₦9.3bn ni Tinubu yà sọ́tọ̀ fún Iléeṣẹ́ Ààrẹ, oúnjẹ ati ìrìnàjò ní 2026

Aarẹ Tinubu nile igbimọ aṣofin l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima yoo na apapọ owo to le ni bilọnu mẹsan an naira lori irinajo abẹle ati oke okun, ounjẹ ati awọn nnkan mii ninu ọdun 2026.

Eyi jẹyọ ninu iwe eto isuna ọdun 2026 ti ajọ to n risi eto isuna ti orilẹede Naijiria fi lede.

Tinubu ni ọjọ kọkandinlogun ọdun 2025 gbe eto isuna lọ siwaju ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria, ti apapọ owo naa si jẹ N58.18tn.

Nibẹ ni Tinubu ti ni ọrọ eto aabo jẹ ohun ti yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje, idokowo ati alaafia.

Sugbọn ninu iwe ti a ri, N3.2tn ni ileeṣẹ aarẹ ya sọtọ fun eto aabo, ti wọn si ya 2.3tn fun eto ẹkọ, 1.1tn fun ina ati ohu amuṣagbara agbara.

Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu eto isuna naa, Tinubu yoo na N7,014,596,511 lori irinajo abẹle ati oke okun, pẹlu N431,620,183 lori ounjẹ jijẹ, alaṣe ati awọn nnkan ẹlẹrin dodo.

Shettima yoo naa owo toto N1,732,106,437 lorin irinajo abẹle ati oke okun ati N186,026,286 lori ounjẹ

Bakan naa ni ileeṣẹ Aarẹ yoo naa owo toto N65.77m lori ijoko ile ati N895m fun rira iwe fun kika ati awọn irinsẹ.

Aarẹ yoo tun ra ọkọ bọgini ti owo rẹ to N179m, ti N778.6m si wa nilẹ fun rira aga ijoko, pẹlu N1.342m fun rira awon irinsẹ eto ilera.

Ṣaaju ni Aarẹ Tinubu ni eto iṣuna ifarada, aṣeyọri iṣẹ ati ilọrọ ni eto isuna ọhun.

O ni ijọba fẹ pese iṣẹ, ṣe atunṣe ọrọ aje ko le fẹsẹ mulẹ daadaa ati pe ijọba oun tun fẹ mu aye rọrun fawọn ọmo Naijiria lọdun 2026 lẹyin ti wọn ti ni ifarada fun ọdun meji bayii.

Iwọnyii ni alakalẹ owo ti Aarẹ ya sọtọ fun awọn ileeṣẹ lọdun 2026

  • Ileeṣẹ Aarẹ → ₦355,100,320,721
  • Ile igibimọ aṣofin agba → ₦344,852,880,669
  • Ileeṣẹ eto aabo → ₦3,154,393,400,291
  • Ileeṣe ọrọ ilẹ okeere → ₦344,235,906,716
  • ileeṣẹ to n ri si ọrọ iroyin → ₦98,163,122,322
  • Ileeṣẹ ọrọ abẹle → ₦696,416,792,599
  • Ọọfisi olori oṣiṣẹ ni Naijiria → ₦26,942,251,897
  • Oluṣiro agba fun Naijiria → ₦15,881,134,488
  • Ileeṣẹ ti araalu le lọ ti maa fi ọrọ sun → ₦29,460,000,000
  • ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ → ₦2,604,702,873
  • Ajọ INEC → ₦1,013,778,401,602
  • Ajọ to n ri si iwa abinibi → ₦6,531,190,463
  • ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa → ₦1,329,461,895,087
  • Ileeṣẹ eto ibaraẹnisọrọ ati ọrọ ayelujara → ₦84,560,421,789
  • Olubadamọran pataki fun eto aabo → ₦664,119,740,541
  • Ajọ to n ri iwa rere→ ₦2,370,626,414
  • Ajọ to n ri si ọrọ ile kikọ ₦2,780,925,426
  • Ajọ to n ri si ọrọ ọlọpaa → ₦2,397,074,830
  • Akọwe agba fun ijọba apapọ → ₦293,021,567,646
  • ileeṣẹ to n ri si akanse iṣẹ → ₦13,781,104,156
  • Ileeṣẹ eto ọgbin→ ₦1,447,973,604,421
  • Ileeṣẹ eto iṣuna → ₦16,781,272,498,002
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ → ₦87,436,249,085
  • Ileeṣẹ to n ri si eto igbanisṣẹ ₦183,572,952,990
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ imọ sayẹnsi → ₦838,674,080,349
  • Ileeṣẹ eto irinna → ₦431,798,285,025
  • Ileeṣẹ to n ri si irinajo ọkọ ofurufu→ ₦88,209,964,483
  • Ileeṣẹ to n ri si ina mọnamọna→ ₦1,107,103,148,958
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi → ₦71,597,986,053
  • Ileeṣẹ to n ri si idagbasoke irin → ₦21,520,279,269
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ ṣiṣẹ → ₦3,485,652,384,621
  • Ileeṣẹ to n ri si eto iṣuna → ₦9,102,998,474,710
  • Ajọ to n ri si ọrọ owo oṣu → ₦4,683,161,168
  • Ajọ to n ri si bi ijọba ṣe n pa owo wọle → ₦4,710,115,027
  • Ajọ to n ri si ibi ti ijọba ba iṣẹ de → ₦1,991,672,502
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ omi → ₦458,648,182,716
  • Ileeṣẹ to n ri si ile kikọ ati idagbasoke awujọ → ₦105,926,305,272
  • Ileeṣẹ to n ri si alumọni inu omi ₦149,181,952,655
  • Ileeṣẹ to n ri si irinajo afẹ → ₦10,417,248,347
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ sinima ati idaraya→ ₦59,882,227,219
  • Ileeṣẹ to n ri si alumọni inu ilẹ → ₦156,335,330,765
  • Ileeṣẹ to n ri si ohun ọsin→ ₦81,186,171,499
  • Ẹka eto idajọ → ₦341,625,739,236
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ idajọ → ₦150,554,556,545
  • Ajọ ICPC → ₦21,120,395,993
  • Ajọ Code of Conduct Bureau → ₦15,748,365,861
  • Olu Ilu Naijiria, FCT → ₦460,737,525,183
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ Niger Delta → ₦1,350,964,245,478
  • Ajọ to n ri si ọrọ ere idaraya → ₦206,433,718,652
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin → ₦154,315,760,358
  • Ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ → ₦2,399,161,320,016
  • Ileeṣẹ to n ri si eto ilera → ₦2,149,385,867,131
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika → ₦164,144,903,358
  • Ajọ to n ri si eto ikaniyan → ₦31,359,208,037
  • Ileeṣẹ to n ri si ọrọ adojutoṣi → ₦462,663,187,207
  • Ileeṣẹ to n ri si idagbasoke awọn ọdọ → ₦518,362,661,771