Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn káàdì ìdìbò tí wón rì mọ́lẹ̀ – INEC

Oríṣun àwòrán, Others
ileeṣẹ ajọ to n risi eto idibo ni Naijiria (INEC) ti ṣeleri pe awọn yoo tu isu de isalẹ ikoko lori awọn kaadi idibo(PVC) ti wọn ri mọlẹ ni awọn agbegbe kan koda ati ile eeyan pataki kan.
Ninu atẹsita ti Alaga fun ileeṣẹ naa, Festus Okoye, fi sita fun awọn akoroyin, ni iroyin naa ti de ọdọ ẹka ileeṣẹ naa to n risi iroyin ati ẹkọ awọn oludibo, ti wọn si ti wo fidio naa bi awọn kan ṣe ri awọn kaadi idibo mọlẹ ni awọn agbegbe kan.
Okoye ni awọn o ni fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa rara.
“iwadi ti bẹrẹ ni kiakia lori iṣẹlẹ naa, ti ẹni ti o lọwọ ninu iwa ibajẹ naa yoo rija ofin.”
“Gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria ti o fi oruko silẹ lo lẹtọ si kaadi idibo, ti ko si ba ofin mu lati dena wọn lati idibo.”
INEC ti wa rọ awọn ọmọ orilẹde Naijiria lati ma foya nitori pe gbogbo awọn kaadi idibo naa ni awọn tẹ sita lati ọjọ kẹrinla oṣu akọkọ lọdun 2022, ti awọn si ti fi ransẹ si gbogbo ipinlẹ lorilẹede lati fun awọn oludibo.
“A ko ni jẹ ki awọn koloransi kan ba iṣe wa jẹ. O ni ọrọ lori kaadi idibo lo jẹ ohun lọkan ti ajọ si n ṣe iṣe lori bi iforukosilẹ yoo ṣe lọ laisi wahala.”
“A n fi da awọn ọmọ Najiria lọju pe iwadi wa yoo fi oju awọn oniwa ibajẹ na han.
“Lọwọlọwọ bayi, Ajọ INEC ti n ṣe atunse lori bi gbigba kaadi idibo yoo ṣe maa waye lai si wahala ti a si ti ṣe ipade lori bi eyi yoo ṣe ṣẹlẹ.”
Atẹsita INEC ọhun wa gba awọn ọmọ Najiria ni iyanju pe ti wọn ba ri awọn to ri kaadi idibo mọlẹ naa, ki wọn mu wọn lọ ileeṣẹ Ajọ INEC to ba wa ni tosi wọn” .















