Ọmọ ọ̀dọ̀ ni wọ́n gbé mi lọ ṣe ní London, wọ́n yí orúkọ mi padà, mo dí olókìkí kí ń tó lè lẹ́nu ọ̀rọ̀ - Mo Farah

Mo Farah

Ko to di gbajugbaja tẹẹ mọ lonii, hummmmn.. ikun imu ti bọ si tosi ti ko si lee pariwo titi to fi dagba.

Gbajúgbajà eléré ìdárayá Sir Mo Farah ti tú àṣírí bí ó ṣe wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom ní kékeré.

Farah ní ọ̀nà àìtọ́ ni wọ́n gbà gbé òun wọ UK láti ṣe ọmọ ọ̀dọ̀.

Ó ní àwọn tó gbé òun wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom ló sọ òun ni Mohammed Farah àti pé Hussein Abdi Kahin gan-an ni orúkọ tí ìyá àti bàbá sọ òun.

Ó ní obìnrin kan ló mú òun kúrò ní orílẹ̀ èdè Somalia tó jẹ́ orílẹ̀ èdè bàbá òun nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án láti wá máa ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ kan ní orílẹ̀ èdè UK.

Àwòrán Mo Farah

Oríṣun àwòrán, others

Farah ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tí òun máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni wí pé òun àti àwọn òbí òun ṣe àtìpó wọ UK tẹ̀lé ni, ó ní òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí òun kò fi ìgbà kankan dé United Kingdom rí.

Ó ṣàlàyé fún BBC pé oko àwọn ní òun àti àwọn ẹbí òun ń gbé kí òun tó di èrò UK.

Ó ní ọmọ ọdún mẹ́rin ni òun wà tí bàbá òun fi jáde láyé lẹ́yìn tí ìbọn bà á nínú ogun abẹ́lé tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Somalia ní ọdún náà lọ́hùn-ún.

Ó fi kun pé bí ọmọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́sàn-án ni òun wà tí wọ́n fi wá mú òun kúrò ní ilé àwọn láti lọ máa gbé ọ̀dọ̀ mọ̀lẹ́bí kan ní Djibouti.

"Obìnrin kan tí mi ò mọ̀ rí ló mú mi wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom".

"Inú mi dùn gidi nígbà náà nítorí mi ò wọ ọkọ̀ òfurufú rí"

"Obìnrin náà ló ní kí n sọ pé Mohammed ni orúkọ mi, ìwé ìrìnnà kan sì wà lọ́wọ́ rẹ̀ èyí tó ṣàfihàn àwòrán mi pẹ̀lú orúkọ Mohammed Farah"

Farah tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn dé UK, obìnrin náà mú òun lọ sí ilé rẹ̀ ní Hounslow, ẹkùn ìwọ̀ oòrùn London tó sì gba ìwé ìrìnnà ọwọ́ òun.

"Níwájú mi ló fa gbogbo ìwé náà ya tó sì dà á sí ilé-ilẹ̀, ìgbà yẹn gan ni mo mọ̀ wí pé mo ti wọ gàù"

Ó ní láti ìgbà náà ni òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ tí obìnrin náà sì ṣe ìkìlọ̀ fún òun wí pé tí òun bá ṣì fẹ́ rí àwọn ẹbí òun láyé òun ò gbọdọ̀ la ẹnu òun sọ ohunkóhun fún ẹnìkankan.

Ó ṣàlàyé pé òun tó ọmọ ọdún méjìlá kí wọ́n tó fi òun sí ilé ẹ̀kọ́ ní Feltham Community college.

Ó ní òun ti wọ́n sọ ní ilé ẹ̀kọ́ náà ni wí pé òun wá ṣe àtìpó ní UK láti Somalia ni.

Atẹjade Mo Farah

Àwọn olùkọ́ Sir Mo bá BBC sọ̀rọ̀

Àwòrán Mo Farah

Oríṣun àwòrán, others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Mo Farah tó bá BBC sọ̀rọ̀ ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ kìí múra dada àti pé kò le sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ni àwọn kò rí kí àwọn òbí rẹ̀ máa wá fún ẹ̀kọ́ àgbà.

Olùkọ́ Farah tó kọ eré ìdárayá, Alan Watkinson ní òun máa ń rí ìyàtọ̀ lára Farah tó bá ti wọ aṣọ eré ìdárayá.

Watkinson ní ó dàbí wí pé eré ìdárayá nìkan ni èdè tí Farah gbọ́.

Mo Farah ni eré ìdárayá dàbí òun tó mú ìgbé ayé tuntun bá òun, tí òun sì rò ó wí pé tí òun bá fẹ́ bọ́ nínú ìgbé ayé tí òun ń gbé lọ́wọ́ òun ní láti mu ni ọ̀kúnkúndùn

Ó ní èyí ló mú òun jẹ́wọ́ ẹni tí òun jẹ́ gan fún olùkọ́ Watkinson tí òun sì ṣàlàyé iṣẹ́ tí òun ń ṣe fún àwọn mọ̀lẹ́bí náà fun.

Ó fi kun pé Watkinson ló so òun papọ̀ mọ́ àwọn ẹbí mìíràn tí wọ́n wá láti Somalia bí tòun àti pé láti ìgbà náà ni inú ti máa ń dùn.

Láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pa òkìkí nínú eré sísá tí wọ́n sì pè é láti wá díje ni Latvia àmọ́ ìwé ìrìnnà tí kò ní ṣe ìdíwọ́ fún un.

Ó ní lọ́dún 2000 ni Watkinson bá òun gba ìwé ọmọ ìlú British pẹ̀lú orúkọ Mohammed Farah.

Farah ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló kojú irú ìṣòro tí òun ní yìí, eré sísá ló gba òun là.

Iléeṣẹ́ BBC gbìyànjú láti kàn sí obìnrin tí Farah fẹ̀sùn kàn pé òun ló mú òun wọ London àmọ́ ó kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ náà.