Àwọn ààrẹ Áfíríkà kí Ọbabìnrin Elizabeth pé ó dìgbóṣe

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ọpọlọpọ ikini ati ibanikẹdun lo ti n waye lati igba ti Burkingham Palace ti kede pe Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi ti waja.
Lara ọrọ iwuri ti wọn sọ nipe Ọba to waja naa jẹ aklinkanju obinrin, to si ni ọyaya ati aanu loju rẹ.
Aarẹ Ilẹ Faranse, Emmanuel Macron to saaju awọn to bu ọla fun un ni ọrẹ awọn ni Ọbabinrin naa jẹ nigba aye rẹ.

Aarẹ Amẹrika mẹrinla ni Ọbabinrin Elizabeth ba lọwọ ki ọlọjọ to de

Aarẹ ile Amẹrika tẹlẹ, Barack Obama ni Ọbabinrin naa ṣọwọn loju gbogbo agbaye nitori o lo ọgbọn, imọ ati oye ni gbogbo ọjọ aye rẹ.
Bakan naa ni aarẹ lọwọlọwọ, Joe Biden sapejuwe Elizabeth gẹgẹ bi obinrin to lamilaaka nigba aye rẹ.
Awọn aarẹ nilẹ Afrika naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣedaro Ọbabinrin to papoda naa.

Naijiria
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni oun fi gba iroyin iku Ọbabinrin Elizabeth naa, ti awọn si ba gbogbo ọmọ Ilẹ Gẹẹsi kẹdun ọba wọn to waja.
Buhari ni itan Naijiria ko le pe lai si ipa ribiribi ti Ọbabinrin naa ko ninu irinajo Naijiria ati irinajo lati goke agba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ivory Coast
Aarẹ orilẹede Ivor Coast, Allassane Ouattara naa ti fi ibanikẹdun rẹ ranṣẹ to si gboriyin fun iṣẹ ribiribi ti Ọbabinrin naa ṣe nigba aye rẹ.
O ba Ọba tuntun Charles Kẹta kẹdun, to fi mọ awọn mọlẹbi ọba ati awọn ara ilẹ Gẹẹsi.
Senegal
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Senegal to tun jẹ adari ajọ African Union, Macky Sall ni iroyin ibanujẹ to ba oun lojiji ni iku Ọbabinrin Elizabeth jẹ fun oun.
O gboriyin fun ba to waja naa fun ipa rẹ nilẹ Afrika ti ko ni akawe.
Liberia
Aarẹ orilẹede Liberia tẹlẹri ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni oun fi darapọ mọ awọn orilẹede lagbaye lati ṣe idaro akọni to jade laye.
O fi aworan igba to ṣepade pẹlu Ọbabinrin naa ni ọdun 2006, to si ni iwuri lo jẹ fun oun lati ṣabẹwo si ọba naa nigba aye rẹ.
Sierra Leone
Aarẹ Sierra Leone, Juio Bio naa fi sori Twitter nipa ibanikẹdun rẹ pẹlu awọn ara Ilẹ Gẹẹsi lọwọlọwọ lori ipapoda Ọbabinrin wọn.
O ni igba Ọbabinrin naa san gbogbo eniyan nitori igbaga wa lasiko tirẹ paapaa aduroti rẹ ni Ajọ Commonwealth ti ko ni onka.
Ghana
Aarẹ orilẹede Ghana, Akufo Addo naa fi si ori ẹrọ Twitter rẹ lati bamikẹdun ati lati sọ iriri rẹ pẹlu ọba to doloogbe naa.
O ni ẹẹmeji ti Ọbabinrin wa si ilẹ Ghana lo nipa ninu aye wọn nibẹ.
Awọn miran ti wọn tun fi ibanikẹdun ranṣe ni aarẹ Kenya, South Afrika ati bẹẹ lọ












