A ti wọ́gilé kí aláìsàn máà san N1,000 owó iná, bí a ṣe ń ṣe gangan rèé - Iléèwòsàn UCH

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn alasẹ ileewosan ijọba ti ilu Ibadan ti sọ̀rọ̀ soke lẹyin ọrọ to gbode kan pe wọn ni ki awọn alaisan to n gba itọju nibẹ maa san ẹgbẹrun kan naira owo epo fun itọju wọn. Ṣe ni àwọn alasẹ Họsibitu naa ko ọrọ wọn jẹ ti wọn si ni àwọn ti yi Ipinu pada nípa rẹ.
Eyi jẹ jáde ninu atejade kan ti agbenuso ileewosan naa, Ọgbẹni Toye Akinrinola fi ṣọwọ si awọn oniroyin nínú eyi to sọ pe "kò sì ìgbà kankan ti ileewosan naa ni ki awọn eeyan san iru owo yii. O túbọ̀ salaye pe ilera awọn eeyan lo jẹ awọn logun torinaa àwọn ko figba kankan bere fun owo ina.
Bakan naa lo ṣalaye pe atejade ti awọn eeyan n tọka si kan wa fun abẹnu ni eyi ti wọn ko si sọ di tootọ lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo finifini lori iru awọn ọrọ to bawi, wọn si wogile e.
"A n fi da awọn araalu loju pe a maa tesiwaju ninu ṣíṣe eto ilera to dara fawọn ọmọ Naijiria lai fi ti ipo ti wọn ba wa ṣe.
Oladejo tun tẹnu mọ ifarajin ileewosan ọhun lati bojuto itọju gbogbo àwọn alaisan to ba wa si UCH lojoojumo.
Gẹgẹ bo ṣe, ileewosan naa ti ṣe oju aanu daadaa ti wọn wọgile owo ti awọn kan o san lòpọ̀ igba.
"A tun fẹ ko di mimọ pe ileewosan Fasiti yii kii pa awọn alaisan tí bẹẹ si ni a ti wọgile gbèsè ti awọn alaisan jẹ lọpọlọpọ ìgbà". Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ ni àṣírí kan lu sọwọ awọn oniroyin pe atejade ileewosan UCH n gbero lati maa kọ owo ina si ara owo ti awọn alaisan ń san.
Koda ọrọ naa sún siwaju débi pe, ẹlẹyinju aanu kede pé òun yóò san owo epo naa fún iye oṣù melo kan.














