Wón ní àwọn ni Lébìrà, Lébìrà ní wón á ṣe ...! - Tinubu sọ òkò ọ̀rọ̀ sì ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu, All Progressive Congress, Bola Ahmed Tinubu ni o ti ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu Labour Party gẹgẹ bi ẹgbẹ oni olu ‘Mushroom’ ti o n ṣe iṣẹ lebira.
Tinubu sọ eyi nigba ti o darapọ mọ iponlongo ibo fun Gomina Adegboyega Oyetola niluu Osogbo ni ipinlẹ Osun.
Oyetola ni o gbinyanju lati wole saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Osun lọjọ satide ọse yi.
“PDP ati ẹgbẹ oṣelu oni Olu. Bii Labour Party, wọn ni awọn ni Lebira, Lebira ni wọn o ṣe ku.”
“Ọlọrun o ni sọ yin di lebira o.”
Tinubu ni o wa nibi ipolongo ibo naa pẹlu aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ahmad Lawan ati ọpọlọpọ awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ti Gomina Babajide Sanwolu si siwaju wọn.
Awọn miiran to wa nibi ipolongo ibo naa ni ipinlẹ Osun ni Abdullahi Ganduje ti ipinlé Kano, Babagana Zulum ti ipinlẹ Borno ati Atiku Bagudu lati ipinlẹ Kebbi.
Alaga fun ẹgbẹ oṣelu naa, Abdullahi Adamu ati igbakeji aarẹ fun Bola Ahmed Tinubu, Kassim Shettima, naa wa nibi ipolongo naa.















