‘’Tí mo bá di ààrẹ! Oró ejò, Marijuana, kórópọ̀n Hyena ni màá fí pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́’’

Oríṣun àwòrán, George Wajackoyah
Oludije legbe oṣelu Roots Party, George Wajackoyah ti dagboru lorilẹede Kenya pẹlu ipinnu lati yi ilẹ ọhun pada ti oun ba di aarẹ.
Wajackoyah, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ti wọn bi lorilẹede Kenya to jẹ atapatadide lo lọ si Ilẹ Gẹẹsi, to si ṣiṣẹ awọn to ma n wa koto ki o to di ọjọgbọn.
Ọpọlọpọ eniyan lo n sọr nipa ipinnu rẹ ati awọn ohun to ni oun yoo ṣe fun awọn ara orilẹede Kenya.
Ninu ọrọ rẹ lo ti ni awọn ọna gboogi ti oun yoo lọ lati yi ọrọ aje wọn to dẹnukọlẹ pada ni lati bẹrẹ si ni ṣe ipese igbo , marijuana ti orilẹede Kenya yoo ma ṣe iṣẹ ọgbin rẹ.
Ti wọn yoo si maa kọ lọ si oke okun fun awọn eniyan lati lọ fun igbayegbadun ati fun eto iwosan.
Ọjọgbọn Wakackoyah naa ni o kẹkọ imọ ofin, to si jẹ ọkan lara awọn oludije mẹrin ti wọn dije du ipo aarẹ ti yoo waye ni Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Awọn onimọ niap afojusun bi idibo naa yoo ṣe lọ ti sọ wi pe oun ni o wa ni ipo kẹta pẹlu idamẹrin esi idibo naa.
Amọ wọn ni awọn ọdọ gba ti rẹ nitori awọn oun to ṣetan lati pese fun wọn ju awọn oludije bi igbakeji aarẹ Kenya,Willian Ruto ati ọkan gboogi ninu awọn alatako ijọba, Raila Odfinga.
Ki lo yatọ nipa Oludije to fe ma a ta Marijuana?
Awọn ololufẹ George Wajackoyah to n dije dupọ naa ni wọn fẹran rẹ nitori o ma n ṣe ọwọ bi ẹni pe oun fa igbo lasiko to ba n ba awọn eniyan sọrọ.
Bakan naa ni o si tun fẹran orin takasufẹ Reggae ti o si ma n jo si lasiko iwọde rẹ̀.
Ọjọgbọn George Wajackoyah ni ti wọn ba dibo yan oun gẹgẹ bi aarẹ, triliọnu mẹsan ana ni oun yoo ma a pa wọle ni abẹle nipa iṣẹ agbẹ paapaa wiwa oko Marijuana, ti ijọba ko si ni tọrọ owo mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa lo ni awọn yoo ma a pese oro ejo ni abẹlẹ alti lati gbe lọ si oke okun fun tita.
O sapejuwe oro ejo naa gẹgẹ bi oun to ṣọwọn ju wura lọ, ti wọn yoo maa lo fuin ipese eto iwosan ati ounjẹ lọ si China nibi ti wọn ti fẹran ẹran ejo jijẹ.
George Wajackoyah fikun un pe oun yoo tun ma a ko koropọn ẹran Hyena lọ si China nibi ti wọn yoo ti ma a lo fun eto ilera awọn eniyan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ ajọ to n risi ọrọ ẹranko ni orilẹede Kenya ti bu ẹnu atẹ lu ipinnu rẹ yii ti wọn si ni ko le kẹṣẹ jari.
Bakan naa ni Ile Ijọsin Aguda nibẹ naa ti ni tita oogun oloro Marijuana yoo mu ti iidile tunbọ bajẹ si ju titẹle lọ.












