Ìdí rèé tí ìjákulẹ̀ ṣé deba olùdìbò 1.126m nínú àwọn tí INEC gbà orúkọ wọn sílẹ nínú ètò iforukọsilẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé

Oríṣun àwòrán, Inecnigeria
Ajọ eleto idibo lorileede Naijiria ti kede pe awọn ti gbọn orukọ oludibo to le ni miliọnu kan yọ kuro ninu awọn to kopa ninu eto iforukọsilẹ to waye laipẹ.
INEC ni awọn ti ọrọ yi kan lawọn to fi orukọ silẹ laarin ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa 2021 si ọjọ Kẹrinla oṣu Kini ọdun 2022.
Amọ ṣa INEC sọ pe gbigba kaadi idibo fawọn araalu to kopa ninu iforukọsilẹ yoo bẹrẹ ni ipari oṣu Kwa titi de ibẹrẹ oṣu Kọkanla.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣana feto iroyin ati idanilẹkọ oludibo Festus Okoye fi sita la ti ri ọrọ yi.
O ni awọn lo ẹrọ Automated Biometric Identification System (ABIS) feto yi lẹyin tawọn fopin si eto iforukọsilẹ ni ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Keje.
Ẹrọ yi gege bo ṣe ṣalaye lo mu ki wọn ri wi pe orukọ awọn oludibo 1,126,359 ni iroyin wọn ko pe perepere ninu 2,523,458 lapapọ.
- Àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ẹ̀rọ BVAS tí INEC yóò lò fún ìdìbò gómìnà Ekiti
- INEC kéde ọjọ́ tí ìdìbò sípò Ààrẹ ọdún 2023 yóò wáyé
- Àpapọ ilé aṣòfin Nàìjíríà buwọ́lù fífi èsì ìdìbò hàn lórí ayélujára
- Wo ìdí tí àjọ INEC fi yọ orúkọ gómìnà báńkì àpapọ̀ tẹ́lẹ̀, Chukwuma Soludo kúrò nínú àwọn olùdíje gómìnà Anambra
Bẹẹ lo ni awọn ko ni pẹ pari eto ABIS tawọn ṣe laarin ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kini titi di ọjọ karundinlọgbọn oṣu Keje 2022.
Pupọ ninu awọn ti INEC sọ pe wọn ja lulẹ ninu oludibo lo forukọsilẹ lẹẹmeeji tawọn mii ti aṣiri awọn mii ti ko lẹtọ lati forukọsilẹ naa si tu sawọn lọwọ.
Awọn ti wọn kuna yi ni INEC sọ pe awọn ti yọ orukọ wọn kuro to si tunmọ si pe wọn ko ni lanfaani lati dibo
Eto ayẹwo pẹlu ẹrọ ABIS ṣi n tẹsiwaju
Ninu alaye ti INEC ṣe yi, orukọ awọn to forukọsilẹ laarin 28th June 2021 si 14th January 2022 nikan ni iye ti wọn lawọn ti ri bayiii.
Bi wọn ba pari ayẹwo orukọ awọn to kopa ninu iforukọsilẹ laarin 15th January si 31st July 2022 o ṣeeṣe ki wọn tun ri awọn miran ti wọn yoo ja lulẹ ninu oludibo.
- SERAP àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì márùn ún pe ìjọba Nàìjíríà lẹ́jọ́ lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò rìrìnàjò ìkẹyìn pẹ̀lú ọkọ̀ òfururfú
- Ni ilẹ̀ Adúláwọ̀, Wo ǹkan míì tí àwọn eèyàn ń sọ̀ nípa ìgbé ayé Obabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Wo ìkéde tí olú iléeṣẹ́ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì gbé síta nípa kíkẹ́dùn ikú Ọbabìrin Elizabeth II ní Nàìjíríà
INEC sọ pe awọn n gbiyuanju lati tẹle ilana to munadoko ni ati pe kete tawọn ba pari gbogbo eto lawọn yoo gbe orukọ gbogbo oludibo to ba kajuẹ lati dibo sita.













