Ta ni Kashim Shettima tí Tinubu gbé gẹ́gẹ́ bí igbákejì?

Aworan Kashim Shettima

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Keje ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu na ọwọ gomina ipinlẹ Borno soke gẹgẹ bi igbakeji rẹ ṣaaju idibo sipo aarẹ ti yoo waye lọdun 2023.

Lati igba ti Tinubu ti kede rẹ ni awọn eniyan ti bẹrẹ si ni sọrọ nigba oludije naa ati iru ẹniyan to jẹ.

Tinubu sọ fun awọn akọroyin pe bio tilẹ jẹpe oun ko jiroro pẹlu Shettima ki oun to gbe igbeṣẹ naa, Oun ni igbagbọ ninu rẹ.

Iroyin gbe e gbe Shettima ko ipa ribiribi lati ri pe Tinubu jawe olubori lori bi Tinubu ṣe laluyọ gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ APC.

Awọn ohun to yẹ ki ẹmọ nipa Kashim Shetima ni yii...

Kashim Ibrahim Shetima jẹ onimọ nipa eto ifowopamọ ati oloṣelu.

Oun ni ṣẹnetọ to n ṣoju gbungun ipinlẹ Borono lọwọlọwọ ni Ile Igbimọ Aṣofin Agba.

Shettima ti di ipo gomina mu lẹẹmeji nipinlẹ Borno lati ọdun 2011 si 2019.

Aworan Shettima ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

O ni iwe eri imọ Bachelor’s ati Master’s Degree lati fasiti Maiduguri ati fasiti Ibadan.

Lẹyin to kawe jade ni o bẹrẹ idokowo ati iṣẹ ni ileeṣẹ ifowopamọsi, to si de ipo adari.

Ni nkan bi ọdun 2000 ni o da adari ileeṣẹ Zenith Bank ni Maiduguri ti o to kọ iwe fi ipo silẹ lati bẹrẹ iṣe ni ijọba gomina Ali Modu Sheriff ni ọdun 2007.

Lẹyin naa lo lo ọdun mẹrin ni ipo gomina ni ọdun 2011, to si dije du ipo aarẹ ni ọdun 2015.

Aworan Shettima ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Lẹyin to pari saa keji ni o lọ si ile igbimọ Aṣofin agba to si jaw olubori ni ọdun 2019.

Ilu Maiduguri ni olu ilu Borno ni wọn ti bi Kashim Shettima.

Iran Alhaji Shettima Mustafa Kattayayibe ni Shettuma ti ṣẹ wa.