọlẹ bo ṣe kọti ikun si ariwo awọn olukọ, ASUU.
Awọn mii ti wọn tun pe lẹjọ naa ni minisita fun ọrọ iṣẹ, Chris Ngige, to fi mọ adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami.
Ipẹjọ yii lo n waye lẹyin ti ijọba apapọ kọ lati mu adehun to ṣe fun ASUU ṣẹ.
Kini Ijoba Naijiria ba bo nile ẹjọ́ ti àwọn kọkọ pe ASUU?
Ile ẹjọ sun ẹjọ ti ijọba apapọ pe tako ASUU siwaju
Ẹwẹ, adajọ Polycarp Hamman ti ile ẹjọ Industrial Court niluu Abuja ti sun ẹjọ kan ti ijọba apapọ pe tako ASUU siwaju.

Oríṣun àwòrán, Ministry of Labour
Minisita fun ọrọ iṣẹ, Chris Ngige, lo pe ẹjọ naa tako ASUU.
Awọn mii ti Ngige tun pe lẹjọ ọhun ni minisita fun eto ẹkọ, Adamu Adamu, Aarẹ ASUU, Emmanuel Osodeke.
Ni kete ti wọn pe ẹjọ naa niwaju adajọ ni agbẹjọro, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Ebunolu Adegoruwa, SAN, sọ pe ASUU naa ti pe irufẹ kan naa tako ijọba apapọ.
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Polycarp Hamman wa sun ẹjọ na si ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 yii fun itẹsiwaju rẹ.
Ìdí rèé tí a fí gbé ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU lọ sílé ẹjọ́ lórí ìyanṣẹ́lódì- Ìjọba Nàìjíríà
Ijọba apapọ Naijiria ti wọ ẹgbẹ olukọ fasiti Naijiria lọ sile ẹjọ lori iyanṣẹlodi oloṣu meje ti wọn gunle.
Ile ẹjọ ti wọn lọ ni eleyi to n gbẹjọ lori ọrọ iṣẹ ti a mọ si Labour Court.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n risi ọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ ni Naijiria Olajide Oshuntokun gbe jade la ti ri ọrọ yi.
O ni ijọba gbe igbesẹ yi lẹyin ti wọn ri wi pe gbogbo idunadura laarin awọn ati awọn olukọ Fasiti fori ṣanpọn.
Ohun ti ijọba lawọn fẹ ni ki ile ẹjọ paṣẹ kawọn olukọ pada sẹnu iṣẹ lasiko ti ẹjọ yi yoo ṣi maa waye.
Lọjọ Aje ni ireti wa pe ile ẹjọ yoo bẹrẹ igbẹjọ lori ọrọ naa.
Bakan naa ni ijọba sọ pe awọn fẹ ki ileẹjọ kede boya iyanṣẹlodi ASUU lodi sofin tabi o ba ofin mu.
- Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?
- Ni ilẹ̀ Adúláwọ̀, Wo ǹkan míì tí àwọn eèyàn ń sọ̀ nípa ìgbé ayé Obabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Wo ìkéde tí olú iléeṣẹ́ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì gbé síta nípa kíkẹ́dùn ikú Ọbabìrin Elizabeth II ní Nàìjíríà
- Camilla di Olorì tuntun
- Wó bí gbogbo ètò ìsìnkú náà yóò ṣe lọ ní Ọjọ́ Aje, Ọjọ́ Iṣẹ́gun, Ọjọ́ru àti Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀...
- Irú Ọba wo ní Charles yóò jẹ́?
Bẹẹ naa ni wọn lawọn fẹ alaye ẹkunrẹrẹ nipa ẹsẹ ofin iṣẹ ni paapaa eleyi to mu ki ASUU gunle iyanṣẹlodi lasiko ti idunadura ṣi n lọ lọwọ.
Lọsẹ to kọja ni Minisita feto Ẹkọ, Mallam Adamu Adamu ke gbajare pe awọn ti ṣe iwọn ti ipa ka lori fifopin si iyanṣẹlodi ASUU.
Loṣu Keji ọdun 2022 ni ASUU gunle iyanṣẹlodi lori pe ijọba labẹ Aarẹ Buhari kọ lati ṣamulo adehun ti wọn buwọlu latẹhinwa.
Adehun yi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ jẹ ọna kan gboogi lati mu idagbasoke ba eto ẹkọ giga ni Naijiria.















