Àwọn ọ̀dọ́ Naijiria ṣe bẹbẹ, ọ̀pọ̀ wọn ń tú yahaya jáde forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò

PVC Registartion

Oríṣun àwòrán, @C2HFoundation

Àwọn ọ̀dọ́ fara ya!

Ó lè ní idà mẹ́rinlèlògòtá nínú Ọgọ́rùn-ún ọdọ tí ó ti forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò bayii.

Awọn ọdọ ninu igbaradi wọn fun eto idibo ọdun 2023, ọpọ wọn ni wọn fara ya, ti wọn si mu iforukọ sile fun kaadi idibo ni okunkundun.

Lẹyin ti ajọ ti o risi eto ìdibo, INEC kede afikun fun iforukọ silẹ fun kaadi idibo, pupọ awọn ti wọn fi orukọ silẹ ni o jẹ awọn ọdọ.

PVC Registartion

Oríṣun àwòrán, @gre8thenry

Eyi lo waye lẹyin ti INEC ni pupọ ninu awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti fi orukọ sile fun kaadi idibo ọdun 2023.

INEC ni merinlelọgọta ninu ida ọgọrun-un ni awọn ọdọ ti wọn fi orukọ silọ bayii.

Ajọ INEC ni kete ti awọn kede afikun naa ni sì ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2022, ni awọn ṣe akọsílẹ awọn ọdọ to le ni milọnu mewaa ti o ti fi orukọ silẹ fun kaadi idibo wọn.

INEC ni o le ni milọnu mẹrin ọdọ ti wọn ṣe iforukọsilẹ lati ori ẹrọ ayelujara ti ọpọ si wa si ọọfisi ajọ naa lati fi orukọ silẹ.