Ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo, Hon. Segun Popoola jáde láyé lẹ́ni ọdún 46

Oríṣun àwòrán, others
Amofin to n ṣoju ekun idibo Ila Oorun-Guusu Ibadan ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, Hon Segun Popoola ti jade laye.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, Popoola gbẹmi mi ni lọjọ Isegun ni Ile Iwosan University College Hospital, Ibadan nibi ti o ti n gba itọju lọwọ.
Agbẹnuso fun adari ile igbimo aṣofin ipinlẹ Oyo, Alhaji Oyetunji Oyekunle, ẹni to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ fun BBC News Yoruba pe iṣẹlẹ ọhun waye ni alẹ ana.
Popoola, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, ni alaga ile igbimo aṣofin ipinlẹ Oyo lori ori ijọba ibile ati ọrọ to jẹ mọ fifini jẹ oye.
O wa lara awọn aṣofin to tọwọ bọ iwe lati fi ẹsun kan igbakẹji gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ, Rauf Olaniyan, ti o si wa lara awọn ti o dije fun ipo aṣofin lẹkun idibo Guusu-Iwọ Oorun Ibadan labe asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party.











