Queen Elizabeth II: Wo ìkéde tí olú iléeṣẹ́ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì gbé síta nípa kíkẹ́dùn ikú Ọbabìrin Elizabeth II ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, RoyalFamily
Olu ileeṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi to wa ni Naijiria ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo lanfaani lati wa buwọlu iwe ikẹdun iku Ọbabinrin Elizabeth
Loju opo wọn ni Twitter ni ikede yi wa ti wọn si sọ pe iwe ikẹdun yi yoo wa ni ṣiṣi bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje titi di ọjọ Ẹti ni Abuja.
Laarin ago mọkanla si aago mẹta ọsan ojojumọ lanfaani yoo wa lati buwọlu iwe yi fawọn to ba fẹ kọ ọrọ ikẹdun iku Ọbabinrin Elizabeth.
Yatọ si iwe ojukoroju to wa ni Abuja yi, oju opo idile ọlọba ilẹ Gẹẹsi,@RoyalFamily,naa sọ pe awọn ti ṣi iwe ikẹdun yii soju opo ayelujara.
Bẹẹ naa ni olu ileeṣẹ ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria ti kọkọ kede pe awọn yoo so asia ileeṣẹ wọn soke lati fi ṣe ami ikede ibọsipo Ọba tuntun King Charles III.
Amọ, asia yi yoo walẹ si aarin pada laago mẹjọ owurọ lọjọ keji ti wọn ba sinku Ọbabinrin Elizabeth tan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Saaju asiko yi ijọba Naijiria naa ti gbe ikede jade nipa iku Ọbabinrin ati idaro lorileede naa.

Oríṣun àwòrán, BBC
Ìjọba Nàìjíríà bu ọlá fún Ọbabìnrin Elizabeth II, wọ́n yóò sọ àsía sílẹ̀ dé ìdajì
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria labẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti ba ilẹ̀ Geesi ati gbogbo agbaye kedun iku Obabinrin keji.Àwọn ààrẹ Áfíríkà kí Ọbabìnrin Elizabeth pé ó dìgbóṣe
Aare Buhari ti kede pe ki wọn sọ asia kaakiri lorilẹede Naijiria ati gbogbo awọn ileeṣẹ Ijọba to wa ni ilẹ okeere silẹ de idaji ni Ọjọ Aiku ati Ọjọ Aje lati bu ọla fun Ọbabinrin Elizabeth keji to papoda ni Ojobo ọsẹ to kọja.
Ninu ọrọ ti ileeṣẹ Ijọba to n risi ọrọ ilẹ okeere ni orilẹede Naijiria gbe jade, wọn sapejuwe Ọbabinrin Elizabeth gẹgẹ bi ẹni to ṣe isẹ takuntakun nigba to tukọ gẹgẹ bi Olori ilẹ Geesi ati ti ajọ isokan Commonwealth, eyi to mu ki alaafia jọba laarin awọn orilẹede agbaye.
Ninu ọrọ ibanikedun rẹ̀, Ijọba Naijiria so pe Ilẹ Gẹẹsi ati Naijiria gbadun ibasepo to dan mọran labe Ijọba Obabinrin.
Naijiria jẹ orileede to tobi ju lara awọn orilẹede to wa labe iṣakoso ilẹ Gẹ̀ẹ́sì ni Afrika titi to fi gba ominira lọdun 1960.














