Wo bí àwọn ọ̀dọ́ Akure ṣe tú jáde polongo fún aráàlú láti gba káàdì ìdìbò PVC wọn

Awọn ọdọ ilu Akure ni wọn ti ṣe iwọde itaniji kaakiri ilu naa to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lati rọ awọn ara ilu ki wọn forukọ silẹ ki wọn si gba kaadi idibo alalopẹ wọn. Iwọde itaniji ọun ti wọn ṣe pẹlu ajọṣepọ ajọ eleto idibo ilẹ yi, INEC, lo bẹrẹ lati agbegbe Arakalẹ gba Ọba Adeṣida, Hospital Road, ti wọn si pari ẹ si NEPA roundabout nibi ti gbogbo awọn adẹrinpoṣonu ati gbajugbaja olorin nilu naa ti dawọn lara ya. Bakana naa ni iforukọsilẹ fun awọn oludibo lori ẹrọ ayelujara n lọ lẹgbẹ kan naa latọwọ ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba ti a mọ si leyi ti wọn ni wọn yoo ko awọn to forukọsilẹ naa lọ si ile iṣẹ ajọ INEC lẹyin eto naa.

Ajọ INEC ni oṣiṣẹ wọn kan ti ko ni iyanda lati sọrọ lorukọ ajọ naa wipe eto idibo ipinlẹ Ọṣun ni ko jẹ ki wọn le darapọ mọ eto naa bo ṣe yẹ. Ẹwẹ, lara awọn ọdọ to ṣe agbatẹru eto ọun bii Ayọ Ajiṣafẹ to jẹ alaga awọn oṣere ni ipinlẹ Ondo labẹ asia Actors Guild of Nigeria, Femi Fashipe to jẹ aṣoju awọn ọdọ ni igbimọ #EndSars ti ijọba gbe kalẹ ati Opeyemi Idiowo to ko gbogbo wọn sọdi ni wọn wipe bi awọn ọdọ ko ṣe bikita nipa iforukọsilẹ naa lo mu ki wọn ni ajọṣepọ pẹlu ajọ INEC lati ṣe iwọde yi, ati pe o le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun kaadi idibo alalopẹ to ṣi wa lọfiisi ajọ INEC ti wọn ko tii gba. Festus Akinsola to jẹ alakoso ajọ naa nipinlẹ Ondo lo ni awọn yoo pese ọkọ ọfẹ lati maa ko awọn eniyan lọ ofiisi ajọ INEC lati forukọsilẹ.

Awọn araalu to wa lara awọn waa forukọsilẹ nibi eto naa, Adewumi Fawọle, Tolu Ogedengbe, Titilayọ Oluwọle ati Nnenna Ṣotọnwa ni wọn dupẹ lọwọ awọn ọdọ ọun fun anfani lati le forukọsilẹ fun kaadi alalopẹ. Idanilẹkọ lori iforukọsilẹ, gbigba kaadi tuntun rọpo awọn to ti bajẹ abi sọnu ati ọna ti wọn fi le paarọ oriko idibo ni o waye nibi iwọde ọun.










