Lẹ́yìn ọdún márùndínlọ́gbọ̀n, ọmọ tí wọ́n bí sórí igi lásìkò ẹ̀kun omi jáde láyé

Carolina Cecilia Chirindza ati Rosita nilẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ kan ti wọn bi sori igi lasiko ti iya rẹ n sa fun ẹkun omi ni Mozambique ti jade laye lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.

Lẹyin ọdun 2000 ni fidio bi ọkọ ofurufu ẹlikọpita kan ṣe doola iya rẹ lori igi jade ti ọpọ si kaanu iya ati ọmọ naa lọdun naa lọhun.

Aarẹ orilẹede naa, Daniel Chapo juwe ọmọ ọhun bii apẹẹrẹ rere fun awọn obinrin nilẹ naa.

Ninu oṣu Keji ọdun 2000 ni ọpọ eeyan jade laye, ti ẹgbẹgbẹrun mii si di alanilelori latari ẹkun omi to waye lẹyin ti odo Limpopo ya.

Carolina Cecilia Chirindza, to jẹ iya ọmọ naa, Rosita, wa lara awọn ti iṣẹlẹ naa pa lara julọ.

Nigba to n ba awọn adoola ẹmi Red Cross, obinrin naa ni "aago mẹrin irọle ni ẹkun omi naa bẹrẹ si n pọ si.

"Bi omi ọhun ṣe n ṣan wa si ile wa lo n pọ si, a si ṣe bii awọn eeyan to ku ṣe ṣe, gbogbo wa gun ori igi lọ.

"Mo gbe awọn ọmọ mi mejeji ṣeyin mi, mo si gbiyanju lati gun igi naa amọ o ṣoro.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Apapọ gbogbo wa jẹ marundinlogun, odidi ọjọ mẹrin gbako ni a si lo lori igi ọhun, a gbadura fun ọpọ wakati nibẹ pe ki iranlọwọ dide.

"A ko ni ohun ti a o jẹ nibẹ, awọn ọmọ bẹrẹ si wa ẹkun mu, amọ ko si iranlọwọ kankan ti a le ṣe fun wọn."

Nigba ti yoo di aarọ Ọjọru ni ọmọ bẹrẹ si n mu Carolina, laipẹ rẹ ni ẹlikopita ijọba South Africa kan n ṣiṣẹ idoola ẹmi ri wọn nibi ti wọn wa lori igi.

Ileeṣẹ iroyin Guardian jabọ pe bi obinrin naa ṣe n bimọ ni iya ọkọ rẹ n di ọmọ naa mu labẹ rẹ ki ọmọ tuntun ọhun ma baa jabọ sinu omi.

Carolina ni "Mo gbagbọ pe ọmọ mi yatọ ninu gbogbo ọmọ latari pe ori igi ni mo bi si ti ko si padanu ẹmi rẹ lasiko naa."

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni iya ati ọmọ naa di ami iforiti ati agbara ki wọn to lọ silẹ Amẹrika nibi ti wọn ti lanfani lati ba awọn aṣofin ilẹ naa sọrọ.

Wayi o, ọmọ naa ti dagbere faye lẹni ọdun marundinlọgbọn lẹyin aisan ọjọ pipẹ.

Ọkan lara awọn mọlẹbi wọn sọ fun awọn akọroyin pe oloogbe naa n ba aisan inu ẹje 'anaemia ' finra ṣaaju iku rẹ.

Iya Rosita tun sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe o tun ba aisan ikọ efee finra ki ọlọjọ to de.

Ẹwẹ, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n ba ẹbi Rosita kẹdun iku rẹ bayii.

Ninu awọn olukẹdun naa sọ pe eto ilera ti kọ ṣe dede lorilẹede Mozambique wa lara nnkan to tete jẹ ko padanu ẹmi rẹ.