Prince William: Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oba Charles ni ọpọ mọ si Ọmọọba ilẹ Wales tẹlẹ - oye ti awọn Ori Ade ile Gẹẹsi ma a fi awọn arole wọn jẹ lati ọdun 1301.
Ọbabinrin kede Charles gẹgẹ bi Ọmọọba ile Wales lati igba to ti wa ni ọmọ ọdun mẹsan
Ni bayii, lẹyin ọdun mejilelọgọta, oye naa wa ti lọ si ọdọ ọmọ rẹ, Ọmọọba William

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ ri ipo oye Ọmọọba tuntun ile Wales gẹgẹ bi ipo to tobi.
Gẹgẹ bi Baba rẹ, ireti wa pe yoo tẹsiwaju lori awọn isẹ idagbasoke ati ifuni to ba ilana ile Wales lọ
Ibaṣepọ rẹ pẹlu orilẹede naa yoo ṣe iranwọ, nibi to sisẹ pẹlu awọn ọmọ ologun ofurufu ni Anglesey ati bi onigbọwọ ajọ ere idaraya Rugby lọrilẹede naa








