Mo ní ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn Kristẹ̀ní àmọ́ ìdí tí mo fí yan Mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bí ìgbákèjì rèé – Tinubu

Aworan Shettima ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oludije lẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ni ibọwọ to peye fun ẹsin mejeeji to tobi julọ ti wọn n ṣe lorilẹede Naijiria.

Ahmed Tinubu sọ eyi lẹyin to yan gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC.

O ni yiyan ti oun yan an ko nii ṣe pẹlu pe oun ko bọwọ fun ẹsin Kristẹni, nitori oun bọwọ fun ẹsin naa ti oun ko si fi ọwọ rọọ si ẹyin.

’Mi o ni lailai tabuku ẹsin kankan ni Naijiria’’

Bakan naa lo ni oun gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn ti ko lọwọ si yiyan ẹlẹsin musulumi gẹgẹ bi igbakeji amọ o ni ilọsiwaju orilẹede Niajiria lo pọn dandan.

‘’Gbogbo ẹyin ti inu yin ko dun si ẹni ti mo yan nitori ẹsin, ẹma binu amọ kii ṣe pe mi o kọ ibi ara si ẹsin Kristẹni.’’

‘’Mi o ni lailai tabuku ẹsin kankan ni Naijiria nitori mọ mọ bi o ṣe ri lara awọn ọmọ Naijiria’’

‘’Mo si fi iye si gbogbo ẹdun ọkan awọn ẹniyan lori yiyan ti mo yan igbakeji.’’

Amọ Tinubu ni ko gbọdọ maa lọ lailai ki oun gbogbo ti ijọba ba fẹ ṣe gbọdọ jẹ nipa ẹsin tabi ẹya.

O ni ipenija orilẹede Niajiria lọwọlọwọ n beere fun ki awọn eniyan fi ọkan si ẹni to ba pegede ju ọrọ ẹsin lọ.

Tinubu ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ bẹrẹ si ni fi oju si ẹni ti yoo mu idagbasoke ati aṣeyọri ba orilẹede Naijiria, kii ṣe ọrọ ẹsin.

Tinubu kéde Kashim Shettima gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ fún ìbò Ààrẹ ọdún 2023
Tinubu and Shettima

Oríṣun àwòrán, @Ade_Nurayn

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti kede sẹnetọ Kashim Shetima, gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yo jọ dije.

Tinubu lo fi ikede yii sita lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Daura, tii ṣe ilu Aarẹ Muhammadu Buhari.

Shetima ni gomina ipinlẹ Borno laarin ọdun 2011 si 2019.

Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ile rẹ naa ni Daura fun nnkan bii wakati kan ko to jade lati fi ikede ọhun sita.

Gẹgẹ bii ohun ti Tinubu sọ, o yan Shettima nitori o jẹ ẹnikan to jafafa, to ṣe fọkan tan, ati ẹni to mọ ohun to n ṣe.

Lara awọn to ba Tinubu lọ si Daura ni Gomina Aminu Masari lẹyin ti ọkọ ofurufu to gbe Tinubu balẹ si papakọ ofurufu ti Umaru Musa Yar’Adua ni Katsina.

Ẹni to tọ ni Tinubu yan bii igbakeji rẹ - Keyamo

Nigba ti so n sọrọ lori ikede naa, minisita eto igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, juwe Kashim Shettima gẹgẹ bii ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ, Keyamo sọ pe Tinubu ko ṣe aṣiṣẹ nipa yiyan Shettima.

O ni “Oṣiṣẹ ile ifowopamọsi to dantọ ati onimọ nipa eto ọrọ aje to ṣe mu yangan” ni Shettima.

“Shettima gan ni ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.”

Ẹwẹ, ẹni ti wọn kọkọ yan lati ṣe igbakeji Tinubu, Ibrahim Masari ti ni oun ko ṣe mọ.

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aiku, o ni lẹyin ijiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan, oun ti jawọ ipo igbakeji naa.

Lẹyin naa lo gbadura ki Ọlọrun jẹ ki ipo Aarẹ ti Tinubu n du bọ si lọwọ gẹgẹ bii ero ọkan rẹ.