Kí ni ìdí ariwo lórí bí Tinubu ṣe yan Musulumi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì Ààrẹ? - CAN dáhùn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko pa ohun wọn da lori titako ki ẹsin kan naa dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ ẹgbẹ CAN, Pasitọ Adebayo Oladeji lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iyansipo gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC.
Oladeji ni ki awọn eniyan ma sọrọ nipa asiko MKO Abiola nitori aye dara nigba naa ju asiko yii lọ.
‘A kò yí èrò wa padà! A ò lọ́wọ́ sí ẹni tí Tinubu yan bíi igbákejì’
‘’Ko si didara ti oludije to ba yan Musulumi gẹgẹ bi igbakeji yoo ṣe fun wa.’’
‘’Ki wọn lọ wọ iwe ofin Naijiria lẹyin ogun abẹlẹ, o yẹ ki wọn ṣe didara si gbogbo ẹya ati ẹsin ni Naijiria’’.
‘’Nigba Abiola ko si Boko Haram to n pa awọn Kristeni, to n jo ṣọṣi abi awọn agbebọn to n ji pasitọ gbe ti wọn si n gba ọkọ awọn eniyan lọwọ wọn.’’
Yiyan igbakeji ẹlẹsin kan naa fihan pe wọn ko naani awa ẹlẹsin Kristẹni ni Naijiria.
Amọ wọn fikun un pe ko si ohun ti awọn le ṣe sii yatọ si ki awọn ọmọ Naijiria dibo fun ẹni ti ọkan wọn ba fẹ ni idibo ọ̀dun to n bọ.
Ohun tí àwọn ọmọ Naijiria n ṣọ rèé nípa Shettima tí Tinubu yàn bíi igbákejì
Ajafẹtọ ọmọ Naijiria, Aisha Yesufu ni yiyan igbakeji lati inu ẹsin kan naa ko bojumu, awọn ọmọ Naijiria ko si ni gba iru rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ninu ọrọ tirẹ, Ajafẹtọ awọn ọdọ Rinu Oduala ni kii ṣe pe ọrọ ẹlẹsin kan naa lo wa nilẹ bayii, amọ ohun ti awọn eniyan n bere fun ni ki pinpin ẹtọ ọmọniyan dọgba lorilẹede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọ agbẹjọro Agba lorilẹeede Naijiria, Festus Keyamo ni oun faramọ ohun ti Tinubu ṣe lori ọrọ igbakeji.
Keyamo ni ko si orilẹede kankan ni agbaye to jẹ pe idagbasoke niiṣe pẹlu didọgba awọn ẹlẹsin to wa ni orilẹede naa.
O ni ṣiṣe ijọba fun idagbasoke kii ṣe lati gboriyin fun awọn adari ẹsin kan tabi jẹ ki nkan lọ bi wọn ṣe fẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3